You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èyí ni bí àwọn Larubawa ṣe kọlu Mecca, tí wọ́n sì jí Òkúta Dúdú lọ
Rírọ-kiri-ká Kaaba jẹ opo pataki kan lara iṣẹ Haji. Eyi tumọ si yiyi Kaaba po.
Lasiko yiyi Kaaba po, ẹgbẹẹgbẹrun eeyan to n ṣiṣẹ Haji yoo maa gbiyanju lati fi ẹnu ko Okuta Dudu ( Al-Ḥajar al-Aswad) to wa nibẹ, gẹgẹ bi ìṣe Anabi Muhammad.
Bayii ni iṣesi yii ṣe wa lati ẹgbẹrun kan ati irinwo ọdun sẹyin.
Ṣugbọn ṣaa, itan Islam sọ fun wa pe asiko kan wa ti ilu Mecca di akọti, o si le logun ọdun to fi ri bẹẹ.
Itan sọ pe ikọlu alagbara kan lo kọlu ilu naa ni nnkan bii ẹgbẹrun kan ọdun o le lọgọrun-un sẹyin (1,100) to si fa eyi.
Asiko naa ni wọn ni ogun ẹsin ati ti oṣelu n waye ni Mecca.
Itan sọ pe ni 317 AH tabi 930 CE, awọn eeyan kan ti a mọ si Qaramid, kọlu ilu Mecca.
Wọn pa awọn to n ṣiṣẹ Haji, wọn gbe Okuta iyebiye naa kuro nibẹ lọ si ilu kan ti wọn n pe ni Al-Ahsa.
Ilu naa wa ni apa Ila-Oorun Saudi Arabia, ti wọn fi ṣe olu ilu wọn.
Àwọn wo ni Qaramid?
Bi awọn akọsilẹ itan ninu ẹsin Islam ṣe sọ, awọn ti a mọ si Qaramid tabi Qaramidawa, jẹ ẹya ẹlẹsin Islam kan to dide lọdun kẹta lẹyin Hijra.
Ko pẹ ti wọn fi tuka ti wọn si da ijọ kan silẹ lọtọ, Ismaili ni wọn pe e, pẹlu iṣesi to yatọ.
Ijọ Ismaili yii ni itan sọ pe wọn dide lati ara awọn ijọ Shia. Eyi ti wọn lo bẹrẹ lati ara aigbọra-ẹni-ye nibẹrẹ ẹsin Islam.
Igbagbọ awọn Shia yii ni pe Imam Ali ibn Abi Talib, ibatan Anabi to tun jẹ ọkọ Fatima; ọmọ Anabi, ni Arole Anabi gidi to yẹ lati tẹle.
Wọn yapa kuro loju ọna ẹsin Islam ti akọkọ, wọn si da ijọ ọtọ silẹ labẹ ariyanjiyan lori ẹni to yẹ ko role Ojiṣẹ Ọlọun, Anabi Muhammad lẹyin iku rẹ.
Bakan naa ni awọn iwe ṣafihan, pe lẹyin iku Imam Jafar al-Sadiq, to jẹ arọmọdọmọ Imam Hussein ibn Ali ibn Abi Talib, iyapa waye ninu ijọ Shia, wọn pin si meji.
Ipinya naa si nipa lori ẹsin Islam lagbaaye.
Ẹgbẹ Qaramidawa ni igbagbọ wa pe o waye lati ara Aafaa Shia Ismaili ti orukọ rẹ n jẹ Hamdan Qarmat.
Hamdan Qarmat fi ẹkọ igbagbọ tiẹ kọ awọn to gba fun un niluu Kufa, ni Guusu Iraq. Ikọni rẹ de Yemen ati awọn ẹkun Bahrain.
Lasiko ti awọn Arab n gbilẹ yii, ayipada ọtọ lo n ba ẹsin Islam.
Ohun ti itan ko fidi rẹ mulẹ ṣaa ni pe boya iyapa yii lo fa a ti awọn Qaramid fi kọlu Mecca, ṣugbọn ohun to daju ni pe ọpọ ogun lo waye.
Bí Abu Tahir ṣe kọlu Mecca lọ́nà líle
Akọsilẹ sọ pe ẹni kan ti orukọ rẹ n jẹ Abu Tahir al-Janabi, lo ṣaaju ikọ Qaramidawa ni Bahrain, eyi si jẹ 311 AH to ṣe rẹgi pẹlu 923 CE.
Ni 317 AH, Abu Tahir ati awọn ikọ rẹ ko ogun ja ilu Mecca lasiko ti iṣẹ Haji n lọ lọwọ, ikọlu to le gan-an si waye.
Itan fi han pe lẹyin ti awọn arinrinajo de Mecca, wọn n gbọ pe Abu Tahir ti wọlu pẹlu ọgọrun-un awọn agẹṣinjagun.
Ọba Mecca nigba naa gbera pẹlu awọn agba ijoye rẹ, wọn lọọ ba Abu Tahir lati fi owo ati ọrọ̀ fa oju rẹ mọra.
Ṣugbọn awọn Qaramidawa ko gba ipẹ naa, o si pada di ogun ti awọn Qaramidawa bori.
Iroyin sọ pe awọn Qaramidawa yii wọ igboro Mecca, wọn dumbu awọn eeyan, wọn si gbe Okuta Dudu inu Kaaba.
Awọn onpitan sọ pe ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ni wọn pa lasiko naa.
Ikọlu naa mi awujọ Islam lagbaaye, bo tilẹ jẹ pe eyi ki I ṣe igba akọkọ ti wọn yoo kọlu Mecca nitori ede aiyede ati ipo aṣiwaju.
O waye lasiko Umayyad naa.
Awọn onpitan ṣalaye pe igbiyanju awọn olori iran Abbasid ati Fatimid lati jẹ ki Abu Tahir da okuta naa pada ja sofo.
Ṣugbọn awọn Musulumi n ṣiṣẹ Haji lọ lai si okuta naa ni Kaaba.
Iroyin sọ pe awọn alalaaji kan maa n fi atẹlẹwọ wọn lasan le ibi ti okuta naa wa tẹlẹ, wọn yoo si fi ẹnu ko o.
Wọn ni Abu Tahir naa n ba aye rẹ lọ, ki iku too pa a ni 334 AH.
Okuta Dudu padà sí Mecca lẹ́yin ọdún mejilelogun
Ọdun kejilelogun lẹyin ti wọn gbe okuta naa kuro ni Mecca ni awọn Musulumi to o da a pada siluu naa.
Ero awọn onpitan lori idapada okuta naa ṣọtọọtọ.
Bawọn kan ṣe sọ pe wọn da a pada lẹyin ti awọn Abbasid sanwo nla fun Qaramidawa, awọn kan sọ pe awọn iran Fatimid lo fipa gbe e wa pada.