Agbẹjọ́rò Àgbà ní Iran yóò wọ́gilé ọlọ́pàá Sharia

Agbẹjọro agba fun orilẹ-ede Iran, sọ pe wọn ti tu ileeṣẹ ọlọpaa Sharia ka ni orilẹ-ede naa.

Mohammad Jafar Montazeri kede igbesẹ naa nibi ipagọ ẹsin kan lọjọ Aiku.

Amọ ko tii si ileeṣẹ ijọba tabi agbẹnusọ to fidi iroyin na mulẹ.

Lati oṣu Kẹsan-an ni iwọde ti n waye ni Iran, nitori bi ọdọbinrin kan sẹ ku si ahamọ ọlọpaa Sharia.

Mahsa Amini ku lẹyin ti awọn ọlọpaa na mu fun ẹsun pe ko wọ ijaabu.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an ni wọn mu Amini, o si ku ni ọjọ kẹta.

Ọgbẹni Montazeri sọ pe ẹka ọlọpaa Sharia naa ko ni ohunkohun ṣe pẹlu ẹka idajọ.

“O si ti di tituka, lati orisun to ti bẹrẹ.”

Amọ ṣa, ileeṣẹ ọrọ abẹle lo ni aṣẹ lori awọn agbofinro, kii sẹ ẹka idajọ.

Bakan naa ni Ọgbẹni Montazeri sọ fun ile igbimọ aṣofin lọjọ Satide pe, ki wọn o ṣe agbeyẹwo ofin to pa a ni dandan fun awọn obinrin lati ma a wọ ijaabu.

Amọ ko daju pe fifi opin si ọlọpaa Sharia, yoo fi opin si ofin ataye-baye naa.

Iku ọmọ ọdun mejilelogun naa lo pilẹ awọn iwọde lati fi ẹhonu han lori aisi iṣẹ, òṣì, aisi idajọ ododo, iwa ibajẹ, ati aidọgba.

Nitori naa ni ko ṣe daju, boya opin yoo de si iwọde naa, ti iroyin fifi opin si ọlọpaa Sharia ba fi jẹ otitọ.

Ọpọ awọn obinrin to n ṣe iwọde ọhun dana sun awọn ijaabu wọn.

Ẹnikan lara wọn sọ fun BBC pe ko si nkan to n jẹ ijaabu lọrọ awọn mọ, nitori pe awọn ti n jade lai lo o fun aadọrin ọjọ.

“Ayipada nla lo de ba wa. Lootọ ọrọ ijaabu lo pari rẹ, amọ nkan ti a fẹ bayii ni iku ijọba apaṣẹ wa a , ati ijọba tuntun.”

Oriṣiriṣi ọlọpaa Sharia ni Iran ti lo lati ọdun 1979 ti Ijijagbara Islam waye nibẹ, amọ eyi ti wọn n lo bayii, Gasht-e-Ershad, lo n mojuto awọn ofin to de ihuwa ninu ẹsin Islam.

Ọdun 2006 ni wọn bẹrẹ si lọ kaakiri orilẹ-ede naa, lati ri i daju pe awọn obinrin n wọ aṣọ to balẹ, wọn o gbọdọ wọ ‘jeans’ ti wọn ya ni ara, ati awọn aṣọ mii ti wọn ba wò pe ko ba ẹsin mu.