Coronavirus: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko rọ àwọn tó bá ọmọ Nàìjíríà tó k'árùn COVID-19 wọ bàlúù láti jókó sílé fún ọjọ́ mẹ́rìnlá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu isunsiwaju ere idaraya apapọ Naijiria to yẹ ko waye nipinlẹ Edo lọdun yii.

Minisita fere idaraya, Sunday Dare lo ti kọkọ keke isunsiwaju yii ko to di wi pe o tun fi kun un pe aarẹ Buhari funrarẹ kede rẹ.

O fi sori oju opo Ayelujara rẹ aarẹ fẹnuko lori igbesẹ naa lẹyin ipade kan to waye laarin minisita feto ilera, oun atawọn akọṣẹmọṣẹ miran lati ṣe agbeyẹwo ọwọja arun Coronavirus lori ere idaraya naa.

Minisita fere idara jẹ ko di mimọ pe lẹyin ti wọn gbe kalẹ niwaju aarẹ lo jẹ ko gbe aṣẹ naa kalẹ lati dena itankalẹ arun naa.

Orilẹ-ede Naijiria ti kede pe ẹlomiran tun ti ni aarun Coronavirus nilu Eko.

Nibayii kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Tunji Abayọmi ti wa ke si gbogbo awọn ero ọkọ baluu BA 75 to gunlẹ si ilu Eko ni ọjọ kẹtala oṣu kẹta ọdun 2020 lati joko jẹẹ sinu ile wọn ki wọn si ya ara wọn sọtọ fun ọjọ mẹrinla.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko rọ àwọn tó bá ọmọ Nàìjíríà tó k'árùn COVID-19 wọ bàlúù láti jókó sílé fún ọjọ́ mẹ́rìnlá

Ẹni ti wọn ṣẹṣẹ kede yii ko ni nkankan se pẹlu ọmọ orilẹ-ede Italy to ko arun naa wọ Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Eko fi sita lọjọ Iṣẹgun ni wọn ti kede pe ẹni ọgbọn ọdun naa, to jẹ obinrin pada de si orilẹ-ede Naijiria lati United Kingdom, UK, ni ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta.

Nigba to de, o ya ara a rẹ sọtọ, lasiko to bẹrẹ si ni ri awọn apẹẹrẹ arun naa.

Esi ayẹwo to ṣe nileewosan si fihan pe o ni arun Coronavirus lara.

Nibayii, ijọba sọ pe o ti wa nileewosan Mainland General Hospital, nibi ti wọn ti n tọju rẹ.

Ẹnikẹta niyii ti wọn yoo kede pe o ni arun naa ni Naijiria.

Ọmọ Italy kan lo kọkọ gbe e wọle. Lẹyin naa ni wọn kede ẹnikan to ni nkan ṣe pẹlu ọmọ orilẹ-ede Italy naa nipinlẹ Ogun.

Ijọba sọ pe awọn meji akọkọ ti n gbadun nileewosan. Ireti si wa pe wọn yoo yọnda wọn kuri nileewosan l'ọsẹ yii.