BB Naija: ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lágboólé Olanrewaju Malcolm, olólùfẹ́ Bisọla rí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Olanrewaju Malcolm, baba ọmọ Bisola Aiyeola to kopa ninu idije Big Brother Naija ni a gbọ pe o ti ku.

Malcolm to jẹ alakoso oṣere nigba aye rẹ niroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe o ku laarọ oni, ọjọ Abamẹta si ile iwosan kan ni agbegbe Surulere, nilu Eko.

Iroyin naa sọ pe ọgbẹni Malcolm papoda lẹyin ti o ti ba aisan kan finra fun ọjọ pipẹ ni ẹni ọmọ ọdun mẹtadinlogoji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi ni ọrọ asọkẹyin oloogbe lori opo Instagram rẹ ni yi pe, iyipada ti de ba oun.

Ilẹ n jeeyan, ko si awaye-ma-lọ.