You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba lù wá ní jìbìtì, gba ilẹ̀ wa - Àwọn olùgbé ìlú Ibadan figbe ta
Awọn olugbe ileto to to ọgbọn lagbegbe ijọba ibilẹ Akinyele nilu Ibadan lo ti rọ Aare Muhammadu Buhari ati Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lati yọ awọn ninu igbekun awọn to fẹ fipa gba ilẹ abinibi wọn lai san owo gba ma binu.
Awọn olugbe ileto Orisunmibare salaye wi pe iwe sọwedowo ti wọn kọ fun awọn kọọkan lara awọn ti ijọba gba ile ọhun lọwọ wọn ni ko ri owo ọhun gba nile ifowopamọ.
Ilẹ agbegbe Orisunmibare ati awọn ilẹ miran tijọba gba lo le ni ọọdunrun sare, ti awọn olugbe ibẹ si rọ ijọba lati mu ileri rẹ sẹ, ki awọn ma ba a kabamọ wi pe awọn fun ijọba nile abinibi awọn.
Nigba ti wọn n ba akọroyin BBC sọrọ, Balogun Oluwaseyi, Akorede Sikiru, Magareth Akerele, Tunji Adepoju salaye wi pe awọn ibudo to le ni ọgbọn ni ijọba gba lati ọdun 2019 ti wọn si kọ lati san owo gba ma binu fun awọn ti ọrọ kan.
Balogun ni “ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo ti dẹti ninu adehun ti wọn ba wa sẹ nigba ti a gba lati yọnda ilẹ wa fun wọn."
"Diẹ ninu wa ni wọn ti pe si ile isẹ ijọba ipinlẹ Oyo to n ri si ọrọ ilẹ, asẹyinwa asẹyinbọ, iwe sọwedowo ti wọn fun wa ni banki ni ko sowo ninu asuwọn naa."
"Awọn to nilẹ ati ile to le ni miliọnu mẹwaa ni ijọba fun ni iwe sọwedowo miliọnu meji."
"Ẹni ti o ni ilẹ sare mẹrin ti kọọkan wọn to milliọnu kan lode oni ni ijọba fun ni ẹgbẹrun marunlelogoji eyi ti ko wa ni ibamu pẹlu dukia rẹ ti ijọba gba”.
Morufat Sumonu ninu ọrọ rẹ ni “gbogbo ilẹ ti ijọba gbẹsẹ le ti ko si tun si olugbe nibẹ lo ti di ile fun awọn ẹni ibi, awọn janduku ati awọn a lọ kolohun kigbe ni wọn ka awọn mọ ile tọsan toru."
Igbiyanju lati ri aridaju ẹsun wọn yii lọwọ ile iṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilẹ ati ile lo ja si pabo.
Awọn ileto ti ọrọ naa kan ni Alausa, Orisunmibare, Oguntilewa, Jooye, Lapite, Ishabi, Ketepe, Akinbode, Oloje, Adamaro, Sonle, Apata, Dedun, Ojedeji to wa lagbegbe ijọba ibilẹ Akinyele, Ibadan.
Ọdun 2019 ni ijọba apapọ ati ipinlẹ Oyo ti gba awọn Saare ile naa lati kọ papakọ reluwe ati papakọ igbẹru si.