Bogoso explosion: Èèyàn 17 kú, 60 farapa níbí ìbúgbàmù kan tó wáyé nítòsí ibi ìwakùsà kan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ko din ni eeyan mẹtadinlogun to kú, ti ọgọta si farapa lẹyin ibugbamu kan to waye nitosi ilu kan ti wọn ti n wa kusa, Bogoso, ni Iwọ-oorun Ghana.

Ileeṣẹ eto iroyin lo fi ikede naa sita ni nkan bi aago marun-un irọle Ọjọbọ.

Awọn alaṣẹ sọ pe eeyan mejilelogoji lara awọn to farapa n gba itọju, ṣugbọn awọn yooku wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Agbegbe Apiate to wa laarin ilu Bogoso ati Bawdie ni ibugbamu naa ti waye ni ọsan Ọjọbọ.

Bi ibugbamu naa ṣe waye

Iwadii ti awọn ọlọpaa kọkọ ṣe fihan pe ijamba ọkọ to waye laarin awọn ọkọ to gbe awọn bkan abugbamu ti wọn fi n wa kusa lo kọkọ fa iṣẹlẹ naa, ko to o di pe ọkọ ayọkẹlẹ kan to sunmọ ẹrọ amunawa 'transformer' kan naa tun bu gbamu.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara, a ri ọkọ akẹru kan to n jona laarin ọna, ti awọn eeyan si n ya fidio rẹ.

Bi wọn ṣe n ya fidio rẹ, ni wọn n rin sunmọ ibi to wa. Bo ṣe ku diẹ ki wọn de ibi ti ọkọ naa wa lo bu gbamu.

Igbesẹ awọn agbofinro ati awọn ara ilu:

Awọn ọlọpaa ati ikọ adoola ẹmi sọ pe ki awọn eniyan ma ba ọkan jẹ.

Bakan naa ni wọn gba awọn ara adugbo naa niyanju pe ki wọn kọkọ fi agbegbe naa silẹ, titi iṣẹ idoola ati atunsẹ yoo fi pari, fun aabo ẹmi wọn.