Wo àwọn àǹfààní tí irú ń ṣe fún ara

    • Author, Marvelous Obomanu
    • Role, Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọ̀kan lára àwọn èròjà tí Yorùbá máa ń lò láti fi mú kí ọbẹ̀ dùn ni irú jẹ́.

Àmọ́ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò mọ̀ ni pé yàtọ̀ sí adùn tí irú máa ń fún ọbẹ̀, ó jẹ́ èròjà tó máa ń pèsè àwọn ìlera kan fún ara tí èèyàn bá ń fi sínú oúnjẹ.

Irú máa ń mú ọbẹ̀ dùn yàtọ̀ sí àwọn adùn ọbẹ̀ ìgbàlódé tó gba ìgbooro báyìí.

Lóòótọ́ ni ojú irú kìí fani mọ́ra bí àwọn adùn ọbẹ̀ ìgbàlódé òní, tí ọ̀pọ̀ kìí fẹ́ lò ó nítorí òórùn rẹ̀ ṣùgbọ́n òórùn rẹ̀ wà lára ohun tó ń mú ara wà ní àlááfíà.

Irú kìí ṣe oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá nìkan, ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀yà káàkiri Nàìjíríà ló ń lò ó, tí oníkálùkù sì ní orúkọ tí wọ́n fún-un.

Irú ló ń jẹ́ nílẹ̀ Yorùbá, Ògìrì ni àwọn ẹ̀yà Igbo ń pè é, nígbà tí àwọn Hausa ń pè é ní dawadawa.

Láti ara èso ìgbá ni wọ́n ti máa ń yọ ìyère tí wọ́n fi ń ṣe irú.

Àwọn àǹfààní ìlera tó wà lára irú

Àwọn àǹfàní ìlera wo ni irú ń ṣe fún ara?

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa oúnjẹ, Vivian Onyenora Ujunwa ṣe sọ, irú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èròjà tó ń ṣe àǹfààní fún ìlera ọmọnìyàn.

Lára àwọn àǹfààní irú fún ara gẹ́gẹ́ bí Onyenora ṣe kà á sílẹ̀ ni:

  • Ó máa ń mú ìgbèrú bá ìlera ọkàn.
  • Ó máa ń jẹ́ kí oúnjẹ dà bó ṣe yẹ.
  • Ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ èèyàn lọ sí ibi tó yẹ lára.
  • Ó máa ń mú ìgbèrú bá ẹ̀yà ara tí kìí jẹ́ kí èèyàn ṣe àárẹ̀.
  • Ó máa ń jẹ́ kí egungun àti eyín èèyàn le si.
  • Ó dára fún ojú nítorí ó máa ń jẹ́ kí èèyàn ríràn dada.
  • Ó dára fún ẹni tó bá fẹ́ dín ara sísan kù.
  • Ó ní èròjà Carbohydrates, Fiber, Protein, Healthy Fats, Calcium, Iron, Vitamins A àtiC, Potassium, Zinc àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Pẹ̀lú gbogbo àwọn àǹfàní irú yìí, onímọ̀ nípa oúnjẹ náà sọ pé irú ní àwọn àléébú tó máa ń fa sí ara bí èèyàn bá jẹ ẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ àti pé àwọn àsìkò kan wà tí èèyàn kò le jẹ irú.

Ujunwa sọ pé àwọn tó máa ń ta irú máa ń jẹ́ kí ó kan kí wọ́n tó tà á, tí ẹni tí nǹkan kíkan kò bá sì bá lára mu le ní ìṣòro láti ara rẹ̀.

Bákan náà ló sọ pé òórùn rẹ̀ tún jẹ́ ìdí tí àwọn míì kìí fẹ́ ṣe àmúlò rẹ̀ rárá.

Ó fi kun pé àwọn tó máa ń ta irú lọ́pọ̀ ìgbà máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ́ sí i nítorí kí ó fi má tètè bàjẹ́ èyí tó ní ó le mú kí ìfúnpá èèyàn ga.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní tí wọn kò bá ṣe é lọ́jọ̀ bó ṣe yẹ, kòkòrò àìfojúrí lè wọnú rẹ̀, tó sì le fa àìlera.

Láti dènà àwọn ìṣòro yìí, Ujunwa ṣèkìlọ̀ pé kí àwọn èèyàn dènà fífi sí oúnjẹ ní gbogbo ìgbà, kí wọ́n sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀ dáadáa.

Lára àwọn oúnjẹ tó kà pé irú dára láti máa fi sè ni ewédú, ẹ̀gúsí, ilá, ọ̀fadà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.