Oba Adewumi Ogunleye: Nítorí ìfẹ́ ìlú àti ọ̀dọ́ ni mo ṣe padà sílé ẹ̀kọ́- Oba Towulade

Pínpín ọrọ̀ Naijiria lọ́gbọọgba ni ọna abayọ si iṣoro wa kìí ṣe ki a pin lọtọọtọ- Oba Ogunleye

Kabiesi Towulade ilu Akinhale ni ipinlẹ Ogun gba BBC Yoruba lalejo.

Nibẹ ni Oba Adewumi Ogunleye ti sọ ohun ti oju rẹ ri ko to fi agba ara pada silẹ ẹkọ.

Nibẹ lo ti kọ iṣẹ amofin to si lọ si 'Law School' to tun ṣe aṣeyege.

Oba sọ bo ṣe tori ifẹ ilu ki oun le maa ṣe idajọ ododo to tun pada lọ gab oye sii titi dori ọmọwe nipa iṣẹ amofin.

Oba Towulade gba awọn ọdọ Naijiria ni iyanju pe ibẹrẹ kii ṣe oniṣẹ ati pe ko si igba ti a daṣo ti a ko rilẹ fi wọ.

Bakan naa lo sọrọ lori iyapa ni Naijiriia pẹlu imọran fun awọn adari Naijiria pe ki wọn fi ootọ pin ọrọ Naijiria ki ọkan koowa le bale.