You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ wo ànfààní márùn ún tí Atailẹ̀ ń ṣe fún àgọ́ ara
Atailẹ ti ọpọ eeyan mọ si ginger jẹ eso kan to da bii alubọsa, to si ri bii bọọlu rugudu amọ oorun rẹ lagbara, ti ọpọ eeyan to ba sun mọ ẹni to jẹ ẹ si maa n gbọ oorun rẹ.
O si dabi pe gbogbo ile idana kaakiri agbaye ni Atailẹ maa n wa.
Amọ kii se pe eso yii wa gẹgẹ bii eroja amuounjẹdun sugbọn awọn eeyan jakejado agbaye maa n lo o gẹgẹ bii oogun lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ki wa ni iwulo eso Atailẹ yii, awọn eeyan wo lo le jẹ, anfaani wo lo n se fun ara, ki si ni awọn aleebu rẹ.
Ninu iroyin yii, BBC News Pidgin ba onimọ nipa ounjẹ sọrọ, Sa'aadu Sulaiman, lati ilu Kano, ẹni to tan imọlẹ sawọn ibeere yii.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Sulaiman ni "Ọpọ anfaani to wa lara Atailẹ to n se anfaani fun agọ ara lo wa lati inu eroja pataki kan to wa ninu eso ọhun.
Eroja naa lo fara jọ eroja sulphur gẹgẹ bii eroja allicin, ohun si lo maa n sisẹ daadaa fun agọ ara lasiko ti eeyan ba lọ Atailẹ tabi jẹ ẹ lẹnu ni tutu.
Awọn Anfaani to wa ninu jijẹ Atailẹ
Lara awọn anfaani to wa ninu jijẹ Atailẹ, gẹgẹ bi akọsẹmọsẹ nipa eroja ounjẹ, Sulaiman ti mẹnuba ree:
- O maa n mu agbega ba awọn eroja to n daabo bo agọ ara: Atailẹ lagbara pupọ tori eroja to wa ninu rẹ, to maa n ba awọn aisan ara wọ ijakadi.
- Fun apẹẹrẹ, Atailẹ ni eroja to n ba awọn Kokoro aifojuri ja, o maa n gbogun ti awọn aisan to wọpọ ati Kokoro kekeke to maa n fa ikọ, ọfinkin atawọn aidape ara miran
- Atailẹ tun maa n daabo bo ọkan ẹda: Eso Atailẹ yii maa n se iranwọ lati mu ki ọkan ẹda sisẹ bo se yẹ nipa mimu ki ifunpa tabi ẹjẹ riru wa silẹ.
- Bakan naa, o tun maa n mu adinku ba odiwọn awọn ọ̀rá to wa ninu ara, ti yoo si jẹ ki ọpa to n gbe ẹjẹ kaakiri inu ara sisẹ bo se yẹ.
- Atailẹ jẹ ọlọpaa ninu ara to maa n daabo bo ara: Jijẹ eso Atailẹ jẹ ọna lati daabo bo awọn sẹẹli ara rẹ lọwọ idibajẹ. Iru idibajẹ yii le fa aisan to le da eeyan gunlẹ tabi to le jẹ ki oju eeyan tete gbo ju ọjọ ori rẹ lọ.
- Atailẹ dara fun Egungun: Awọn iṣẹ iwadii kan ti fi han pe atailẹ maa n ṣe iranwọ fun egungun ninu ara papaa julọ fawọn obinrin.
- Atailẹ n dena aarun jẹjẹrẹ: Iwadii ti fidi rẹ mulẹ pe atailẹ maa n gbogun ti oriṣiiriṣii arun jẹjẹrẹ bi jẹjẹrẹ ikun, jẹjẹrẹ, ọyan, jẹjẹrẹ fuku ati jẹjẹrẹ woropọ. Jijẹ atailẹ ti wọn ti lọ le gbogun ti arun jẹjẹrẹ ni kiakia laarin wakati diẹ. Awọn to ba n jẹ atailẹ daadaa kii saba ni arun jẹjẹrẹ.
Njẹ gbogbo eeyan ni atailẹ jijẹ dara fun?
Agbẹnusọ ẹgbẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ounjẹ jijẹ, Bahee Van de Bor, nilẹ Gẹẹsi, sọ pe atailẹ le dakun ailera tawọn eeyan kan ni ninu ikun wọn.
Van de Bor ni ''atailẹ jijẹ le dakun ailera awọn eeyan to ba ni arun IBS.
Nitori naa, o ṣe pataki fun gbogbo eeyan to fi mawọn ọmọde to ba larun IBS lati ṣọra ṣe pẹlu jije atailẹ.''
Ọgbẹni Van de Bor sọ pe ọna mii ti eeyan tun le gba fi gbadun atailẹ ni nipa lilo ororo ara rẹ fun idana.
''O ṣe pataki lati mọ pe fifi ororo atailẹ dana fawọn to ba larun IBS lara, amọ, iru ororo yii kii ni eroja allicin ti anfaani ti atailẹ n ṣe fun agọ ara wa ninu rẹ.'' Van de Bor lo sọ bẹẹ.
Eroja aṣaraloore inu atailẹ
- Atailẹ tutu to gbe iwọn100g ni awọn eroja wọnyi:
- Agbara: 149 Kcal
- Okun: 33.06g
- Okun faiba: 2.1g
- Eroja amuaradagba: 6.36g
- Ọra: 0.50g
- Eroja agbara: 1.70mg
- Eroja foleeti: 3µg
- Iṣu mọlẹ: 0mg
- Ọra to pọ: 0.083g
- Ọra ti ko pọju: 0.006g
- Ọra to pọ soju kan: 0.251g