You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ojodu trailer accident: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ da ìgboro rú l'Eko nítorí ikú àwọn tí tírélà pa ní Ojodu- Berger, àwọn kan ń nàka sáwọn òṣìṣẹ́ ojú pópó
Ọkọ ajagbe tirela to ṣeku pa awọn akẹkọọ ileẹ̀kọ́ girama Ojodu Grammar school.
Eyi to wa lagbegbe Berger ni ipinlẹ Eko la gbọ pe o ṣekupa awọn akẹkọọ naa lasiko ti wọn fi n kuro nileewe lọ si ile wọn.
Ọkan lara awọn eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe iwọde awọn akẹgbẹ wọn da ọpọ hilahilo silẹ lati nnkan bii agogo meji ọsan ọjọ Aje ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Akọroyin BBC to debi iṣẹlẹ naa sṣalye pe oun ri awọn ẹsẹ bata akẹkọọ tawọn ewe ọpẹ ti wọn fi bo ẹya ara awọn oku awọn akẹkọọ naa ti wọn ri ko jọ.
Lara awọn eeyan to ri nibẹ ṣalaye pe wọn ti gbe diẹ lara awọn akẹkọọ naa lọ si ileewosan.
Amọṣa o, awọn agbofinro ti da alaafia pada si agbegbe naa lẹyin yanpnyanrin to bẹsilẹ latọwọ awọn akẹkọọ ileewe naa kan lagbegbe ibẹ lati fi ẹhonu han lori iku awọn akẹgbẹ wọn.
'Awọn oṣiṣẹ oju popo lo n le tirela naa'
Bí ìjàmbá Tírélà tó pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ l'Eko ṣe ṣẹlẹ́ rèé àti bí ó ṣe kan VIO, FRSC
Lootọ ko tii si ẹni lee sọ ni pato ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ buruku yii, awọn eeyan kan lagbegbe naa n sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ alamojuto oju popo kan ni wọn n le awakọ tirela naa ki ijamba naa to waye.
Awọn kan ni oṣiṣẹ tirela naa n gbiyanju ati sa mọ awọn oṣiṣẹ VIO kan lọwọ ki o to lọ kọlu awọn akẹkọọ naa.
Bakan naa ni awọn miran n darukọ ileeṣẹ ẹṣọ oju popo FRSC pẹlu.
Ki ni ileeṣẹ ẹṣọ oju popo FRSC sọ?
Ajọ ẹṣọ oju popo ni ipinlẹ Eko ti wa sọrọ sita pe awọn ko mọ si ohun to ṣokunfa ijamba naa.
Ninu atẹjade kan to fi sita, ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Eko ṣalaye pe awọn eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn lo ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa pe ki wọn wa ṣeranwọ lori didoola ẹmi awọn akẹkọọ ti iṣẹlẹ ijamba naa kan.
O ni meje ninu wọn ni wọn gbe lọ sibudo itju iṣẹlẹ pajawiri Lagos state Emergency Center to wa lagbegbe Ọjọta ti eeyan kan to ni ọkọ pẹlu tun ko awọn meje miran wa sibẹ.
Ileeṣẹ ẹṣọ oju popo ni ko si oṣiṣẹ rẹ kankan to wa lagbegbe naa lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.
Ki ni Ọlọpaa sọ?
Ikọ kogberegbe rapid Response RRS nipinlẹ Eko ni wn ti pana wahala lagbegbe naa, ohun gbogbo lo si ti n lọ ni pẹlẹ putu.
Bakan naa ni ikọ naa fi kun un pe gbogbo agbegbe naa ni wọn n fọn ọlọpaa si bayii lati kawọ awọn to ba fẹ da wahala silẹ.
Amọsa ileeṣẹ ọlọpaa ko tii le sọ ni pato iye awọn akẹkọọ to ku ninu ijamba naa.
Tírélà pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ l'Eko, làwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ wọn bá da ìgboro rú
Awọn akẹkọọ ileẹ̀kọ́ kan lagbegbe Ojodu Berger niroyin fidi rẹ mulẹ pe wọn kagbako iṣẹlẹ ijamba ọkọ eleyi to mu ẹmi ọpọ wọn lọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ, ọkọ ajagbe kan lo kọlu awọn ọmọ naa lẹyin ti ijanu rẹ kọṣẹ.
- Mẹ́ta lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College tí Sylvester dárúkọ ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá - Kọmisanna ọlọpaa Eko
- Ìgbésẹ̀ láti dínà arìnrìnàjò ọmọ Nàìjíríà sí UK yóò da ètò rú fáwọn tó fẹ́ bá ẹbí wọn ṣe Kérésìmesì ní UK
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
- Wọ́n bá òkú ọmọ ọdún méje tó di àwátì nínú 'cooler' nílé 'pásítọ̀' ní Ado-Ekiti
Iroyin ọhun tun sọpe ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lawọn akẹkọọ ileewe Ojodu grammar school ti fọn sigboro lati ṣe iwọde lori iku awọn akẹgbẹ wọn.
Fun ọpọlọpọ wakati ni gbogbo nnkan fi dojuru lagbegbe naa ti olukuluku si n sa asala fun ẹmi wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ṣalaye fun awọn akọroyin kan pe awọn ti n gbe igbesẹ to yẹ lati mu alaafia pada si agbegbe naa.
O ni awọn ọlọpaa to kun oju iwọn ti wa nibẹ lati mojuto iṣẹlẹ naa gẹgẹbi akọṣẹmọṣẹ.