You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Obìnrin tó ṣekúpa ọlọ́pàá méjì, ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àtijọ́ àtàwọn mẹ́sàn án míì dèrò àgọ́ ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa Bangkok ti sọ pe awọn ti fi ṣikun ofin mu obinrin kan lori ẹsun pe o ṣekupa awọn ọrẹ rẹ mejila pẹlu majele ‘cyanide.’
Wọn mu Sararat Rangsiwuthaporn lẹyin iwadii iku ọkan ninu awọn ọrẹ rẹ ọhun.
Iroyin ni awọn mọlẹbi oloogbe ọhun ti kọkọ fura si Sararat lẹyin ti wọn jọ rinriajo kan ni ibẹrẹ oṣu yii.
Lẹyin ọpọ iwadii, ọlọpaa ni awọn fura pe Sararat lọwọ ninu iku ologbe naa, to fi mọ awọn mọkanla mii, eyii ti ọrẹkunrin rẹ atijọ wa ninu wọn.
Bo tilẹ jẹ pe afurasi ọhun ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun, ijọba ilẹ naa ti kọ lati fun ni beeli.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ
Nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin ni afurasi atawọn ọrẹ rẹ rinrinajo lọ si Ratchaburi, nibi ti wọn ti lọ ṣadura labẹ ẹsin Budah fun abo.
Ko pẹ lẹyin adura naa ni ọkan lara awọn ọrẹ rẹ, Siriporn Khanwong, dede ṣubu lulẹ, to si ku leti odo ti wọn ti lọ ṣadura.
NInu iwadii, ọlọpaa ni awọn ṣawari majele ‘cyanide’ ninu agọ ara rẹ, bẹẹni apo ilewọ rẹ, owo ato ẹrọ ilewọ oloogbe naa di awati.
Awọn alaṣẹ ni irufẹ ọna kan naa ni awọn ọrẹ afurasi naa to di oloogbe ṣe jade laye.
Lati ọdun 2020 ni aẉọn ọrẹ Sararat ti n fo ṣanlẹ ku lọọkan ejeji.
Lara awọn to ku ni ọrẹkunrin afurasi naa nigba kan ri, ọlọpaa meji ti wọn jẹ obinrin, atawọn mii ti wọn ko fi orukọ wọn lede.
Ọlọpaa ni iwadii awọn fi han pe ọrọ owo lo mu ki afurasi ọhun maa gbẹmi awọn ọrẹ rẹ, amọ iwadii ṣi n tẹsiwaju.