APC Aspirants Screening: Wo ọjọ́ tí ìgbìmọ̀ àyẹwò yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ lórí àwọn olùdíje tí wọn fí fọ́ọ̀mù ṣọ̀wọ̀ fun ipò labẹ àsìá APC

Oludije mọkandinlọgbọn ni o ti n jọ pe wọn ti fi fọọmu wọn ṣọwọ ti wọn yoo sì lè koju igbimọ ayẹwo ẹgbẹ oṣelu APC .

Laarin ọjọ meji ni wọn yoo fi se ayẹwo yí ṣaaju idibo abẹnu ẹgbẹ ni ọjọ kejidinlọgbọn osu kaarun.

Lara awọn to ribi fi fọọmu wọn ṣọwọ la gbọ pe igbakeji ààrẹ Yemi Osinbajo ati Asiwaju Bola Tinubu wa.

Bẹẹ naa ni ààrẹ Banki idagbasoke ilẹ Afrika,Dokita Akinwumi Adesina, Ogbonnaya Onu to jẹ mínísítà fun eto imọ ẹrọ ati sayensi ni Naijiria tẹlẹ ati aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Naijiria, Ahmad Lawan.

Amọ,a ko le fidi ọrọ múlẹ boya ààrẹ tẹlẹ rí Goodluck Jonathan ati Gomina banki apapọ Godwin Emefiele tàwọn kan ra fọomu fún ribi fi tiwọn ṣọwọ ṣaaju gbedeke ago mejila oru ọjọ Ẹti.

Yatọ sí àwọn taa ka kalẹ yi awọn oludije miran ti wọn ti fi fọọmu wọn ṣọwọ niyi:

  • Pasitọ Tunde Bakare
  • Rotimi Amaechi
  • Godswill Akpabio
  • Sen Rochas Okorocha
  • Sen Ibikunle Amosun
  • Gómìnà David Umahi
  • Gómìnà Kayode Fayemi
  • Gomina Yahaya Bello ati awọn miran.

Ọjọ wo ni igbimọ ayẹwo yoo bẹrẹ iṣẹ?

Atẹjade kan lati ọdọ akọwe eleto igbimọ ayẹwo APC, Suleiman Muhammad Argungu sọ pe wọn yoo ṣe ìfilọ́lẹ̀ awọn alaga ati akọwe igbimọ fún ipo ile aṣofin ati Gomina ni ọjọ Abameta tii se ọjọ kẹrinla oṣù Kàrún.

O ni kete ti ìfilọ́lẹ̀ yi ba ti pari ni awọn alaga ati akọwe igbimọ naa yoo bẹrẹ iṣẹ ayẹwo àwọn tó fẹ du ipo ile asoju sofin mu.

Ọjọ Kejì ọjọ yi ni tàwọn tó fẹ du ipo Gomina ati ile aṣofin agba yoo tẹle.

A kò ti ni iroyin to se dimu lori igba ti ìfilọ́lẹ̀ àti ayẹwo igbimo tàwọn tí yoo du ipò ààrẹ yoo waye.

Amo igbakigba ti yoo ba jẹ, iṣẹ tó pọ ni igbimọ naa yoo ṣe nítorí iye àwọn oludije ipo ààrẹ labẹ asia ẹgbẹ APC kii ṣe kekere.