You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Iléèṣẹ́ ààrẹ̀ Nàìjíríà sọ pé ọ̀rọ̀ òṣèlú ni sísọ́ pé dandan ní kí Buhari bá ọmọ Nàìjíríà lórí coronavirus
Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti sọ pe pe ko si nkan to yẹ ki aarẹ Muhammadu Buhari ṣe lori arun coronavirus ti ko ti i ṣe.
Oluranlọwọ agba fun aarẹ lori iroyin ati ipolongo, Garba Shehu sọ ninu atẹjade kan pe ọrọ oṣelu ni bi awọn kan ṣe n bu aarẹ nitori pe ko ti i ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori amohunmaworan.
"Iwa ti ko ṣe e gbọ seti, ati ọrọkọrọ to n jade lẹnu awọn kan, paapa awọn aṣofin to n fi ẹsun kan aarẹ pe ko ja ọrọ naa kunra nitori pe ko ti i ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori amohunmaworan."
Ileeṣẹ aarẹ tẹsiwaju pe kii ṣe asiko yii lo yẹ ki awọn eniyan o maa bu aarẹ, ṣugbọn o yẹ ko jẹ akoko iṣọkan tako arun naa.
Garba shehu sọ pe lootọ ni Naijiria n dojukọ itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus bi gbogbo orilẹ-ede to ku lagbaye, ijọba Muhammadu Buhari si ti gbe awọn igbesẹ kan lati din ipa rẹ ku lara awọn ọmọ Naijiria.
Awọn nkan to ka silẹ re e pe aarl ti ṣe lati din ajakalẹ arun naa ku ni Naijiria:
- Ka le mu adinku ba laarẹ ṣe paṣẹ ki wọn o fofin de awọn arinrinajo lati orilẹ-ede mẹtala, to ni ju ẹgbẹrun eniyan to ni arun naa lọ.
- Ijọba tun ti dawọ fifun awọn ọmọ orilẹ-ede naa ni fisa. Ogunjọ oṣu kẹta si ni aṣẹ naa yoo bẹrẹ iṣẹ.
- Awọn ileeṣẹ iroyin ati ajọ to jẹ tijọba ti n ṣe ọpọlọpọ ipolongo imọ toto.
- Bẹẹ ni eto ayẹwo to l'agbara wa ni papakọ ofurufu ati ibudokọ ori omi to wọ Naijiria.
- Awọn igbesẹ ti a gbe yii, bi ẹyin naa ṣe mọ, ti gba ọrọ kare ọmọ ọdọ rere lati ọdọ ajọ eto ilera l'agbaye, WHO.
- Awọn igbesẹ ti a ti gbe n ṣiṣẹ daradara, ti awọn miran si n wo awokọṣe wa.
- Aarẹ tun paṣẹ fun ileeṣẹ eporọbi Naijiria, NNPC, lati din owo epo bẹtiro ku. Arun Covid-19 yii naa lo mu ki owo eporọbi o din l'agbaye, aarẹ si pinnu pe gbogbo ọmọ Naijiria lo yẹ ko janfaani rẹ.
- Banki apapọ Naijiria naa kede pe oun yoo lo owo to le ni Tiriliọnu kan Naira, lati ya awọn olokoowo ti ajakalẹ arun naa ba okoowo wọn jẹ.
Lati igba ti arun naa ti wọ Naijiria ni ipe ti n jade lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria pe o yẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori arun naa lati fi wọn lọkan balẹ, bi awọn aarl to ku ṣe n ṣe kaakiri agbaye.