Ilé ẹjọ́ fi èèyàn mẹ́tà sí ẹ̀wọ̀n fún lílọ́wọ́ nínú ìbúgbàmù tó wáyé nílùú Ibadan

Oríṣun àwòrán, JAMES IGBASAN
Ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Ibadan, ti ju arabinrin kan ati ọkunrin mẹta si ọgba ẹwọn, fun ipa ti wọn ko ninu ibugbamu to waye niluu Ibadan ninu oṣu Kinni.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni ibugbamu nla naa waye, nibi ti awọn eeyan ti ku, ti ọpọ si tun farapa.
Oriṣiriṣi ile nlanla lo tun wo lulẹ lasiko iṣẹlẹ naa to waye ni agbegbe Bodija.
Ileeṣẹ ọlọpaa gbe Ramatu Camara,ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, Ganiu Malik, ẹni ogun ọdun, ati Abubakar Samara, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, lọ si ile ẹjọ fun ẹsun lilo awọn nnkan ija to le pa ilu run, kiko awọn nnkan to le fa ibugbamu pamọ, ati awọn ẹsun mii.
Ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ni ijọba ipinlẹ Oyo kede sita pe ọwọ ti tẹ afurasi mẹta to lọwọ ninu isẹlẹ ibugbamu to waye ni Bodija nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi wọn.
Oludamọran si Gomina lori ọrọ eto abo, Fatia Owoseni lo kede ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Ibadan.
Owoseni ni eeyan mẹta ni iwadi ti fihan pe wọn lọwọ ninu ibugbamu naa, ti wọn yoo si foju ba ileẹjọ lori iwadi ti awọn agbofinro se.
O tẹsiwaju pe agbegbe Aderinola ni ibugbamu naa ti waye ki i se agbegbe Dejo Oyelese.
Bakan naa lo safihan orukọ nnkan to bugbamu naa, eyi to pe ni ‘Water Gel Type Based Explosive’ to si jẹ pe ina mọnamọna lo ma sokunfa ibugbamu naa.
O ni ẹrọ aworan CCTV to jẹ ti ọkan lara Ile ti ibugbamu naa kọlu lo tu asiri bi isẹlẹ naa se
Ọlọpaa to rojọ tako wọn nile ẹjọ sọ pe awọn mẹtẹẹta, ati awọn afurasi mii to ti salọ bayii, jẹbi ẹsun pe wọn ko awọn nnkan abugbamu sinu ile gbigbe kan, eyi to ṣekupa iya agba ẹni ọdun marundinlaadọrin, Bolanle Badmus, ati awọn mẹtala mii.
Adajọ ile ẹjọ naa, E.U Akpan, paṣẹ pe ki wọn o ko awọn afurasi naa si ọgba ẹwọn Agodi titi di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.
O ni igbesẹ wọn lodi si abala kẹrindinlọgbọn, ofin Naijiria to ni i ṣe pẹlu igbesunmọmi, ati idena rẹ.

Ki lo sẹlẹ saaju?
Iṣẹlẹ ibugbamu kan ti waye ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kinni ni agbegbe Adeyi Bodija ilu Ibadan.
Gẹgẹ bi awọn kan to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe sọ iro ibugbamu naa rinlẹ de awon agbegbe kaakiri ilu Ibadan ni nnkan bii agogo mẹjọ alẹ to waye.
Ṣe ni igboro daru ti ipaya si ba ọpọlọpọ awọn olugbe ibadan ni kete ti iro ibugbamu naa waye eyi to mi ọpọlọpọ agbegbe ilu nla naa lalẹ ọjọ Iṣẹgun
Lara awọn agbegbe ti irọkẹkẹ ibugbamu naa de ni Bodija, Agbowo, Ẹlẹyẹle, Orogun, ati General Gas .
Bakan naa lawon eeyan to wa lagbegbe bii Iwo road, Gate, Bẹrẹ Mokola ati bẹẹbẹ lọ pẹlu ni awọn pẹlu gbọ jinijini irọkẹkẹ ibugbamu ọhun.
Awọn fidio ati aworan to n jẹyọ lori ayelujara n se afihan awọn oku ti wọn gbe kuro lagbegbe naa .














