You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Hisbah Kano fi òfin de lílo èdè 'Black Friday', àwọn ọmọ Naijiria kan yarí lórí ayélujára
Àjọ Hisbah tó jẹ́ ọlọ́pàá Sharia ní Kano kọ lẹ́tà ìkìlọ̀ lórí lílo èdè 'Black Friday'.
Ajọ to n ṣamojuto Ofin Sharia nipinlẹ Kano, Hisbah, ti kọ lẹta si ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ kan to wa nipinlẹ naa, lori lilo àṣà 'Black Friday'.
Ninu lẹta naa ti ajọ Hisbah kọ, o ni ọjọ Mimọ ni ọjọ Jimọ jẹ ninu ẹsin Islam, nitori naa pipe e ni ọjọ dudu jẹ nkan iwọsi.
- 'Black Friday' àyájọ́ ẹ̀dínwó ọjà tó gbá ayé kan
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
- Òbinrin kan fẹ́ ọkọ méjì torí ọkọ àkọ́kọ́ rìnrìnàjò fún ọdún méjì péré
- Olórin Kano tí wọ́n dájọ́ ikú fún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
- Awakọ̀ Maruwa tó bá gbé okùnrin àti obìnrin papọ ní Kano yóò jẹ búlálà mẹ́wàá- Hisbah
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara
Wọn sọ ninu lẹta naa pe "Musulumi ni ọpọ awọn to n gbe nipinlẹ Kano, ti wọn si ka ọjọ Jimọ si ọjọ Mimọ.
Hisba ni: "Nitori eyi, a rọ yin lati fi opin si pipe ọjọ naa ni 'Black Friday', ni kiakia.
"A si fẹ ki o ye e yin pe awọn ọlọpaa Hisbah yoo ma a tọ pinpin lati le dena lilo ede naa, ati lati le jẹ ki alaafia ati irẹpọ wa nipinlẹ Kano."
Alayee re e lori nkan ti Ọjọ́ Black Friday jẹ ni agbaye
- Black Friday ni orukọ ti wọn n pe ọjọ Ẹti to ba tẹle ọjọ idupẹ 'Thanksgiving Day' nilẹ Amerika.
- Ọjọbọ kẹrin ninu oṣu Kọkanla lọdọọdun ni wọn maa n ṣe e.
- Ọjọ Black Friday yii ni awọn ile itaja maa n ta awọn ọja wọn ni ẹsinwo.
- Gbogbo agbaye si ni awọn onile itaja ti maa n lo ede yii.
- 'Black Friday' àyájọ́ ẹ̀dínwó ọjà tó gbá ayé kan.
- Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, si ni Black Friday ti ọdun 2020.
Awọn wo ni Hisbah?
Ọjọ ti pẹ ti orukọ ajọ Hisbah ti n jẹyọ ninu iroyin, paapaa ni awọn ipinlẹ to wa ni Ariwa Naijiria.
Ọrọ lẹta ti wọn kọ yii si ti n fa ariyanjiyan lori ayelujara Twitter.
- Fatai Rolling Dollar, Ọmọ ìdílé oyè tó gbé igbá orin tí Ebenezer Obey ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀!
- Kí lo mọ̀ nípa ìbẹta kan ṣoṣo tí Alaafin Oyo bí? Wọ́n pé ọdún méjìlá báyìí
- Elon Musk, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ SpaceX, Tesla CEO ń bá Bill Gates du ipò ẹni tó lówó jùlọ ṣèkejì lágbayé
- Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé
Ninu ọrọ rẹ, @DrOlufunmilayo lori Twitter sọ pe "Black Friday ma n ran awọn ontaja lọwọ. O si n ran awọn eeyan to ku diẹ kaato fun lọwọ.
"Ti ẹ ba fi opin si black Friday, yoo pa okoowo lara, ati awọn talika to yẹ ko ra nkan ni ẹdinwo."
@Sunnyyon ni ti s pe boti lẹ jẹ pe oun kii ṣe ololufẹ ajọ Hisbah, oun naa ko fẹran àṣà 'Black Friday'. O ni o y ki Naijiria naa ni awọn ọjọ isinmi ti ẹ.
Oriṣiriṣi iwa 'to ba tako ẹsin Islam' ni wọn ma n mu awọn eeyan si, ti wọn si ma n fi ofin Sharia ṣe idajọ wọn.
Laipẹ yii ni iroyin sọ pe wọn dana sun awọn ọti lile.
- Ọmọbìnrin tó tayọ nínú ìdànwó WAEC ọdún 2019 pẹ̀lú A1 méje ti kú
- Nàìjíríà fohùn ránṣẹ́ padà sílé aṣofin UK pé ọ̀rọ̀ EndSars kò sí lẹ́nú wọn láìgbọ́ ìwádìí tán!
- Orúkọ Aisha Yesufu náà wọ inú BBC 100 Women tí a fi ń sọri àwọn obìnrin tó pegedé ní 2020
- Ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù rèé kó tó dágbére f'áyé
- Omotara kan ìdin nínú iyọ̀, àwọn ọmọ ilẹ̀ Faranse náà bínú síi nítorí alágbe tó fi ṣe yẹ̀yẹ́.