You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Siblings kidnapped in Abuja: Ọmọ ìyá kan nàá mẹ́ta di àwátì ní ilé-ẹ̀kọ́ wọ́n nílùú Abuja
Ọmọ iya kan naa mẹta ti di awati nile ẹkọ alakọbẹrẹ kan nilu Abuja
Ọjọ Iṣẹgun ni iya awọn ọmọ naa de ile ẹkọ naa ladugbo Kabusa lati ko wọn lọ sile, amọ ko ri wọn.
Awọn ọmọde naa, Marvelous, Alex ati Rehoboth Sunday, ni iwe iroyin the Punch jabọ pe ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹjọ si meji.
Gbogbo igbiyanju awọn ara adugbo, awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa, ati awọn obi wọn lo ja si pabo
Eyi to fa iwọde ni agbegbe naa ki wọn o to fa awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa le ọlọpaa lọwọ.
Awọn ara adugbo to ba oniroyin sọrọ sọ pe gbogbo kọọrọ ati gbangba to wa ni adugbo Kabusa ni ara adugbo wa awọn ọmọ naa de titi di Ọjọru, ti wọn ko si ri wọn.
Iroyin sọ pe awọn obi awọn ọmọde naa ti kọkọ padanu ọmọ wọn kan to ku, ki mẹta yooku tun to di awati bayii.
Lọjọ Ọjọbọ bakan naa, awọn ara adugbo Kuje ṣe iwọde nitori ijinigbe ti wọn lo n waye ni gbogbo igba ni agbegbe awọn.
Iroyin ti a gbọ ni pe eeyan mẹta ni awọn agbebọn jigbe ninu ile wọn loru Ọjọbọ.