Wo adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tuntun ìpínlẹ̀ Ogun, Oluomo àti ìgbákejì rẹ̀, Latifat

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Họnọrebu Taiwo Oluomo tí ó ń ṣojú ẹkùn Ifo1 nílé ìgbìmọ̀ aṣofin ipinlẹ Ogun ti wọlé lẹẹkeji gẹ́gẹ́ bí adari ilé igbimo aṣofin ipinlẹ Ogun.
Ọmọ ilé ìgbìmò asofin Musefiu Lamidi tí ó ń ṣojú Ado Odo Ọta 11 ni ó dabaa kí Oluomo jẹ adari ilé nígbà tí ọmọ ilé ìgbìmọ aṣofin tí ó ń ṣojú Ijubu East Oyedele Wasiu kéjìì aba náà.
Taiwo Oluomo ni ó ti ṣe adari ilé ìgbìmò aṣofin náà nínú ijoko kẹsan, òun sì ni ó tún jawe olubori lónìí lai ni alátakò kankan gẹgẹ bii adari ilé ìgbìmọ aṣofin ipinlẹ Ogun fún ijoko kẹ̀wáá.
Bákan náà, Họnọrebu Àjàyí Bolanle Latifat tí ó ń ṣojú Yewa South tí wọlé gẹ́gẹ́ bí igbakeji adari ilé ìgbìmò asofin ipilẹ ogún nínú ètò ijoko elekewa nílé ìgbìmọ̀ aṣofin ipinlẹ Ogun.
Èyí wáyé nígbà tí Hon Omolola tí ń ṣojú ẹkùn Ìjẹ̀bú Ode daba rẹ lai ni àtakò kankan.

Ohun gbogbo kọ́kọ́ dúró rigidi níbi ìfilọ́lẹ̀ ilé ìgbìmò aṣòfin ìpínlẹ Ogun
Ṣaaju nigba ti wọn bẹrẹẹ ohun gbogbo dúró rigidi níbi ìfilọ́lẹ̀ ilé ìgbìmò aṣòfin ìpínlẹ Ogun ẹlẹkẹẹ̀wá.
Nígbà tí ó kú díẹ̀ ki ifilole ijoko náà bẹ̀rẹ̀ ni akowe ilé ìgbìmò aṣofin ipinlẹ Ogun, Deji Adeyemo ni ìwádìí fihàn pé àjọ eleto abo ni ètò abo ilé ìgbìmò asofin náà kò múná doko to.
Akowe ilé ìgbìmò aṣofin ipinlẹ Ogún náà ṣàlàyé pé, gbogbo ọmọ ilé ìgbìmò asofin tí wọn fi ibo yàn àti àwọn ènìyàn jankan jankan tí wọ́n ti jókòó tẹ́lẹ̀ títí tó fi dórí àwọn Akoroyin gbọdọ jáde kúrò ní ilé ìgbìmò asofin náà ná fún àtúnṣe àti ayẹwo finifini fún eto abo tí ó péye.


Lẹ́yìn tí àwọn agbofinro, ọtẹlẹmuyẹ àti àwọn ẹṣọ eleto àbò tí ṣàyẹ̀wò fínnífínní fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmò asofin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dibò yàn wọlé tán, ó lè ní wákàtí kan tí gbogbo nnkan fi dúró lai si eto.
Akoroyin BBC News Yoruba ti o wa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun jẹ ki o di mimo pé ìpàdé alágbára kan ń lọ lọ́wọ́ láàrín àwọn ọmọ ilé ìgbìmò asofin náà pẹ̀lú gomina ipinlẹ, Ọmọba Dapo Abiodun.
Ìrètí wá pé ìpàdé náà ni ṣe pẹ̀lú ẹni tí yóò jẹ olórí ilé igbimọ aṣofin ẹlẹkẹẹwa náà.

Eto naa ti o yẹ ki o ti bẹ̀rẹ̀ láti agogo mẹwa òwúrò ni kò tètè bẹ̀rẹ̀ rárá.
Ìwádìí fihàn pé olórí ilé igbimo asofin ipilẹ ogún, Olakunle Oluomo tí ó ń ṣojú ẹkùn idibò Ifo àti Hon Daisi Elemide tí ó ṣójú ẹkún idibò Odeda ni wọn jijọ fẹ́ díje sì ipò adari ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ipinlẹ náà.
Fọfọfọ ni ẹnu àbáwọlé ilé ìgbìmò aṣofin ipinlẹ Ogn kún fún àwọn ènìyàn, awọn akọroyin àti àwọn alẹnulọrọ níbi eto ifilọle ilé ìgbìmò asofin náà.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmò aṣofin mẹrindinlọgbọn ni wọ́n ń ṣojú ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun láti àwọn ijọba ìbílẹ̀ ti o wa ni Ìpínlẹ̀ Ògun.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin mẹ́tàdínlógún tí wọ́n wá láti ẹgbẹ́ oselu APC ni wọ́n yóò wa ní ìjókòó sì ilé ìgbìmò aṣofin ẹlẹkẹẹwa yìí nígbà tí àwọn mẹsan wá láti inú ẹgbẹ́ oselu PDP.
Ijoko òní yìí ní àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin náà ti yàn adari ilé àti igbakeji.
Ìgbà kẹrin nìyí tí Họnọrebu Taiwo Oluomo tí wá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ipinlẹ Ogun. Bákan náà, igbákejì rẹ, Họnọrebu Latifat Ajayi ti wá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ.














