You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Omicron Nigeria COVID-19: Yàtọ̀ sí èèyàn mẹ́ta tó kọ́kọ́ kó Omicron, wo iye àwọn tó tún lùgbàdì àrùn náà báyìí
Ileesẹ to n gbodun ti itankalẹ àrùn ni Naijiria NCDC ti fìdí rẹ múlẹ péé eeyan mẹta tun tí lugbadi ẹdá arun COVID-19 tuntun Omicron.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Ìṣẹgun ni won ti so pe eyi ti mu kí apapọ èèyàn tó kọ eda arun yi ni Naijiria di mẹfa.
Gbogbo wọn ní ẹrí fi hàn pé wọn rinrinajo laipẹ yi lọ sí South Africa ninu oṣù Kọkànlá.
Ẹda COVID-19 tuntun yi jẹ eleyi to n kan ọpọ lominu lagbaye nitori awọn onimọ sayensi sí n gbìyànjú lati mọ nipa rẹ.
Ni ọjọ Aje ni ilẹ Gẹẹsi fi orúkọ Naijira kun awọn orilẹ-ede ti wọn gbegi dina lati ma ṣe wọ ilẹ wọn.
Awọn ti ki ba ṣe ọmọ ilẹ Gẹẹsi to bá n bọlagi Naijiria ko ni le wọ ilẹ wọn.
Wọn ni awọn gbé ìgbésẹ yi lati le daabo bo àwọn ọmọ orileede wọn nítorí wọn ti pe eeyan tó ko arun yi ni South Africa ko kere.
Amọ igbesẹ yi ko dun mọ Naijiria ninu tawon alase si ṣàpèjúwe rẹ gegey bi idẹyẹsi ti ko ṣe deede.
Awọn orilẹ-ede Áfríkà mẹwàá miran ni wọn ti gbegi dina pe kí wọn má ṣe rìnrìnajo sí ilẹ wọn yàtọ sí Naijiria nitori ẹda COVID-19 Omicron ti wọn s'awari ni South Africa.
Naijiria ni orile-ede Afrika ti eeyan pọju nibe ti awọn eeyan ilẹ naa di fẹ wọ igba mílíọ̀nù.
Ṣugbọn iye eeyan to wa ni akọsilẹ pe won ti ko arun COVID-19 ko ti kọja 215, 000 lati igba tí àjàkálẹ̀ yi bẹrẹ lọdun to kọja.
Iye eeyan to ti gba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 kere ni Naijiria.
Awọn alaṣẹ so pe eyi ko sẹyìn bi araalu ṣe n tadi sẹyìn lati jade wa gba abẹrẹ náà.