You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lagos walk for peace: Wo ìdí tí Sanwo-Olu wọ́gilé ìrìnàjò àláàfíà 'Walk for Peace' tó fẹ́ẹ̀ rìn pẹ̀lú àwọn ará Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti jawọ ninu erongba rẹ lati rin irin alaafia fun ipinlẹ Eko loṣu Kejila, ọdun 2021.
Ọgbọnjọ oṣu Kọkanla ni Ọgbẹni Sanwo-Olu kede pe oun ati awọn alaṣẹ ipinlẹ Eko yoo rin yika ipinlẹ naa lati pe alaafia pada, lẹyin rogbodiyan iwọde EndSars to waye lọdun 2020.
Bakan naa ni Sanwo-Olu ke si awsn to jẹ gbajumọ laarin awọn to dari iwọde naa .
Lara wọn ni akọrib, Folarin Falana 'Falz', Debo 'Mr Macaroni'.
Ikede yii fa awuyewuye lori ayelujara, paapaa laarin awọn ọdọ to gbagbọ pe ijọba ipinlẹ Eko ko ṣe idajọ ododo lori awọn ti sọja pa ni Lekki toll Gate.
- A ṣetán láti bá Sanwo-Olu rìnrìn àlàáfíà, ẹ̀yin krìstẹ́nì, ẹ darapọ̀ mọ wa- MURIC
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- Ìlú Eko yóò gbàlejò Àarẹ Muhammadu Buhari lónìí
- Wo ohun tó fa ariwo FRSC àti Ọlọ́pàá gangan nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó gba ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Ojodu Berger
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
Sugbọn lọjọ kẹsan an, oṣu Kejila, ni gomina tun fi atẹjade miran sita pe o ti di dandan fun oun lati da gbogbo igbaradi to n waye fun irinajo alaafia naa 'Walk for Peace', ki oun ma ba fi ẹmi awọn ara Eko sinu ewu"nitori itankalẹ ẹda aarun Covid-19, Omicron.
O ni laarin ọjọ ti oun kede irin alaafia naa si oni, awọn to ni aarun naa ti pọ si.
"Nitori idi eyi, ko si igbesẹ miran ti mo le gbe ju pe ki n da gbogbo imurasilẹ fun irin alaafia naa duro.
"N ko ni fi ẹmi ara Eko kankan wewu nitori pe mo n wa alaafia. Mo dupẹ fun gbogbo atilẹyin ti eto naa ti ri gba. Gbogbo lo n fihan pe awọn eniyan wa pataki alaafia fun idagbasoke ilu."