You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìlànà tuntun fún owó gbígbà ní báńkì - CBN
Gomina banki apapọ orilẹede Naijiria, Godwin Emefiele sọ pe asiko ti to ki eto ọrọ aje Naijiria lati kuro ni ti owo beba bọ si lilo imọ ẹrọ di sanwo, eti ti oloyinbo n pe ni “cashless”.
Emefiele to sọrọ yii lẹyin ipade pẹlu aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ni ijọba apapọ ti ṣe idokowo owo to jọju fun imọ ẹrọ ro peye ati mu ki ayipada yii lọ nirọwọrọsẹ.
Oniruuru awuyewuye lo ri n waye lori eto iṣuna tuntun ti banki apapọ ṣẹṣẹ fi lede laipẹ yii ninu eyi to ti sọ iye owo ti eeyan lee gba lori kanta banki lojumọ di ẹgbẹrun lọna ogun naira ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira lọsẹ fun eniyan.
Emefiele ṣalaye pe “lati ọdun 2012 ni eto naa ti bẹrẹ ki o to si pe wọn ṣẹwe lee lawọn igna mẹta si mẹrin kan nitori pe a wo o pe o yẹ fun wa lati gbaradi daada lati rii pe eto imọ fun iṣuna ẹrọ gbilẹ daadaa lorilẹede Naijiria.
Laarin ọdun 2012 si 2022 a gbagbọ pe oniruuru ilana imọ ẹrọ Igbalode lẹkan banki ti gbilẹ too ṣi ran awọn to wa lẹkan banki lọwọ pipọ.
“Gẹgẹbi ṣe jẹ orilẹede to ni ọrọ aje to robi julọ ni Afirika, Naijiria nilo lati bọ siwaju ila lilo imọ ẹrọ fun eto banki lorilẹede Naijiria. A ko le gba lati je ki ida marundinlaadọrun ninu ọgọrun iye idunadura ro n waye lẹka banki wa maa waye jinna si ikawọ banki wa.”
Iha ti banki apapọ Naijiria kọ si bi ile asofin apapọ ko ṣe fọwọ si ilanq naa
Gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele ni ko si idi fun awọn aṣofin apapọ lati maa beru nitori pe igbesẹ ti ayipada lee ba nigbakugba ni, nitori naa agbeyewo le baa laipẹ.
O woye pe kii ṣe inu sidun banki apapọ naa lati fi iya jẹ awọn ọmọ Naijiria, ohun ro n lepa naa ni idagbasoke eto ọrọ aje.
O run fi kun un pe bqnki apapọ naa too gbe orukọ awọn agbodegba rẹ ri too maa ṣakoso bi gbigba owo atijọ fi owo tuntun rọpo lawọn igberiko sita.
Gomina banki apapọ orilẹede Naijiria naa ni miliọnu kan ati irinwo ni iye awọn agbodegba naa ati pe iye owo atijọ ri awọn eeyan ti da pada si awọn banki bayii ri le ni ẹẹdẹg ẹ́ta biliọnu naira.
Amoṣa, awọn aṣofin apapọ nile aṣofin soju nilu Abuja ti ranṣẹ pe adari banki apapọ orilẹede Naijiria naa lati fi oju han niwaju rẹ lati le wa sọ ti ẹnu rẹ.
Ilé aṣòfin pàṣẹ kí CBN dáwọ́ dúró lórí gbèdéke owó tí àráàlú le gbà lọ́sẹ̀
Ile aṣofin ti sọ fun banki agba Naijiria, CBN, lati dawọ duro lori gbedeke to fi le iyw owo ti araalu le gba jade ninu asunwọn wọn nile ifowopamọ.
Ọjọ Iṣẹgun ni CBN kede peawọn ọmọ Naijiria ko ni le gba ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira kuro ninu asunwọn wọn ni banki, laarin ọsẹ kan.
Awọn ileeṣẹ ko ni le gba ju ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta.
Yatọ si eyi, owo ti wọn le gba jade ninu asunwọn naa ko ni i ju ẹgbẹrun lọna ogun Naira lati ori ẹrọ POS lojumọ.
Awọn aṣofin nile igbimọ aṣoju-ṣofin ti ranṣẹ si Gomina CBN, Godwin Emefiele lati yọju si wọn fun alaye lori gbedeke naa.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti Aṣofin Aliyu Magaji, bẹrẹ ijiroro lori igbesẹ CBN, nibi ijoko ile aṣofin ni Ọjọbọ.
Pupọ ninu awọn aṣofin naa lo gbagbọ pe fifi gbedeke le iye owo ti araalu le gba jade ninu asunwọn wọn, yoo ni ipa ti ko dara lori okowo ati awọn ọmọ Naijiria ti ko ni anfaani si ile ifowopamọ.
Amọ ṣa, awọn kan tun gbagbọ pe igbesẹ CBN yoo dena iwa ọdaran.
Yatọ si eyi, owo ti wọn le gba jade ninu asunwọn naa ko ni i ju ẹgbẹrun lọna ogun Naira lati ori ẹrọ POS lojumọ.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kinni, ọdun 2023, ni ofin tuntun naa yoo bẹrẹ isẹ.
Ikede yii waye lasiko ti CBN n gbaradi lati ko owo Naira tuntun jade fun nina, bẹrẹ lati ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, dun 2022.
Ẹnikẹni ti yoo ba gba ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira laarin ọsẹ kan, gbọdọ ṣetan lati san ida marun-un owo to ba gba.
Awọn ileeṣẹ yoo san ida mẹwaa.
Bakan naa, sọwedowo (cheque) to ba le ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, ko nii jẹ sisan pẹlu owo.
Onitọhun ni lati gba a sinu asunwọn rẹ ni.
Fun gbigba owo jade lati inu ẹrọ ATM, gbedeke ẹgbẹrun lọna ogun Naira lojumọ ni CBN fi sita, ko si gbọdọ ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira laarin ọsẹ kan.
Bakan naa ni CBN tun sọ ninu ikede rẹ pe igba Naira (200 Naira) ati awọn owo to wa labẹ rẹ, nikan ni wọn o ma a ko sinu ẹrọ ATM.
Ṣugbọn ṣa, banki agba naa sọ pe ẹnikẹni tabi ileeṣẹ to ba ni eredi to jẹ ootọ, lati gba ju miliọnu marun-un Naira tabi miliọnu mẹwa Naira, yoo la iwadii alagbara kọja.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni CBN gbe owo Naira (200, 500, 1000) jade.