You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Taa ni Balogun Kuku, bàbá olówó tó mú ẹ̀sìn Islam wọ ilẹ̀ Ijebu, tó tún bẹ̀rẹ̀ ọdún Ojude Ọba?
Odu ni Balogun Kuku nilẹ Ijẹbu, ti ọpọ eeyan si mọ ile awodamiẹnu to kọ silu Ijẹbu Ode, eyi ti ọpọ awọn elere tiata ma n lo fun ere wọn lasiko yii.
Eyi lo gbe BBC Yoruba de ilu Ijebu Ode lati foju gan ni ile Balogun Kuku, ka si mọ nipa itan igbesi aye rẹ.
BBC Yoruba ba Asiwaju fun idile Balogun Bello Kuku nilu Ijebu Ode, to tun jẹ Ọgbeni Ọja tilẹ Ijebu, Olorogun Ọmọwe Sunny Folorunso Kuku, sọrọ nipa itan aye akọni jagunjagun yii.
Olorogun Kuku, ti i se iran kẹfa si akọni jagunjagun naa ni, apetan orukọ baba nla idile awọn naa ni Bello Odueyungbo ( Ifa ko lọ sinu igbo) Bórogún.
Fún ojúlówó ìròyìn nípa àṣà Yorùbá, darapọ̀ mọ́ BBC Yoruba lórí Whatsapp Channel
Oriki lasan ni Kuku jẹ fun baba naa eyi to pada di orukọ rẹ ti gbogbo idile rẹ n jẹ.
Wọn fun un ni orukọ naa nitori bi iya rẹ ṣe bi, lo ku.
Orukọ naa wa lati ara gbolohun "iya Kú, ọmọ Kù". Apapọ rẹ lo di Kuku.
"Mama to bi baba nla wa yii ku laarin ọjọ mẹta to bi, mama mama rẹ lo tọ ọ dagba, to si kọ Kuku ni ọna okoowo.
Kuku n se okoowo karakata, to si n ta nnkan ijagun nilẹ Yoruba. Eyi lo sọ ọ di olowo tabua, milọnia, ko to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun.
Bi ogun ba wa nilẹ Yoruba, ẹni ti Kuku ba se atilẹyin fun pẹlu nnkan ijagun, ni yoo bori ogun naa, to si ni orisirisi ọta ibọn to maa n ta fun ẹni kọọkan.
Ogbeni Ọja salaye siwaju si pe idi katakara eroja ijagun yii ni Balogun Kuku ti di jagunjagun nitori o ni ibọn ati ọmọ ogun pupọ ti yoo daabo bo awọn to ba kọwọrin pẹlu rẹ.
"Bi ogun ba de, Balogun Kuku lo ma siwaju ogun fun ilẹ Ijẹbu, o lowo lọwọ, onisowo ni, to si maa n doju kọ awọn adigunjale.
Oun si ni Awujalẹ maa n lọ lati jagun bii ogun Kiriji, ohun si ni Olori awọn Parakoyi onisowo to di ẹgbẹ awọn onisowo Chambers of Commerce loni yii."
"Balogun Kuku gba lati di Krisitẹni amọ pasan lawọn aya rẹ fi na Pasitọ jade tori o ni iyawo kan ni Kuku gbọdọ mu laarin iyawo marundinlaadọrin to fẹ"
Nigba ti Oloye Sunny Kuku n salaye ipa ti Balogun Kuku ko ninu awọn ẹsin igbalode ti igbagbọ ati Musulumi nilẹ Ijebu, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ.
Lara ohun to pa ni lẹrin ni itan bi Balogun Kuku se gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ ti akude wọ igbesẹ rẹ naa.
Gẹgẹ bi Sunny Kuku ti wi, awọn Krisitẹni lo wọ ilu Ijẹbu Ode wa, ti wọn si wa waasu fun Balogun Kuku lati di ọmọlẹyin Kristi tori o ni ero pupọ.
"Balogun Kuku lo ni ilu, o si fẹran ẹsin Krisitẹni naa , to si gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ Pasitọ sọ fun pe yoo mu ọkan soso ninu iyawo marundinlaadọrin to ni.
Kuku wa sọ fun Pasitọ pe ko wa lọjọ kan lati wa se iribọmi fun oun, ti yoo si tun ba oun mu iyawo kansoso ninu awọn iyawo oun, ti yoo sẹku sinu ile.
Kuku pe awọn iyawo rẹ, to si salaye isẹlẹ yii fun wọn, awọn iyawo duro de Pasitọ, bo si se de, wọn ko pankẹrẹ bo Pasitọ, ti wọn si lu jade kuro ninu ile wọn."
Ogbeni Oja ni idi ree ti Balogun Kuku ko se di ọmọlẹyin Kristi mọ, se o kuku mọọmọ da ete fun Pasitọ ni, to fẹ ba le gbogbo iyawo rẹ danu."
"Balogun Kuku gba ẹsin Islam, ida aadọrun eeyan Ijebu Ode si tẹle lati di Musulumi, o si bẹrẹ ọdun Ojude Ọba"
Oloye Sunny Kuku tẹsiwaju pe lẹyin ti Kuku ko di Krisitẹni mọ, wọn wa fi ẹsin Islam lọ ọ, to si tẹwọgba nitori ẹsin naa fun ni anfaani lati ni ọpọlọpọ iyawo.
"Bi Kuku se di Musulumi ni ida aadọrun eeyan ilu Ijebu Ode naa yipada di Musulumi, to si we lawani fun gbogbo wọn.
Awọn ẹlẹsin ibilẹ maa n lọ ki ọba Awujalẹ lasiko ọdun wọn ni ọdọọdun amọ bi Kuku ati awọn eeyan Ijebu Ode ṣe di Musulumi, ni wọn yi ikini naa pada si abẹwo si ọdọ ọba ni ọjọ kẹta ọdun Ileya.
Abẹwo asiko ọdun Ileya yii ni wọn pe ni Ojude Oba, ti Balogun Kuku yoo si lewaju awọn araalu lati lọ ki Awujalẹ.
Ẹsin Islam di itẹwọgba nilẹ Ijẹbu nitori Balogun Kuku, o lowo, o lọla, to si ni ero rẹpẹtẹ lẹyin."
Awujalẹ fi Balogun Kuku jẹ oye Olorogun, to tumọ si Olori ogun, eyi ti idile Kuku n jẹ titi di oni oloni.