You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Ighoho kéde àwọn ọ̀daràn Fulani mẹ́ta tó ṣàkọlù sílé ìyá rẹ̀, ọwọ́ tẹ ọ̀kan, méjì na pápá bora
Gbajugbaja ajijagbara, Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti kede pe awọn ọdaran Fulani mẹta kan ti ṣakọlu sile iya oun to wa niluu Igboho, nipinlẹ Oyo.
Igboho ni ọwọ tẹ ọkan lara awọn afurasi naa, wọn si ti faa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, nigba ti awọn meji to ku na papa bora.
Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi, o ni lootọ ni afura kan ti wa ni ahamọ awọn, iwadii si ti bẹrẹ lati mọ okodoro iṣẹlẹ ọhun.
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí 23 fún Adebimpe Oyebade rèé
- Àwa ọmọ ìpínlẹ Ondo kò nífẹ́ sí Yoruba Nation, ọmọ Naijiria ni wá- Akeredolu
- Ìdí tí Ọba Aládé ò ṣe gbudọ̀ gbè lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Oduduwa Republic rèé láì bi Alálẹ̀ ilẹ̀ - Olubadan
- Omi Àgbọn, Ọsàn wẹ́wẹ́, ìbẹ́pẹ àtàwọn ohun mẹ́rin mìí tóo gbọ́dọ̀ mu lásìkò ẹ̀run rèé
- 'Ìjọba Kwara kàn fẹ́ fi ọ̀rọ̀ Hijab dá ìjà sílẹ̀ láàrin Krìstíẹ́ní àti Mùsùlùmí ni'
- 'Ẹ wá gbé àwọn òkú yín o! A ò ráyè kó òkú sí mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... - Aláṣẹ Mọ́ṣúárì Ilorin
- Ọsẹ̀ méjì péré là fún ẹyín darandaran láti forúkọsílẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Ìjọba Ekiti
Ẹwẹ, minisita ileeṣẹ to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu tẹlẹri, ti awọn eeyan tun n wo gẹgẹ bii alatilẹyin Sunday Igboho, Femi Fani-Kayode naa tun kede ọrọ naa loju opo Twitter rẹ.
O ni "mo ṣẹṣẹ ba Sunday Igboho sọrọ tan ni, o si sọ fun mi pe ọwọ tẹ awọn Fulani meji to jẹ ọmọ ilẹ okeere nile iya oun to wa ni Igboho, nipinlẹ Oyo."
"Afojusun awọn Fulani naa ni lati ṣakọlu si iya agba ọhun, ọkan ninu wọn sa asala ṣugbọn ẹnikeji rẹ ti wa ni gbaga ọlọpaa."
Lẹyin naa lo fi oju afurasi naa lede loju opo ọhun.
Ṣaaju ni agbẹnusọ fun Ighoho, Olayomi Koiki ti kọkọ kede iroyin naa, to si sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ku iṣẹju diẹ.
Ti ẹ ko ba gbabgbe, Sunday Igboho ati awọn ẹmẹwa rẹ ti kọkọ kede pe awọn mu awọn eeyan meji kan, ti ọkan jẹ ọmọ ogun, to si fẹsun kan awọn eeyan naa ope wọn wa ṣe ami oun.
Ṣugbọn ko pẹ si asiko naa ti ileeṣẹ ologun fesi pe eni tim wọn mu ninu aṣọ ṣọja kii ṣe oṣiṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun.
- Bí mo ṣe sáré ibùsọ̀ Kìlómítà 1,500 tí mo fi bọ́ lọ́wọ́ agbébọn - Gómìnà Ortom Benue
- O kéré sí Number! 'Àwa ológún ò fi ara wa wọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti máa ṣe alamí lórí irú ẹ Sunday Igboho'
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Háà! Ọkùnrin méjì fipá bá obìnrin kan lòpọ̀ nínú ọkọ̀ lójú àwọn ọmọ rẹ̀ lójú pópó