You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2020 EndSARS Protest update: Olùwọ́de EndSars mìí tí oyún bàjẹ́ mọ́ lára ni ẹ̀wọ̀n Akure, Bukunmi Ayodele gba òmìnira
Lẹyin oṣu mẹwaa to ti wa ni ọgba ẹwọn, Bukunmi Ayodele ti gba ominira.
Lasiko iwọde EndSars to waye ni awọn ipinlẹ kan ni orilẹ-ede Naijiria ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni awọn agbofinro mu Bukunmi ati awọn oluwọde miran ni ipinlẹ Ondo.
Lati igba naa si lo ti wa ni ọgba ẹwọn Olokuta, to wa ni ilu Akure, ki ile ẹjọ to o gba beeli rẹ ni Ọjọru, ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021.
Bukunmi Ayodele ni ọdọ keji ti ile ẹjọ gba beeli rẹ lara awọn oluwọde EndSars nipinlẹ Ondo, lẹyin ti iroyin nipa wọn jade.
Kemisola Ogunniyi lo kọkọ gba ominira lẹyin to bimọ si ọgba ẹwọn.
- Olùwọ́de EndSARS bímọ tuntun nínú ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó ti lo oṣù mẹ́jọ ní àhámọ́
- Báyìí ni olùwọ́de EndSARS, Eremosele Adene ṣe gba òmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà
- Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Osun bínú yabo iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ìdigunjalẹ̀ tó gba ẹ̀mí eèyàn ní Iree
- Ọ̀rẹ́bìnrin kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó gún "Sugar daddy" rẹ̀ pa
- Bí ènìyàn Ọ̀ọ́dúnrún ṣe fò ṣán'lẹ̀ kú rèé torí ààrùn onígbà méjì ní Kano ati Jigawa
Agbẹjọro fun Bukunmi, Amofin Tope Temokun sọ ninu atẹjade to fi kede ominira onibaara rẹ pe lati ọjọ kẹjọ, oṣu Keje ni ile ẹjọ ti gba beeli rẹ.
Sugbọn ko le kuro ni ọgba ẹwọn nitori pe ko tete ri miliọnu kan Naira to wa lara ilana beeli ti adajọ fun un.
Amofin Temokun sọ pe "o ṣoro lati ri iru owo bẹ ẹ, nitori pe ọmọ naa ko ni ẹnikan ayaafi iya rẹ to jẹ alaini."
O ni oun dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria to da si ọrọ naa nigba ti iroyin rẹ jade.
Bakan naa lo sọ pe Bukunmi yoo nilo iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu, lati le pada si igbe aye rere, nitori pe ọgba ẹwọn to lọ ti mu idiwọ ba ọrọ aje rẹ.
O ṣalaye pe oyun tun bajẹ mọ ọmọbinrin naa lara lasiko to wa ni ọgba ẹwọn naa, ti ko si ri itọju kankan gba lẹyin iṣẹlẹ ọhun.
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń wa ẹnu lé ìyàwó ọmọ Ààrẹ Buhari torí àwọn aṣọ ìgbéyàwó rẹ̀ tó ṣí ara sílẹ̀
- Ààrẹ NFF tẹ́lẹ̀ri Oneya jáde láyé lẹ́ni ọdún 73
- Bí ènìyàn Ọ̀ọ́dúnrún ṣe fò ṣán'lẹ̀ kú rèé torí ààrùn onígbà méjì ní Kano ati Jigawa
- A ti mú afurasí darandaran méjì tó ń da màálù tó kan ọmọ oṣù mẹ́ta pa- Ọlọ́pàá
- Ẹran Akíka(Pangolin) àti ìwo Erin d'ẹ́rù b'olẹ̀, ìjọba f'òfin gba bílíọ́nù 22 ẹran ara wọn