Àìsàn ẹ̀jẹ̀ rúru ló kọ́ ṣe 'I Sho Pepper'', ó ń pọ̀ ẹ̀jẹ̀ lórí ahọ́n, dákú fọ́jọ́ mẹ́sàn -án, kí ọlọ́jọ́ tó dé - Yetunde Ogunsola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Agbaọjẹ oṣere ori itage, Yetunde Ogunsola, to jẹ ọkan lara iyawo ogbontarigi onitiata n ni to ti di oloogbe, Oloye Ishola Olusola Ogunsola, ti ọpọ eeyan mọ si ''I Sho Pepper'' ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ lori bi gbajugbaja oṣere naa ti ku atawọn nnkan mii nipa igbeyawo rẹ pẹlu oloogbe naa.

Ọdun 1972 ni Yetunde Ogunsola, to jẹ ọmọbibi ilu Ilesha bẹrẹ ere tita lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ oṣere oloogbe ''I Sho Pepper.''

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to sẹ pẹlu Kunle Afod, Yetunde fidi rẹ mulẹ pe nibi toun ti n tẹle ''I Sho Pepper'' kiri naa loun ti di iyawo rẹ.

"Dokita ni aisan ẹjẹ riru lo n se I Sho Pepper, pe ko sinmi, amọ o tun gba Eko lọ lati kọrin, ibẹ ni wọn ti pe wa pe o n pọ ẹjẹ lori ahọn"

Yetunde to fi orilẹede Canada ṣe ibugbe bayii ni baba oun ko binu si bi oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣere ''I Sho Pepper'' toun si tun di ọkan ninu awọn iyawo rẹ.

Nigba to n sọrọ nipa iku oloogbe naa, Yetunde ṣalaye pe nigba ti ''I Sho Pepper'' ṣe aarẹ ni o lọ fun ayẹwo ara rẹ.

''Lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo fun Ogunsola tan ni wọn ri pe o ti ni aisan ẹjẹ ruru wi pe o si lọ soke gan an.

Dokita to ṣe ayẹwo fun Ogunsola, to tun jẹ ọrẹ rẹ, sọ fun un pe ki o maa lọ ile lati lọ sinmi tori ẹjẹ ruru to ni,'' Yetunde lo sọ bẹẹ.

Amọ, ''I Sho Pepper'' kọ eti ikun si ọrọ dokita to jẹ ọrẹ rẹ, ko lọ ile lọ sinmi.

Yetunde ni Ogunsola tun gba ibi to ti n ṣere lọ ni, nigba naa lo rinrin ajo lọ si ilu Eko nibi to ti lọ kọ orin.

O ni bayii ni aisan to n ṣe e tun lagbara sii.

Ṣadeedee ni awọn iyawo Ogunsola gba ipe niluu Ibadan wi pe ọkọ wọn ti n pọ ẹjẹ lẹnu, wọn ni lati ibi ahọn rẹ lẹjẹ ti n tu jade.

Awọn dokita bẹrẹ si ni gbiyanju agbara wọn lati du ẹmi Ogunsola pẹlu bi aisan to n sẹ e ti ṣe n lagbara si.

Yetunde ni bayii ni ''I Sho Pepper'' ko le sọrọ mọ, to si wọ ‘Coma’ fun ọjọ mẹsan an gbako.

Lẹyin ọpọ akitiyan awọn dokita ni Ogunsola yaju, ti o si rinrin ajo lọ si ilu Ibadan ibugbe rẹ.

Amọ, ko si ẹni to ri ti ọlọjọ ṣe, ''I Sho Pepper'' jade laye lọdun 1992 lẹyin ọdun kan to ṣaisan.

"Emi ni iyawo keje ''I Sho Pepper'' , o si tun fẹ iyawo meji miran le mi, ọkọ gidi ni"

Yetunde Ogunsola tun ṣalaye wi pe oun ni iyawo keje ninu awọn iyawo ti ''I Sho Pepper'' fẹ nigba aye rẹ.

Agbaọjẹ oṣere naa ni Ogunsola tun fẹ iyawo meji le oun lẹyin ti awọn jẹ ṣe igbeyawo tan.

Ilumọọka oṣere naa tawọn eyan mọ si Ayoni ninu ere ṣalaye pe ọpọ awọn iyawo Ogunsola ni ko duro ti i ti wọn kan bi ọmọ lasan fun un.

O ni oun ni Ogunsola fẹran julọ ninu gbogbo awọn iyawo rẹ tori awọn mejeeji lo jẹ oṣere.

Yetunde ni oriṣiiriṣii iṣẹ loun maa n ba ''I Sho Pepper'' nigba naa.

Agba oṣere Yetunde ni oun maa n sọ fawọn to ba ni oun ni Ogunsola fẹran julọ wi pe iṣẹ rẹ lo fẹran.

O ni oun ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu gbogbo awọn iyaale oun.

''Ko si ija laarin mi atawọn iyaale mi tori wọn maa n ri emi ati ọkọ wa gẹgẹ bi olupese fun ẹbi wa.

Ko si ẹni to jowu ninu wọn tori awọn naa n ri owo na lati ibi iṣẹ ti a n ṣe eyi ti wọn fi n ṣe nnkan to ba wu wọn.

''I Sho Pepper'' gan an funra rẹ jẹ ọkọ gidi, ko ni gba ki iyawo ri iyaale fin, bakan naa ni ko si ni gba ki iyaale rẹ iyawo jẹ,'' Yetunde ṣalaye.

''Iku baba mi ni iṣẹlẹ manigbagbe to ṣẹlẹ si mi lẹnu iṣẹ, oun nikan lo da tọju mi lati ọmọ ọdun mẹta''

Yetunde Ogunsola ni iku baba oun wa jẹ nnkan to dun oun gan an tori baba ooun nikan lo tọju oun lati ọmọ ọdun mẹta.

O ni ija to wa laarin iya ati baba oun lo jẹ ki baba oun nikan tọju oun dagba.

''Ohun to dun mi julọ nipa iku baba mi ni pe n ko si nibẹ nigba ti baba mi ku.

O wu mi ki n wa nibẹ nigba ti baba mi ku, amọ, Ọlọrun ko jẹ ko ri bẹ,'' Yetunde lo sọ bẹẹ.

Nigba to n sọrọ nipa nnkan to jẹ idunnu fun un julọ, Yetunde ni orin ti oun kọ pẹlu ẹgbẹ oṣere Ishola Ogunsola nibi iku oloogbe Duro Ladipo.

O ni lẹyin naa ni oun gbọ ohun ara oun ninu redio lẹyin ti awọn se rẹkọọdu orin naa tan.

Agba oṣere naa sọ pe orin yii wa lara awọn nnkan to gbe oun jade lagbo oṣere.

Oni nnkan keji to jẹ ki inu oun dun ni ọjọ ti oun gba fisa Amẹrika.

Yetunde ni oun wa lara awọn oṣere mẹjọ ti wọn fun ni fisa Amẹrika lọdun naa.