Olonisakin, Buratai: Buhari kéde àwọn ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọmọ ogun tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi aṣojú Naijiria nílẹ̀ òkèèrè

Aare Buhari kéde Buratai ati Olonisakin gẹ́gẹ́ bíi aṣojú Naijiria sí Benin àti Cameroun

Minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, lo fun awọn ọgagunn naa ni iwe iṣẹ wọn tuntun lọjọru.

Wọn fun ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun tẹlẹ, ajagunfẹyinti Lt. Gen. Tukur Yusufu Buratai ni lẹta gẹgẹ bii aṣoju Naijiria si orilẹ-ede Republic of Benin.

Nigba ti ajagunfẹyinti Abayomi Gabriel Olonisakin to jẹ minisita eto abo tẹlẹri gba lẹta gẹgẹ bii aṣoju Naijiria silẹ Cameroon.

Lasiko ti wọn n kede ipo tuntun naa fun awọn eeyan ọhun, minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama ki wọn ku oriire, o si tun rọ wọn lati jẹ aṣoju Naijiria rere nilẹ okeere.

Nigba ti wọn n fesi, Buratai ati Olonisakin ṣeleri lati jẹ aṣoju rere fun Naijiria ati lati lo iriri wọn lẹnu iṣẹ ologun ni Naijiria lẹnu iṣẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gba.

Ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2021 yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari fi orukọ awọn eeyan mẹrin to jẹ ọga agba ileeṣẹ Ologun ana ṣọwọ sile igbimọ aṣfin fun fifi ontẹ lu.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo tapa si igbesẹ ọhun, awọn aṣofin buwọlu orukọ awọn mẹrẹrin naa lọjọ kẹtalelogun, oṣu keji kan naa.

Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ana, Ibok Ibias ati ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ana, Abubakar Sadique ṣi n reti lati gba lẹta ti wọn.