Wo kókó tó wà nínú òfin àtúnṣe ìdókòwò epo rọ̀bì àti gáàsì tí Tinubu buwọ́lù

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, ASIWAJU BOLA AHMED TINUBU/FACEBOOK

Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Bola Tinubu buwọlu iwe aṣẹ lori atunṣe idokowo epo rọbi ati gaasi ni Naijiria ni Ọjọru.

Oludamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Ajuri Ngelale ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe Aarẹ Tinubu gbe igbesẹ yii lati mu irọrun ba idokoowo ni Naijiria.

Ngelale ni ofin ti Tinubu buwọlu yii yoo jẹ k'awọn olokoowo epo rọbi ati gaasi nilẹ Africa maa fẹ maa ṣowo pẹlu orilẹ ede Naijiria.

Agbẹnusọ aarẹ tun fikun ọrọ rẹ pe igbesẹ yii yoo mu eto ọrọ-aje Naijiria gboro sii fun anfani awọn araalu.

Wọnyii ni awọn koko to wa ninu iwe aṣẹ atunṣe idokowo epo rọbi ati gaasi ti Tinubu buwọlu:

  • i. Akọkọ ninu koko to wa ninu ofin tuntun yii ni imoriya fun idokoowo gaasi orijina ati gaasi ti wọn n ri ninu epo rọbi lati isalẹ omi.
  • ii. Ṣiṣe adinku eto gbigbe iṣẹ idokoowo gaasi fun kọngila si oṣu mẹfa.
  • iii. Ṣiṣe amulo awọn nnkan ti kii ṣe ti ilẹ okeere laiṣe ipalara fun okoowo tabi iye ti okoowo yoo jẹ.

Ngelale sọ pe ileeṣẹ ijọba to n ri si eto iroyin ati ọgbọn inu yoo fi ẹkunrẹrẹ awọn koko yii lede laipẹ.

Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto idajọ, ẹka ijọba to n ri si eto iṣuna ati ti epo rọbi to fi mọ ileeṣẹ ijọba to n ṣagbatẹru eto iṣuna ati ọrọ-aje wa lara awon ileeṣẹ ijọba to ṣiṣẹ lori awọn koko to wa ninu ofin tuntun ti Tinubu buwọlu yii.

Ileeṣẹ ifọpo rọbi NNPCL, ajọ FIRS to n pawo wọle fun ijọba ati ajọ NMDPRC to n ri ọrọ epo rọbi lori ilẹ ati ninu omi l'awọn ẹka ijọba mii to ṣe agbekalẹ ofin tuntun lori idokoowo gaasi ati epo rọbi.