Iskilu Wakili: Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Iskilu Wakili, 'Balógun Fulani' tí OPC mí ní Ayetẹ ìpínlẹ̀ Ọyọ

Igba akọkọ kọ niyii ti orukọ Iskilu Wakili n jade ninu iroyin.

Botilẹ jẹ pe lọjọ Aiku to kọja ti ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ba a ni ọpọ to o gbọ nipa rẹ.

Ninu oṣu Keji, ọdun 2020 ni iroyin ti kọkọ jade nipa rẹ lẹyin ti Sunday Igboho fun awọn Fulani ni gbedeke lati kuro ni ilu Igangan nipinlẹ Oyo.

Gbedeke naa lo yọri si bi Seriki Fulani, Abdulkadri Saliu, ṣe kuro ni ilu naa.

Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ nigba naa ni pe awọn darandaran Fulani tun kọlu awọn agbẹ ni ilu Ayetẹ.

Awọn araalu ọhun sọ fawọn akọroyin pe Fulani kan ti orukọ rẹ n jẹ, Iskilu Wakil lawọn sọ fun pe ko fi ori ilẹ to wa silẹ nitori ko ra ilẹ naa lọwọ ẹnikankan.

Eleyi ni iroyin sọ pe o bi Wakil ninu ti o si bẹrẹ si ni leri pe oun ni oriṣiiriṣii ohun ija oloro lakata oun.

Iskilu Wakili ni ẹni ti awọn eeyan gbagbọ pe o tun l'agbara julọ laarin awọn Fulani to wa ni agbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo.

Iroyin sọ pe oun ni olori gbogbo awọn daran-daran Fulani ni agbegbe Ayetẹ.

A gbọ pe koda, baalẹ agbegbe naa, Baale Odomofin fun Wakili ni gbedeke lati kuro ni agbegbe ọhun.

Taa ni Iskilu Wakili?

Iroyin sọ pe ọdun mejidinlogun sẹyin lo de ilu Ayetẹ, ni agbegbe Ibarapa nipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi daran-daran.

Wakili si ti to ẹni ọdun marundinlọgọrin.

Gẹgẹ bi awọn iwe iroyin abẹle kan ṣe sọ, Iskilu Wakili ko gba aṣẹ lọwọlọwọ ẹnikẹni, to fi tẹdo si ilu naa, pẹlu ọpọlọpọ daran-daran to n ba a ṣiṣẹ.

Iga Wakili ni wọn pe orukọ agbegbe ibi to tẹdo si. Eyi to tumọ si pe agbegbe tabi ibugbe Wakili.

Oriṣiriṣi ẹsun bi fifi ipa gba ilẹ, ijinigbe ati ipaniyan si ni awọn eeyan fi n kan.

Awọn iroyin kan ti ẹ sọ pe Wakili ti gbe igi di awọn agbegbe kan to jẹ oko ni ayika ibi to n gbe, pe awọn agbẹ ko gbọdọ de ibẹ mọ, lẹyin ti Seriki Fulani sa kuro ni Igangan.

Eyi ni wọn sọ pe o waye lẹyin ti Seriki Fulani ni Igangan kuro ni ilu.

Awọn kan gbagbọ pe Wakili n lo agbara ibilẹ oogun abẹnu gọngọ ati nkan ijagun lati daabo bo ara rẹ.

A gbọ pe o ni ọmọkunrin kan, Abu, ti oun naa jẹ akinkanju 'jagunjagun bi i baba rẹ'.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gbọ nipa rẹ ri

Ọrọ kan ti ọwọ BBC Yoruba tẹ lori ayelujara Twitter fihan pe arakunrin kan, Omo Arijo Sebi Oba lori Twitter ti pe akiyesi ijọba ipinlẹ Ọyọ si ọrọ Iskilu Wakili ri.

Ninu ọrọ naa lo ti fẹsun kan pe Wakili n halẹ mọ awọn ara ilu Ayetẹ to fun ni gbedeke lati kuro ni ilẹ wọn tabi ko san owo ilẹ to n gbe.

Ẹka to n ri si ijiroro laarin araalu ati ijọba ipinlẹ Ọyọ lori Twitter da ọkunrin naa lohun pe awọn yoo fi ẹdun ọkan rẹ nipa Iskilu Wakili ranṣẹ si awọn ẹka ti yoo gbe igbesẹ lori rẹ.

Bakan naa ni awọn iwe iroyin abẹle sọ ninu oṣu Kinni ọdun pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ko awọn oṣiṣẹ ajọ Amọtẹkun bi igba lọ si ilu Ayetẹ, lati koju Iskilu lẹyin ti ijọba gbọ iroyin nipa iṣẹ rẹ.