You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sáà ọlọ́dún mẹ́fà kan ti tó fáwọn olóṣèlú dípò sáà ọlọ́dún mẹ́rin méjì – Makinde
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti sọ pe saa kan to jẹ ọdun mẹfa lo yẹ ki awọn oloṣelu ti wọn dibo yan maa lo lori alefa dipo saa meji ọlọdun mẹrin-mẹrin.
Makinde ni ọdun mẹfa ti to fun adari to ba mọ ohun to n ṣe lati mu irọrun ba awọn to n ṣejọba le lori.
Gomina ọhun ti wa ke si awọn aṣofin ki wọn gbe igbesẹ lori aba naa.
O ni "Mo ti lo ọdun mẹfa lori oye bo tilẹ jẹ pe a padanu ọdun 2020 ti kii ṣe ẹbi ẹnikẹni.
"A tun padanu nnkan bii ọdun kan mii ti a fi n ṣe ipolongo ibo fun saa keji, ni bayii, awọn eeyan tun ti n ba wa sọrọ lori ohun to yẹ ki a ṣe lẹyin eyii.
"Nitori naa mo lẹ sọ pe iye akoko ti a fi ṣiṣẹ gan ninu ọdun mẹjọ naa ko ju ọdun marun un lọ.
"Idi ree ti mo fi ro pe o yẹ ka yọ awọn idiwọ wọnyii kuro, saa kan ṣoṣo to jẹ ọdun marun tabi ọdun mẹfa ti to ọmọluabi lati ṣe awọn iṣẹ ti a fẹ ṣe."
Makinde lo sọ ọrọ naa lasiko ti awọn Musulumi ṣabẹwo si nile ijọba to wa ni Agodi, niluu Ibadan lẹyin adura ọdun Ileya.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọrọ ofin ni aba ọhun, o jẹ ohun to yẹ ko ṣiṣẹ fun orilẹede Naijiria ti wọn ba le gba aba naa wọle.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ootọ ọrọ ni oun sọ nipa saa ti awọn oloṣelu n lo lori oye ko si yẹ ki ẹru maa ba eeyan lati sọ otitọ nitori ohun to fẹ jẹ tabi ipo to fẹ dimu.
Gomina Oyo ọhun sọ pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ti irufẹ ọrọ bẹẹ yoo jade ree, ohun to yẹ ki awọn aṣofin Naijiria gbe yẹwo ni.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni igbakeji Makinde, Abdulraheem Lawal, Otun Olubadan ilẹ Ibadan, Rashidi Ladoja; igbakeji gomina tẹlẹ, Taofeek Arapaja; to fi mọ awọn igbakeji gomina meji mii nigba kan ri, Hazeem Gbolarumi ati Hamid Gbadamosi.