You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Jamb 2022: Àjọ̀ JAMB kéde àwọn nkan tí akẹ́kọ̀ọ́ kò gbọdọ̀ mú wọ yààrá ìdánwò
Esi idanwo abala akọkọ a to jade- Ajo JAMB
Omowe Fabian Benjamin to jẹ alukoro ajọ Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB) to jẹ ajọ to n risi eto idanwo gbigba awọn akẹkọọ wọle sile ẹkọ gigha ni Naijiria ti sọrọsoke.
Fabian sọ pe awọn akẹkọọ to ṣe idanwo abala akọkọ tọdun 2022 UTME yii to waye lọjọ Eti ati ọjọ Abamẹta ni esi idanwo wọn yoo jade lọsẹ yii.
- Ẹkún tún sọ ní Zamfara, àwọn agbébọn pa èèyàn 48
- Kí nìdí táwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà ṣe fẹ́ wọ́gilé ìrìnnà òfúrufú ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé?
- Wo ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní "ọ̀nà ikú" tí àwọn ènìyàn ṣì ń ṣe ìrìnàjò lórí rẹ̀ síbẹ̀
- Torí oge ṣíṣe, wo obìnrin tó ṣe ìrìbọmi omi tútù àmọ́ tó já sí ikú fún u
- 'Mo bá ajá ní ìbálòpọ̀ nítorí ₦1.4m', ka ǹkan tí òfin Nàìjíríà ṣọ nípa ìwà yìí
- Bí Jibrin ṣe kúrò ní ẹgbẹ̀ òṣèlú APC kò níi ṣe pẹ̀lú Bola Tinubu- Agbẹnusọ ìpolongo
Àjọ̀ JAMB kéde àwọn nkan tí akẹ́kọ̀ọ́ kò gbọdọ̀ mú wọ yààrá ìdánwò fún UTME 2022
Ajọ to n ṣeto idanwo aṣewọle sile ẹkọ giga ni Naijiria ti kede awọn nkan ti awọn akẹkọọ ko gbọdọ mu wọ yaara idanwo ni ọdun 2022
Idanwo aṣewọle si ile ẹkọ giga ni Naijiria, JAMB, fun ọdun 2022, ti bẹrẹ ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un.
Eyi si ti mu ki ajọ to n ṣeto idanwo naa fi awọn ikede sita nipa awọn nkan eewọ ti awọn akẹkọọ ko gbọdọ mu wọ yaara idanwo wọn.
Ninu ikede naa to wa ni ori itakun agbaye wọn, ajọ JAMB sọ pe ẹnikẹni to ba ṣe aigbọran si eyikeyi ilana naa, ko ni ṣe idanwo rẹ.
- Ikú d'óró! Wole Adetiran tó kọ orin àdákọ àgùnbánirọ̀ Naijiria 'NYSC Anthem' ti jáde láyé
- Ṣe gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà lè díje dupò Ààrẹ? Àlàyé rèé
- Òkú obìnrin yìí kan ìlẹ̀kùn pósí gbà-gbà-gbà pé òun ò kú lọ́jọ́ ìsìnkú rẹ̀! Kàyéfì tuntun
- Ìdí tí NIN rẹ fi ṣe pàtàkì láti forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB 2021 rèé
Nkan mẹtalelogun ni JAMB kọ sita pe o lewu fun akẹkọọ lati mu wọ yaara idanwo.
Awọn nkan naa ni:
•Bairo Ikọwe
•Ẹrọ iabnisọrọ
•Gilaasi oju afimufinlẹ (Spy Reading glasses)
•Kakuletọ
•USB, CD, Hard Disks ati awọn mii to fara pẹẹ
•Iwe kika tabi fun kikọ nkan
•Kamẹra
•Ẹrọ agbohunsilẹ (recorder)
•Ẹrọ gbohun-gbohun (Microphones)
•Ear pieces
•Ink and Pen readers
•Smart or Contact Lenses
•Smart Rings and Jewellery
•Smart Buttons
•Bluetooth devices
•Key Holders
•ATM Cards
•Erasers
•Aṣọ inuju (Hankerchief)
•Towẹnu inuju (Face Towels)
•Owo
•Aṣọ oru to ni ibori (Sweater with cap)
•Fila (Face caps)
Dandan ni fun awọn to fẹ ṣe idanwo lati tẹ iwe pelebe kan jade lori ayelujara
Ṣaaju ni ajọ naa kede pe awọn akẹkọọ gbọdọ tẹ iwe pelebe to ni akọsilẹ orukọ wọn, ibudo idanwo wọn, ọjọ ati akoko idanwo.
Lati tẹ iwe pelebe naa, lọ si ori itakun agbaye https://www.jamb.gov.ng.
Awọn ibudo idanwo, CBT centres, nikan ni awọn akẹkọọ ti le tẹ iwe yii jade tẹlẹ.
Amọ ni bayii, o le tẹ iwe pelebe naa ni ibudo yoowu to ba ni ẹrọ ayelujara ati ẹrọ itẹwe, boya aladani tabi ti awọn to fi n ṣe okoowo.
Agbẹnusọ ajọ naa, Fabian Okoro, sọ pe o ṣe koko fun awọn to fẹ ṣe idanwo lati tete tẹ iwe pelebe naa, ki wọn o le ṣe gbogbo imurasilẹ to yẹ ṣaaju ọjọ idanwo..
Bakan naa ni ajọ naa sọ pe oun yoo lo ẹrọ Biometric Verification Machine (BVM), lati ṣe ayẹwo gbogbo ẹni to fẹ ṣe idanwo, ki wọn o to wọle si yaara idanwo wọn.
Yatọ si eyi, ajọ JAMB sọ pe oun ko ni ṣe idanwo miran fun idi kankan, nitori pe awọn gbagbọ pe awọn to fẹ sẹ idanwo gbọdọ gbaradi, ki wọn o si mule si itosi ibudo idanwo wọn.