You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣọ́jà la ìbọn mọ́ awakọ̀ kan lórí l'Ondo tó fi kú, iléeṣẹ́ ológun ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé
Lẹyin iku awakọ ero, Yakubu Joshua, ti a gbọ pe ṣọja kan lo la ibọn mọ ọn lori nipinlẹ Ondo, ileeṣẹ ologun ti ṣeleri lati fiya jẹ ṣọja naa.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ ṣọja ọhun, atẹjade ti Igbakeji adari ikede nileeṣẹ ologun, ẹka 32 Artillery Brigade, Major Njoka Irabor, fi sita l'Ọjọbọ oni, leri lati ri i pe ṣọja naa ko lọ lai jiya.
Ọmọ ẹgbẹ awakọ NURTW ni Oloogbe Joshua bi a ṣe gbọ, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii lo ko si wahala to gba ẹmi rẹ niluu Akunu Akoko, ipinlẹ Ondo.
Kí ló fa ikú awakọ̀?
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun ṣe ṣalaye, Joshua ko ero lọjọ kẹtala oṣu Kẹwaa yii lati ilu Akure nipinlẹ Ondo, wọn n lọ si ilu Abuja.
Nigba ti wọn de ibi kan ti ko jinna si ibudo ayẹwo awọn ologun niluu Akunu, ijọba ibilẹ Ariwa/ Ila-Oorun Akoko, ipinlẹ Ondo, ọkọ naa yọnu, ko si le tẹsiwaju irinajo si Abuja mọ.
Eyi lo mu ki awọn ero ọkọ maa beere owo wọn pada lọwọ dẹrẹba yii, to si pada di ariyanjiyan laaarin wọn.
Ero ọkan kan ni wọn lo ranṣẹ pe ṣọja lati wa ran awọn lọwọ ninu wahala naa.
"Ṣọja yii yọju si wọn, ṣugbọn o huwa lọna to tako iṣẹ to yan laaayo, eyi to di ariwo laaarin oun ati dẹrẹba, to si pada di pe wọn wọya ija.
"Ẹsẹkẹsẹ ti olu ileeṣẹ ologun 32 Artillery Brigade gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni wọn sare gbe awakọ naa lọ si ileewosan, sanwo itọju rẹ, a si tun yan ologun kan lati duro ti i"
Bẹẹ ni atẹjade awọn ṣọja naa ṣalaye.
Wọn fi kun un pe nigba ti ileewosan to wa l'Akoko sọ pe kawọn maa gbe e lọ si ileewosan miran ni Akure, awọn gbe e lọ sibẹ.
Lẹyin eyi ni wọn tun ni kawọn gbe e lọ sile iwosan ijọba, FMC ilu Owo, awọn si tun gbe e lọ pẹlu.
Ile iwosan FMC naa ni wọn lo pada dakẹ si lọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa ti i ṣe ọjọ keji iṣẹlẹ naa.
Ileeṣẹ ologun ni oun ti kan si ẹbi Oloogbe nipa bi ẹbi naa ko ṣe ni i jiya lẹyin iku olori ẹbi wọn.
Ṣugbọn ile iṣẹ ologun fi kun un pe awọn ti kan si ẹbi Oloogbe Joshua Yakubu, nipa bi ẹbi rẹ ko ṣe ni i jiya lẹyin iku olori ẹbi wọn.
Wọn ni yatọ si pe ṣọja to daran naa yoo jiya, awọn ti ṣabẹwo si idile Oloogbe.
Ati pe ileeṣẹ ologun yoo ri i pe awon ọmọ ati iyawo rẹ ko rare lẹyin iku rẹ.
Bakan naa ni wọn ni isinku rẹ ko ni i ṣẹyin awọn.
"Ìbọn AK47 ni ṣọ́jà là mọ́ Olóògbé lórí''
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe wi, ibọn AK47 ti ṣọja naa n lo ni wọn lo la mọ Oloogbe Joshua Yakubu lori.
Ṣaaju ko to la ibọn naa mọ ọn lori ni a gbọ pe ṣọja yii ti lu u bii ejo aijẹ.
Ìya ti awakọ naa jẹ lo pọ to bẹẹ to fi balẹ sile iwosan bi a ṣe gbọ, to si pada ja si iku ojiji to mu ẹmi rẹ lọ.
Iyawo kan ati ọmọ mẹrin ni Oloogbe Joshua Yakubu, ọmọ ipinlẹ Kogi, fi saye lọ.