You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Orílẹ̀ èdè Peru ní Ààrẹ obìnrin akọkọ
Orilẹede Peru ti kede igbakeji Aarẹ to jẹ obìnrin gẹgẹ bii aarẹ tuntun lẹyin ti Ile Igbimo asofin orilẹede naa yoo aarẹ tẹlẹ Pedro Castillo kuro nipo.
Dina Boluarte, ẹni to jẹ obinrin akọkọ ti yoo jẹ aarẹ ni orilẹ ede Peru ni wọn bura wọle fun lọjọbọ ana.
Ṣaaju igbesẹ ile gbìnmọ aṣofin, Aarẹ tẹlẹ, Castillo ni oun fẹ parọ ile igbimọ aṣofin orilẹ ede naa pẹlu igbimọ miiran, eyi to pe ni "exceptional emergency government".
Igbesẹ yìí ni ko dun mọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ninu, ti wọn si kede yíyọ nipo rẹ lẹyin ipade wọn.
Kete ti wọn ṣe ikede naa ni awọn ọlọpaa mu aarẹ tẹlẹ naa lọ atimọle.
Boluarte, ẹni ọgọta ọdun to jẹ agbẹjọro ni oun yoo wa ni isakoso isejọba orílẹeede Peru di oṣu keje ọdun 2026 to jẹ akọkọ ti saa aarẹ tẹlẹ Castillo yoo pari. Nígba to n sọrọ lẹyin to ṣe ìbúra, Boluarte ni oun nilo akoko lati fi bori awọn ìṣoro to n koju Orilẹede naa.
"Nnkan ti mo beere fun ni aaye ati akoko lati gba Orilẹede wa silẹ.