Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún 76 he fún ẹ̀sùn lílu jìbìtì orí ayélujára tó ṣekúpa ọ̀dọ́ kan láti Canada

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ giga kan to wa ni Ikoyi nipinlẹ Eko ti ran ọkunrin kan Olukeye Adedayo lọ ẹwọn ọdun mẹrindinlọgọrin fun ẹsun lilu jibiti lori ayelujara.

Awọn ẹsun mii ti wọn tun fi kan Olukeye Adedayo lo tun ni ohun se pẹlu ibalopọ ọmọde ati gbigba owo lati ma pin aworan ihoho sita ati ikobani.

Adajọ Alexander Owoeye lo gbe idajọ naa kalẹ ni Ọjọ Kọkandinlogun Oṣu Kẹfa ọdun 2025, to si ni Adedayo jẹbi gbogbo ẹsun mejidinlogun ti ajọ EFCC ka si iẹsẹ.

Adedayo, ẹni ti o n lo orukọ bii hrm87, charlotte708, ati harlilott_716 lori ayelujara, ni ọwọ tẹ fun bi o ṣe da ẹgbẹ kan silẹ lori oju opo ibanidọrẹ Instagram, eyi to pe ni "Expose Janjua Robin Nudes".

Ẹgbẹ naa si lo n lo lati maa fi pin aworan ihoho ọmọ ọdun mẹrinla kan lati orilẹede Canada Robin Janjua.

Ṣaaju, o ni oun ko jẹ ẹsun ti wọn ka si oun lẹsẹ ṣugbọn olupẹjọ, ti Bilikisu Buhari lewaju fun pe, ẹlẹrii meji tako eyi ni ile ẹjọ:

Awọn ẹlẹrii naa ni Wahid Hamidi ti Royal Canadian Mounted Police (RCMP) ati oṣiṣẹ EFCC Saidu Yakubu.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Ni oṣu keji ọdun 2023, wọn pe ileeṣẹ ọlọpaa lati ile kan ni Surrey, British Columbia, nipa iku ọdọmọkunrin kan to padanu ẹmi rẹ.

Iwadii ọlọpaa fihan pe ọmọ ọdun mẹrinla ọhun ṣekupa ara rẹ nitori eeyan kan to fi aworan ihoho rẹ lu ni jibiti, ko si ma gba owo lọwọ rẹ.

Olukeye Adedayo sọ fun oloogbe naa pe ko ra gift cards fun ohun ki oun ma ba pin aworan ihoho rẹ fun gbogbo aye.

"O nifẹẹ hockey, to si n gbadun aye. Ko si bi a ko ṣe ni ṣafẹri rẹ. Oni inu re ni, ti wọn si lo inu rẹ gba ẹmi rẹ," mọlẹbi ṣalaye.

Ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2023 ni ajọ EFCC wọ Olukeye Adebayo lọ si ile ẹjọ.

Ilu Akute nipinlẹ Ogun ni ọwọ ti tẹ Adebayo ni Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2023 lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa gba iroyin lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Canada, RCMP.

Nigba ti wọn n tu ile rẹ ni Ilaro nipinlẹ Ogun, ileeṣẹ ọlọpaa ṣawari foonu ti Adedayo n lo lati fi dunkoko mọ oloogbe.

Ko ki n ṣe igba akọkọ ree ti ile ẹjọ Naijiria yoo ran eeyan lọ si ẹwọn nitiro ẹsun bayii.

Ni ọdun 2024, tẹgbọn-taburo Samuel ati Samson Ogoshi ri ẹwon he ni US.

Ọna lati da bo bo ara rẹ lọwọ jibiti sextortion

Awọn akọsẹmọsẹ ti gbe awọn amoran sita lori bi eeyan ṣe le da bobo ara rẹ lọwọ awọn onijibiti ayelujara

Ajọ Cyber Security Authority lorilẹede Ghana lo gbe awọn amọran yii sita.

  • Ma ba ẹnikẹni ti o ko ba mọ di ọrẹ lori ayeluajara, paapa awọn ti ko iroyin kankan nipa wọn.
  • Ma ba ẹnikẹni ṣe ọrẹ ti yoo mu ni pe ki ẹ pada lori ikanni Whatsapp
  • Ma ṣe ya aworan ihoho rẹ si ẹnikẹni tabi ya sori foonu rẹ.
  • M a se gbe ipe fidio lati ọdọ ẹni ti o ko mọ ri.
  • Ma ṣe pin aworan ihoho rẹ tabi gbe sori ayelujara.