Wo àwọn àìsàn tó le ṣúyọ ní àgọ́ ara lásìkò ààwẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àsìkò ààwẹ̀ jẹ́ ìgbà tí àwọn ènìyàn máa ń lò láti súnmọ́ Ẹlẹ́dàá wọn.

Yàtọ̀ sí àwẹ̀ Ramadan tó gbajúmọ̀ fún àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti lẹ́ńtì tó gbajúmọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń gba àwẹ̀ àdágbà fún ìdí kan tàbí òmíràn.

Lásìkò àwẹ̀, àwọn ènìyàn máa ń séra fún oúnjẹ jíjẹ, omi mímu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé àwẹ̀ gbígbà ní àwọn àǹfàní tó máa ń ṣe fún àgọ́ ara, ọkàn àti ẹ̀mí.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn dókítà ní bí àwẹ̀ ṣe ní àwọn àǹfàní tó ń ṣe fún àgọ́ ara náà ló ní ìdàkejì rẹ̀.

Àwọn dókítà ní ó ṣeéṣe kí àwọn àìsàn kan jáde sí àgọ́ ara tàbí kí àwọn kan tó bá ti wà lára tẹ́lẹ̀ lékún nítorí àìjẹun.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wí pé ènìyàn sì tún le rí ìwòsàn sí àwọn àìsàn kan látara àwẹ̀ gbígbà.

Àwọn àìsàn tí ààwẹ̀ le fà sí àgọ́ ara nìyí:

Dókítà Mu'awiya ti ilé iṣẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ Katsina, ìyẹn Katsina State Health Authority ka àwọn àìsàn wọ̀nyí kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn nǹkan tí àwẹ̀ le fà sí ènìyàn lára

Ọgbẹ́ inú: Ọgbẹ́ inú jẹ́ àìsàn tó máa ń mú kí ènìyàn máa ní ìnira nínú ikùn tí yóò sì dàbí ẹni pé wọ́n ń fi abẹ́rẹ́ gún ènìyàn nínú.

Àìsàn yìí máa ń pọ̀ si tàbí kó mú ènìyàn tí ènìyàn kò bá jẹun lásìkò pàápàá oúnjẹ àárọ̀ tí àwẹ̀ gbígbà sì tún le ṣàkóbá fún ẹni tó bá ní irú àìsàn bẹ́ẹ̀.

Àìsàn kíndìnrín: Dókítà Mu'awiya ṣàlàyé pé àwọn àwọn àìsàn kàn wá tó jẹ́ wí pé àìmu omi déédé ló máa ń fà wọ́n èyí tí àìsàn kíndìnrín jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.

Ó ní àwọn máa ń gba àwọn tó bá ní àìsàn yìí lámọ̀ràn láti máa mu omi ní òrèkóòrè tí ẹni tó bá ń gbàwẹ̀ kò sì ní le se bẹ́ẹ̀.

Àìsàn ilé ìtọ̀: Àìsàn yìí náà gba kí ènìyàn máa mú omi ní gbogbo ìgbà láti mú àdínkù bá ìnira tí àwọn tó bá ní àìsàn yìí ń kojú kù.

Dókítà ní ọ̀pọ̀ àwọn àìsàn yìí ni àwọn ènìyàn máa ń ní tí wọ́n bá ń àwẹ̀ tó sì ṣèkìlọ̀ fún ẹni tó bá ń rí àwọn àpẹẹrẹ àìsàn wọ̀nyí láti jìnà sí àwẹ̀ gbígbà.

Àwọn àìsàn tí ènìyàn le rí ìwòsàn lásìkò àwẹ̀

Dókítà Mu'awiya tún tẹ̀síwájú pé àwọn àìsàn kan wà tó jẹ́ wí pé tí ènìyàn bá ń gba àwẹ̀ ó ṣeéṣe kí ènìyàn tètè rí ìwòsàn fún-un.

Àìsàn okan: Dókítà ní àpọ̀jù ọ̀rá látara oúnjẹ jíjẹ ló máa ń fa àìsàn ọkàn tó sì jẹ́ wí pé tí ènìyàn bá ń gbàwẹ̀, àdínkù le ba púpọ̀.

Àìsàn jẹjẹrẹ: Nǹkan tó máa ń fa jẹjẹrẹ ni tí ẹ̀yà ara kan bá ń dàgbà ju bó ṣe yẹ lọ tí dókítà sì ṣàlàyé pé tí ènìyàn bá ń gbàwẹ̀, àìsàn náà kò ní ríbi dàgbà.

Àìsàn onígbá meji: jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ti bàjẹ́ ló sábà máa ń fa àìsàn yìí tó sì jẹ́ wí pé tí ènìyàn bá wà nínú àwẹ̀ kò ní lè jẹun débi tí yóò jẹ èyí tó ti bàjẹ́.

Àìsàn ẹ̀dọ̀: Dókítà Mu'awiya tẹ̀síwájú pé ẹ̀dọ̀ ló máa ń yọ àwọn nǹkan tí kò dára nínú oúnjẹ tí à ń jẹ kúrò ní ara.

Ó ní lásìkò àwẹ̀, ẹ̀dọ̀ kò ní ní iṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe nítorí ènìyàn kò máa jẹun púpọ̀.

Ara sísan: Dókítà ní sísanra ní àsanjù jẹ́ àìsàn fúnra rẹ̀ àti pé àwọn ọ̀rá tó bá pọ̀jù ní àgọ́ ara ló máa ń ṣokùnfà wọn.

Dókítà Mu'awiya ní àwẹ̀ gbígbà máa ń mú àdínkù bá bí ènìyàn ṣe ń sanra nítorí oúnjẹ jíjẹ ní àsìkò.

Àwọn oúnjẹ tó dára láti máa jẹ lásìkò àwẹ̀

Dókítà fi kun pé ó ní àwọn oúnjẹ tó yẹ kí ènìyàn máa jẹ lásìkò tó bá ń gbàwẹ̀ àti àwọn oúnjẹ tó yẹ kí ènìyàn sá fún nítorí ìlera ara.

Ó ní àwọn oúnjẹ tó bá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ "protein" dára púpọ̀ láti máa jẹ nítorí wọ́n máa ń pẹ́ kí wọ́n tó dà nínú.

Bákan náà ló ní kí ẹni tó bá ń gbàwẹ̀ jìnà sí omi tó bá tútù jù lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ ṣínu.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ọsàn wẹ́wẹ́ pàápàá èyí tó bá tútù kò dára tó fún ẹni tó bá ń gbàwẹ̀ láti fi ṣínu.