You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọba tí wọ́n jí gbé láàfin rẹ̀ nípìnlẹ̀ Ondo gba òmìnira
Iroyin sọ pe awọn ajinigbe ti yọnda kabiesi ilu Olóṣò ti Òṣò-Àjọwá, Ọba Clement Omoola Jimoh, ti wọn ji gbe ni ọsẹ to kọja.
Awọn ajinigbe tu silẹ lẹyin ọjọ meje ni ahamo wọn. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, SP Funmilayo Odunlami fi idi rẹ mulẹ ninu ifọrọwerọ tẹlifoonu pẹlu awọn akọroyin.
Ẹbi Oba Jimoh sọ fun awọn akọroyin pe Ọjọru ni wọn tu u silẹ, to si ti wa ni ileewosan fun itọju ara rẹ.
Awọn ajinigbe naa yabo aafin rẹ niluu Ajowa-Akoko, to wanijọba ibilẹ Akoko North-West, lọjọbọ ọsẹ to kọja, ti wọn si gbe e salọ.
Lẹyin naa ni awọn ajinigbe naa beere fun ọgọrun miliọnu Naira, gẹgẹ bi owo itusilẹ rẹ. Amọ, a ko le sọ boya ẹbi rẹ san owo naa ko to gba ominira.
Ohun tí a mọ̀ lórí bí awọn ajínigbé ṣe jí Ọba gbé lọ láàfin ní Ondo rèé
Lẹyin ti iroyin gbode wi pe awọn afurasi ajinigbe kan ya wọ aafin Olóṣò ti Òṣò-Àjọwá nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun-Ariwa Akoko ni Ipinlẹ Ondo ti wọn si ji Kabiyesi Ọba Clement Jimoh Olukotun gbe lọ.
Eyi lo mu ki BBC News Yoruba kan si aafin Oba naa lati fidi ohun to ṣẹlẹ nibẹ mulẹ gan-an.
Ọgbẹni Gani Muhammed Ajowa, to fi igba kan ri jẹ oluranlọwọ agba fun gomina Akeredolu lori eto iroyin sọ fun BBC Yoruba sọrọ wi pe ni nkan bii aago mẹwa kọja iṣẹju marun-un lalẹ ọjọbọ ni awọn agbebọn naa yawọ aafin.
Ajowa ṣalaye pe awọn ajinigbe naa ko ṣe meni ṣe meji ti wọn fi fibọn ba awọn ilẹkun ati dukia jẹ ki wọn to palẹmọ kabiyesi ọhun.
O ni gbogbo ara ogiri aafin ni awọn ajinigbe naa fi ọta ibọn da batani si eyi to si ko ipaya ba awọn to wa ni aafin lasiko naa ko to di pe wọn mu kabiyesi lọ.
O fi kun pe awọn ti n sa gbogbo ipa awọn lati ṣe awari ọba naa ki awọn si gba a kalẹ kuro lọwọ awọn ajinigbe yii.
Oluranlọwọ gomina tẹlẹ ri ọun ni gbogbo awọn ọdẹ ati aṣọde nilu Osó lo ti kan lu igbẹ lati tọ ipasẹ awọn ajinigbe naa ki wọn si lee gba ọba wọn pada.
Bakan naa lo fi kun wi pe awọn ṣi n reti ki awọn to ji ọba naa gbe lọ kan si awọn nitori awọn ni ireti wi pe wọn maa kan si awọn lati bere owo itusilẹ.
Àwọn Afurasí àjíǹigbe kó ìbọn wọ Ààfin, jí Ọba Aládé gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo
Awọn afurasi agbebọn kan ti a ko mọ ẹyẹ ti o ṣu wọn ni wọn ti ji Olóṣò ti Òṣò-Àjọwá nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun-Ariwa Akoko ni Ipinlẹ Ondo gbe lọ.
Ọba Clement Jimoh Olukotun ni iroyin fi ye wa pe awọn agbebọn naa wọle tọ ninu Aafin rẹ pẹlu oniruuru ibọn, ki wọn o to wọle lọ gbe Ọba.
Lasiko yii, gbogbo awọn mọlẹbi lo ti sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn mọlẹbi Kabiyesi to ba awọn akọroyin sọrọ wipe ni nkan bii aago mẹwa kọja iṣẹju marun lalẹ Ọjọbọ ni awọn agbebọn naa yawọ Aafin ti wọn si ba awọn ilẹkun ati dukia jẹ ki wọn to ji Kabiyesi ọhun.
"Wọn ba Ilẹkun iwaju afin jẹ ni lati fi ri aye wọle.
Awọn agbebọn naa leri si awọn mọlẹbi kí wọn to wọ Kabiyesi jade, ti wọn si ju wọn si ninu ọkọ.
"Ko si ẹnikẹni laarin wa ti awọn ajinigbe naa ti kan si sugbọn a mọ pe awọn ajinigbe ni wọn".
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC Yoruba wipe awọn ti bẹrẹ iwadi ni kikun lori iṣẹlẹ ọhun ti wọn si n gbiyanju lati doola ẹmi Ọba alaye naa.
Ẹwẹ, o fi kun un pe awọn ko ni ẹkunrẹrẹ alaye pe awọn to ṣe iṣẹ laabi naa ko ibọn wọ inu aafin lati wa ṣe iṣẹ ibi ọhun ṣugbọn awọn araalu ni wọn ko ibọn dani.