You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bauchi Blasphemy: Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ́bù méje ní Bauchi nítórí obìnrin tí wọ́n ló bú Ànọ́bì lórí Whatsapp
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ọlọpaa ti kun gbogbo agbegbe to wa ni ijọba ibilẹ Warji, nipinlẹ Bauchi, lẹyin ti awọn ọdọ kan bẹrẹ iwọde lori pe ẹnikan sọrọ odi si ẹsin Islam.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita lọjọ Satide, arabinrin ẹni ogoji ọdun kan lo fi ọrọ to tako anọbi si ori ayelujara, eyi to tun fa wahala.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe ori ayelujara Whatsapp ni wahala ti bẹrẹ.
Ẹni naa sọ pe gbogbo awọn to wa ninu 'Whatsapp Group' ọhun lo jẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Warji, to fi mọ obinrin ti wọn lo sọrọ abuku si anọbi.
"Ni nkan bi aago mọkanla owurọ ọjọ Ẹti, ni obinrin naa fi fidio kan nibi ti ẹnikan lati orilẹ-ede Ghana ti n bú ẹsin Islam.
"Mo ba obinrin naa wi pe ko yọ fidio ọhun kuro, amọ ko da mi lohun."
- Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Fífún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí mẹ́fà lórí ikú "Sound Engineer"
- A kò fẹ́ kí Kumuyi wá ṣe ìsọjí ìta gbangba nílùú Abia – IPOB
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
Mọ̀ sii nipa awọn to wa ninu 'Whatsapp Group'naa ni Bauchi:
O ni awọn bi ogun lo wa ninu 'Group' naa, mẹẹdogun ninu wọn si jẹ Musulumi.
"Nitori naa lo ṣe jẹ nkan ti ko bojumu fun un lati fi iru fidio bẹẹ si aarin wa.
"Eeyan bii mẹrin lo tun sọ fun pe ko yọ fidio naa kuro, ti ko si da wọn lohun. Koda, igbakeji ọga agba pe e lori foonu rẹ, amọ ko gbe ipe naa."
Ẹlẹri naa ṣalaye pe nkan to bi awọn eeyan kan ninu re e , to fi di pe awọn ọdọ kan bẹrẹ si ni wa obinrin naa ni nkan bi aago marun-un irọlẹ.
Ṣugbọn ori ko yọ, nitori pe awọn oṣiṣẹ ajọ DSS tete doola rẹ ki awọn ọdọ naa to de ile rẹ.
Ṣe lootọ ni awọn ọdọ naa dana sun ṣọọṣi ati ile pasitọ kan?
Ṣaaju ni iroyin ni awọn ọdọ to ṣe iwọde ọhun dana sun ṣọọṣi kan, ati ile pasitọ, ṣugbọn ẹni to ba BBC sọrọ ni irọ patapata ni eyi.
O ni amọ wọn dana sun awọn ile itaja ati ile gbigbe to jẹ ti awọn eeyan kan.
Alaafia ti pada jọba - Ọlọpaa
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Bauchi, Umar Mamman sọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, SP Ahmed Wakili fi sita pe, alaafia ti pada si agbegbe naa.
Ati pe awọn ọlọpaa n lọ, wọn n bọ ni agbegbe naa ni.
O ni ogunlọgọ eeyan lo farapa , ti wọn si tun dana sun ile mẹfa, ati ṣọọbu meje nibi rogbodiyan naa to waye lọjọ Ẹti.
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- "Láti àkókò yìí lọ, àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa bo ojú wọn lórí tẹlifíṣọ̀nù"
- Àwọn ọmọ ogun America pa olórí ISIS, Ibrahim al-Qurayshi ní Syria
- Gbajúgbajà akọrin takasúfè nílẹ̀ America, DMX ti jáde l'áyé
- Ìkìlọ̀! America yóò tutù ju bó ti yẹ lọ
- Ohun tí a mọ nípa ikọlù àwọn agbébọn sí ilé ìtura ní Ikorodu rèé
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
Ọga ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe o sẹ pataki ki awọn agbalagba ma a gba awọn ọdọ ni imọran pe ki wọn o ma a yago fun ohunkohun to ba le da wahala silẹ ni agbegbe wọn.
Bakan naa lo sọ pe iwadii ti n waye lati mọ awọn to wa nidi iṣẹlẹ ọhun.
Awọn iṣẹlẹ isọrọ abuku si Anọbi to waye ni Naijiria laipẹ
Ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, 2022 - Ọsẹ to kọja ni awọn kan sọ akẹkọọbinrin ti ile ẹkọ Shehu Shagari College of Eductaion, Deborah Samuel,ni okuta pa, ti wọn si tun dana sun oku rẹ.
Wọn ti ẹsun kan an pe o bu anọbi Muhammed ninu ọrọ kan to sọ.
Iṣẹlẹ yii ṣi n fa awuyewuye jakejado Naijiria.
Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 - Ile ẹkọ kan ni Kano ju ọkunrin kan ti ko gbagbọ ninu ẹsin kankan, Mubarak Bala, si ẹwọn ọdun mẹrinlelogun.
Wọn fi ẹsun kan na pe o bu anọbi. Ọgbẹni Bala, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni aarẹ Humanist Association of Nigeria.
O ni lootọ ni oun jẹbi ẹsun mejidinlogun ti wọn fi kan oun, amọ o bẹbẹ fun idajọ ti ko le. Ọdun 2020 lo ti wa ni atimọle.
Oṣu Kẹjọ, 2020 - Ile ẹjọ Sharia nipinlẹ Kano dajọ iku fun akọrin kan, fun pe o bu anọbi Mohammed.
Ile ẹjọ naa sọ pe ki wọn o yẹgi fun Yahaya Aminu Shariff ni.