Òkè ńlá wọlẹ̀ lásìkò ìjì òjò, àgbàrá òjò pa èèyàn mẹ́tàdínlógójì, gbé àwọn mẹ́rìndínlógun lọ, ilé ọgọ́rùn-ún bàjẹ́

Ko din ni eeyan mẹtadinlogoji ti agbara ojo gba ẹmi wọn lẹkun Iwọ-Oorun Indonesia, to si tun gbe awọn mẹrindinlogun lọ lopin ọsẹ to kọja yii.

Ojo nla ni wọn lo bẹrẹ laarọ ọjọ Abamẹta to kọja, ti awọn ara agbegbe naa ko si kọbi ara sii pe yoo ṣe wọn jamba.

Wọn ni bi ojo ọhun ṣe bẹrẹ ni ilẹ ru soke pẹlu atẹgun iji nla, eyi to ṣakoba fun ọpọ awọn olugbe agbegbe Mount Marapai, ilẹ ruru ti wọn lo lagbara julọ ni Sumatra.

“Mo gbọ ti ara san, ariwo to n jade si dabi ti omi gbigbona lati ara apata nla kan to jabọ lati ori oke Mount Marapi”

A gbọ pe awọn apata nla-nla to wa to wa lagbegbe naa ni wọn wọlẹ, paapaa ni Mount Marapi.

Ojiji ti iṣẹlẹ ọhun waye la gbọ pe o fa a to fi gbẹmi awọn mẹtadinlogoji ọhun, to si gbe awọn mẹrindinlogun lọ.

Bakan naa la gbọ pe ile ti ko din ni ọgọrun-un, to fi mọ awọn mọṣalaṣi ati awọn dukia ijọba lo bajẹ kọja afẹnuroyin.

Lara awọn ti ori ko yọ nibi ijamba ọhun sọ ohun ti oju wọn ri, ati ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa.

Iyale ile, ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Rina Devina, ninu ọrọ rẹ sọ pe, “Mo gbọ ti ara san, ariwo to n jade si dabi ti omi gbigbona.

O jẹ ariwo apata nla kan to jabọ lati ori oke Mount Marapi”

“Niṣe ni gbogbo rẹ dudu, mo wa lo foonu mi lati fi tan ina. Gbogbo ilẹ ti di amọ, mo wa bẹrẹ sii pariwo ‘Ọlọrun ṣaanu wa’ loore-koore”.

“Awọn kan sunkun, bẹẹ lawọn miran wa ni ikayasoke nigba ti wọn ko le ṣalaye ibi ti awọn eeyan wọn wa"

Obinrin ọlọmọ mẹta naa tun fi kun ọrọ rẹ pe “Ile to wa lẹgbẹ wa ti kun fun apata nla-nla, ti awọn ara ile keji mẹrin si ku loju ẹsẹ.”

Ajọ National Search and Rescue Agency sọ pe awọn oṣiṣẹ awọn, nigba ti yoo fi di ọsan ọjọ Aje, ti ṣawari oku eeyan mọkandinlogun ni abule kan ti wọn pe ni Canduang ni ẹkun Agam, ti wọn si tun ri oku awọn mẹsan miran ni ẹkun Tanah Datar to sunmọ ibẹ.

Berliana Reskyka, toun naa tun jẹ ọkan lara awọn olugbe agbegbe Agam nigba toun naa n sọrọ, ṣalaye iriri rẹ fun BBC, to si lo ba oun lẹru pupọ.

“Awọn kan sunkun, bẹẹ lawọn miran wa ni ikayasoke nigba ti wọn ko le ṣalaye ibi ti awọn eeyan wọn wa.

Awọn miran tiẹ wa to jẹ pe oku awọn eeyan wọn ni wọn n ri kaakiri.”