Bukola Saraki 2023 Election: Èmi gan an ni ọmọ Nàìjíríà tó wà fún gbogbo ọmọ Naijiria- Bukola Saraki

Ọjọ Kejidinlọgbọn si ikọkandinlọgbọn, ninu Osu Karun un ni idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP naa yoo waye.

Oludije fun ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP, Bukola Saraki ti ni oun ni yoo jẹ olulaja laarin awọn Musulumi ati ọmọlẹyin Kristi.

Saraki sọ eyi lasiko to n ba awọn aṣoju oludibo labẹle sọrọ lori idibo abẹle ẹgbẹ to n bọ ṣaaju idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023.

Awọn oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu naa wa ki awọn oludije to le ni ẹgbẹrun mẹta (3,700) dibo yan an gẹgẹ bi ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ naa.

Igba wo ni PDP yoo yan awon ọmọ Oye?

Ọjọ Kejidinlọgbọn si ikọkandinlọgbọn, ninu Osu Karun un ni idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP naa yoo waye.

Ninu ọrọ rẹ, Saraki ni oun ṣetan lati tun orilẹede Naijiria ṣe, ti oun yoo si jẹ afara laarin awọn ọmọ Naijiria ni Ariwa ati Guusu orilẹede naa.

''Emi ni ma a jẹ afara laarin awọn Musulumi ati Kristẹni, afara laarin awọn ara Guusu ati Ariwa orilẹede Naijiria.''

Bakan naa lo rọ wọn ki wọn dibo gẹgẹ bi ọkan wọn ba ṣe gba wọn laaye.

''Iṣoro ti Naijiria ni nipe ko si adari to yanju bi o ṣe yẹ lati tukọ orilẹede Naijiria.''

''Ohun ti Naijiria nilo ni awọn ọmọ wa ni ọjọ iwaju, Naijiria ati ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bakan naa lo parọwa si wọn lati dibo yan oun, ki oun le da ẹgbẹ oṣelu naa pada si ipo.

Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria - Bukola Saraki

2023 Election: Bukola Saraki ní òun kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Naijiria láti máa sálọ sí òkè òkun

Oludije fun ipo aarẹ ni Naijiria ati aarẹ Ile Igbimọ aṣ̣ofin tẹlẹri, Bukola saraki ti fi idi rẹ mulẹ wi pe oun yoo dije du ipo aarẹ lorilẹede Naijiria ninu idibo to n bọ ni ọdun to n bọ.

Saraki sọ eyi lasiko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn oniroyin ni ilu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ, Saraki ni idibo ọdun to n bọ yoo fi aye silẹ fun awọn eniyan lati ni ireti ju asiko ti ko si ireti lọ.

Laarin ọdun meji ni eto ilera ọfẹ yoo wa fun awọn ọmọ Naijiria lati ipele ida meje to wa si ida aadọta.

Saraki to jẹ gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ ṣalaye nkan mọkanla ti oun yoo ṣe ti wọn ba yan oun si ipo gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Awọn ohun mọkanla ti ma a ṣe niyii ti mo ba di aarẹ ni Naijiria

Bukola Saraki ni oun dije dupo aarẹ nitori oun ni igbagbọ pe Naijiria yii yoo ṣeeṣe fun awọn eniyan, ti wọn yoo si ṣe aṣeyọri.

Ninu ọrọ rẹ ni aṣofin tẹlẹri naa, Bukola Saraki ti ni ti wọn ba dibo yan oun ni oun yoo mu gbogbo ileri mọkanla yii ṣẹ;

•Ohun akoko ti maa ṣe nipe ki n ri daju pe ko si ọmọde kan ti ko lọ si ileẹkọ, ko si jẹ anfaani eto ẹkọ to mu irorun wa fun awọn eniyan.

•Ipese eto ilera fun awọn agbalagba ati gbogbo ọmọ Naijiria lati ida meje si ida aadọta laaarin ọdun meji.

•Ni asiko mi, opin yoo de ba igbesunmọmi ati iwa ọdaran nitori awọn agbofinro ati ileeṣẹ ọmọogun yoo gba ẹkọ ati ohun ẹṣọ ogun.

•Ma a ri daju pe iwe ofin Naijiria mulẹ daradara laisi pe awọn kan n doju ofin naa boḷẹ

•Idi ti mo fi fẹ di ipo aarẹ mu ni wipe mo fẹ ṣiṣẹ pẹlu awọn olokowo ati aladani lati kọ awọn ọdọ to le ni miliọnu kan ni iṣẹ ọwọ ni ọdọọdun.

•Ida abọ miliọnu ile igbe ni maa pese fun awọn ọmọ Naijiria

•Ma a ṣe atilẹyin fun Naijiria ki wọn le di ipo wọn mu daradara ninu awọn orilẹede to wa ni ilẹ adunlawọ.

•Bukola Saraki ni oun yoo ri daju pe eto ẹkọ ni awọn fasiti gbooro si to si ni awọn ọna igbalode bi ti awọn fasiti to leke ni agbaye.

•Bakan naa lo fikun un pe oun yoo ri daju pe awọn eniyan ko kaakiri lọ si oke ọkun lati lọ wa iṣẹ nitori awọn yoo pese iṣẹ fun awọn ọdọ, ti owo gọbọi yoo si ma a wọle fun wọn.