Akeugbagold twins: Wo ìdí tí Akeugbagold fi dáríji àwọn tó jí ìbejì rẹ̀ gbé nílé ẹjọ́

Gbajugbaja olori ẹlẹsin Islam, Sheik Taofeek Akeugbagold ti kọwe sile ẹjọ giga ti ipinlẹ Ọyọ nilu Ibadan pe oun ko ṣe ẹjọ mọ pẹlu awọn to ji awọn ọmọ rẹ gbe.

Ọjọ Aje ni Akeugbagold sọ niwaju Onidajọ Moshood Abass pe oun sẹ ẹjọ mọ pẹlu awọn afurasi naa.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2020 ni awọn ajinigba naa wọ inu ilu Akeugbagold, ti wọn si ji awọn ọmọ rẹ to jẹ ibeji gbe lọ.

Ọjọ kẹjọ ni awọn ajinigbe naa to tu awọn ọmọ naa to jẹ ọmọ ọdun meji gbe, lẹyin ti iroyin sọ pe miliọnu mẹrin Naira ni wọn gba lọwọ awọn obi wọn.

Ko pẹ si asiko naa ni ọwọ tẹ awọn afurasi ajinigbe naa, ti ọkan lara wọn jẹ oṣiṣẹ Akeugbagold.

Awọn ti ọwọ tẹ ni Ridwan Taiwo, Rafiu Mutiu , Olumide Ajala , Rafiu Modinat, Bashiru Mohammed ati Opeyemi Oyeleye.

Rafiu Modinat to jẹ obinrin laarin wọn lo n ba wọn tọju awọn ọmọ naa ni ahamọ.

Nigba to n ba BBC sọrọ lori idi to fi jawọ ninu ẹjọ naa, Sheik Akeugbagold sọ pe oun ṣe bẹ nitori pe oun tẹle ọkan lara awọn ilana ẹsin Islam, to jẹ idariji.

O ṣalaye pe wọn ti bẹ oun laimọye igba fun idariji.

O ni nkan akọkọ ni pe awọn ọmọkunrin naa ti fi ami ẹni to ronu piwada han lori nkan ti wọn ṣe.

"Ki n ran wọn lọ si ẹwọn ko tumọ si pe wọn yoo yi iwa pada. O yẹ ki wọn o ti yiwa pada laarin oṣu mẹsan-an ti wọn lo ni ahamọ.

"Gẹgẹ bi olori ẹlẹsin, Islam kọ mi lati ni ẹmi aforiji, mo si gbọdọ tẹle ẹkọ ti mo n kọ awọn eeyan."

O sọ pe lootọ ni nkan ti wọn ṣe buru jai, to si yẹ ki wọn o ṣe ẹwọn, ati pe wọn ti ṣe adehun, wọn si fọwọ siwe pe awọn ko ni i de ibi ti oun ati ẹbi oun wa.

Nkan mii to tun tọka si ni pe wọn le pada di ogbontagi ọdaran ni ọgba ẹwọn, eyi ti ko dara.

Bakan naa ni Akeugbagold sọ pe oun gbadura pe ki oun o ma kabamọ pẹlu ẹbi oun lori pe oun tẹle ilana ẹsin Islam, lati dariji wọn.

O fikun pe oun ko fẹ ẹ gbọ nkankan mọ lori ẹjọ naa, nitori pe gbogbo igba ti wọn ba ti lọ si ile ẹjọ ni wọn n pe orukọ awọn oun ati awọn ọmọ oun.

O ni "oore to gaju ti mo tun dupẹ lọwọ awọn ọkunrin naa ni ile ẹjọ lọjọ Aje ni pe wọn da awọn ọmọ mi pada fun mi laaye.

Ṣugbọn ṣa, adajọ ile ẹjọ naa ko ti i fun Akeugbagold ni esi lori ẹbẹ rẹ.