Nigeria Police: Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá ní kí àwọn ọlọ́pàá jà fún ara wọn

Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu ti paṣẹ fun awọn ọlọpaa kaakiri lati gbe ija ara wọn ja, ti ẹnikẹni ba kọju ija si wọn ni igbooro.

Ọga Adamu sọ eyi lasiko to n kaakiri awọn ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

Adamu ni ki awọn ọlọpaa naa tẹramọṣẹ, ki wọn si huwa to dara fun awọn araalu, amọ ki wọn koju oro si ẹnikẹni to ba kọju ina si wọn.

'' Mo gba yin nimọran lati ṣiṣẹ karakara, ki ẹ si ṣiṣẹ yin gẹgẹ bi iṣẹ, amọ ti ẹnikẹni ba fi ọwọ kan yin, ẹ gba ara yin la.

''Igbelarugẹ ati iṣọkan orilẹede yii wa lọwọ awọn araalu to ba ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ọlọpaa,''

''Amọ, ti iwa ọmluwabi ba sọwọ lawujọ, ti awọn janduku si gbajọba, ko ni si alaafia lorilẹede Naijiria mọ.''

Bakan naa ni Ọga ọlọpaa, Mohammed Adamu naa sọ fun wọn wi pe bi awọn eniyan tilẹ bu wọn tabi sọrọ kubakugbe si wọn, iyẹn ko to lati jẹ ki awọn ọlọpaa ma ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lorilẹede Naijiria.

Ọmọ ọdún mọ́kànlá tó bá wọn fọ́ àgọ́ ọlọ́pàá, wọ gàù ọlọ́pàá ní Edo

Ọmọ ọdun mọkanla kan ti awọn ọlọpaa ni o wa lara awon janduku to kọlu ileeṣẹ olopaa kan ni ipinlẹ Edo nibi to ti wọ aṣọ iṣẹ sajẹnti kan ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii.

Wọn ni o ti n jẹwọ fun ọlọpaa bayii ohun to mọ nipa bi wọn ṣe fọ agọ ọlọpaa naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Edo, SP Chidi Chibuzor salaye fun BBC pe ọmọ ọdun mọkanla naa wa lara awọn janduku to fọ ile ikonkan pamọ si kan, aṣọ ọlọpaa lo si wa lọruun rẹ nigba ti ọwọ agbofinro tẹ ẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan n sọ pe ọmọdekunrin naa wa lara awọn janduku to kọlu agọ ọlọpaa Ọba market, lẹyin ikọlu naa si ni o gbe aṣọ iṣẹ sajenti naa wọ to si n.pe ara rẹ ni ọga ọlọpaa orilẹede Naijiria.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Chibuzor fidirẹ mulẹ fawọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan pe lootọ lọmọ naa wa lara awon to kọlu ileesẹ ọlọpaa naa sugbọn " a muu ninu aṣọ iṣẹ ọlọpaa sajẹnti naa.

Fọto ọmọdekunrin naa nibi to joko si nilẹ ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu aṣọ iṣẹ sajenti naa lọrun rẹ ti lu ori ayelujara pa ṣugbọn alukoro ileeṣẹ olopaa nipinlẹ Edo ni awọn ko ṣe afihan ọmọ ọdun mọkanla naa pẹlu awọn janduku ti wọn fihan lọjọbọ nitori ọjọ ori rẹ.

Oni wọn yoo fa a lọ si ọgba ẹwọn awọn majesin tọjọ orí wọn ko ju ọdun mejidinlogun lọ gẹgẹ bi ilana ofin ṣe laa kalẹ.

Awọn janduku ja iwọde alafia lati tako iwa kotọ awọn ọlọpaa SARS #EndSARS ti wọn si lo anfani naa lati kọlu awọn kọlu ọgba ẹwọn, agọ ọlọpaa, awọn ile ikonkan pamọ si ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ipinlẹ naa.

Awọn ọlọpaa n'ipinlẹ Edo ni awọn janduku naa dana sun agọ olopaa, wọn ji ibọn ati ọta ko, wọn fipa ba awọn obinrin lo pọ l'awọn agbegbe kan, wọn pa ọlọpaa fọ ile onile ati ṣọbu oniṣọbu.