You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí o ṣe le mọ̀ pé o ti jìn sí ọ̀fìn tẹ́tẹ́ títá, àti bí o ṣe le bọ́
Tẹtẹ tita ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, ki i ṣe nnkan ana rara, wọn ti n ta a lati ọdun gbọọrọ, ṣugbọn iyatọ nla ti ba tẹtẹ tita lode oni, o si ti da bii ogun laye awọn kan.
Nibi to buru de lasiko yii, a ti ri awọn eeyan ti wọn n ta dukia bii ile, ilẹ̀, mọto, ọkada ati bẹẹ bẹẹ lọ lati ta tẹtẹ.
Kinni naa ko yọ awọn iyaale ile paapaa silẹ, obinrin mii n fi owo ọbẹ ta tẹtẹ.
Baale ile mii n fi owo to yẹ ko fi gbọ bukata nile ta tẹtẹ, bẹẹ la si n ri awọn akẹkọọ ti wọn fi owo ile ẹkọ wọn gbe 'two sure', wọn n ta tẹtẹ ki wọn le jẹ owo gọbọi.
Lojumọ to mọ lorilẹede Naijiria lonii, iwadii fidi ẹ mulẹ, pe ọgọta miliọnu (60m) ọmọ Naijiria ni wọn n ta tẹtẹ.
Awọn olootu rẹ si sọ pe bi wọn ṣe n ta a to yii, ida aadọrun (90%) lo tun ṣi wa nilẹ ti wọn o tiẹ ti i maa ta iru rẹ, ọkanjua n dagba, ọgbọn n rewaju ni.
Ninu okoowo to ru gọgọ to si pawo ju lasiko yii ni Naijiria, tẹtẹ tita jẹ ọkan gẹgẹ bi Micheal Eja, Adari ajọ to n mojuto tẹtẹ tita nipinlẹ Cross River ṣe sọ.
Ọgbẹni Eja ṣalaye pe 500bn si 600bn ni owo ti tẹtẹ tita n pa wọle.
O ni awọn to n ta a nikan si kọ lo n jere rẹ, ijọba naa n jẹ anfaani tẹtẹ, nitori o n pawo wọle, o si n pese iṣẹ fun awọn ọdọ.
Kí ni tẹ́tẹ́ títa gan-an?
Lai ni i fa ọrọ gun, itumọ tẹtẹ tita ko ju ki eeyan fi nnkan ẹyọkan silẹ, ko si fẹẹ fi gba ilọpo rẹ pada.
Bi iru ẹni ba jẹ, wọn yoo fun un nilọpo owo to fi ta tẹtẹ ọhun, bi ko ba si jẹ, owo rẹ to fi ta tẹtẹ ọhun wọgbo niyẹn.
Ironu pe awọn yoo jẹ ilọpo owo lo maa n wa lọkan awọn onitẹtẹ, wọn ki i fẹẹ fọkan sibi pe awọn le ma jẹ.
Eyi lo maa n jẹ ki wọn maa tẹsiwaju ninu iwa naa.
Bi eeyan ba jẹ owo nla nibi tẹtẹ, ẹni naa ko ni i sọ pe o ti to, yoo tun ta a si i ko le baa jẹ si i ni.
Bi iru ẹni bẹẹ ko ba waa jẹ mọ, tabi to padanu gbogbo owo nla to jẹ tẹlẹ, eyi ko tun sọ pe yoo fi tẹtẹ silẹ, yoo maa ta a lọ naa ni.
Eyi ni ọpọ eeyan fi gbagbọ pe nnkan to buru to si ni ẹmi buruku kan ti i ki i jẹ ki wọn le dẹkun rẹ ni tẹtẹ n ṣe.
Ǹjẹ́ òfin Naijiria lòdì sí tẹ́tẹ́ títa?
Ofin Ọlọrun lo lodi si tẹtẹ tita, iwe mimọ mejeeji ti i ṣe Bibeli ati Kurani lo tako iwa yii, to si kilọ pe eeyan ko gbọdọ dan an wo.
Labẹ ofin Naijiria, tẹtẹ tita ki i ṣe iwa ọdaran, niwọn igba ti ki i ba ti i ṣe pe ẹnikan jale lọọ ta a, ti ko si ijẹni-nipa tabi pe wọn fi dandan le e fun ẹnikan lati ta a.
Àléébù tó wà nínú tẹ́tẹ́
- Ijakulẹ nigba ti onitẹtẹ ba fi owo nla ta a ti ko si jẹ, n mu ẹlomiran pa ara rẹ.
- Ikayasoke ki esi tẹtẹ naa too jade n pa ẹlomiran pẹlu.
- B’awọn ẹlomi-in ba fi dukia nla bii ile ati ilẹ̀ ta tẹtẹ tan, wọn ko ni i pada jẹ, dukia naa ko si ni i ṣee ra fun wọn mọ laye.
- Titapa si ofin Ọlọrun ni tẹtẹ tita.
- Oju abuku, ẹni ti ki i ṣe ọmọluabi ni awọn eeyan maa n fi wo onitẹtẹ lawujọ.
- Awọn miran maa n lọọ ba were sọrọ ki wọn le baa jẹ tẹtẹ, ara to ba si wu alarun ọpọlọ ọhun lo le fi wọn da.
Bí o ṣe lè bọ́ nínú ògun tẹ́tẹ́ títa
Onimọ nipa iṣoro yii, Bimpe Akingba, akọwe ajọ Nigeria Bookmakers, sọ fun BBC pe ki i ṣe ẹni to n ta tẹtẹ nikan ni yoo ran ara rẹ lọwọ.
O ni ijọba ko ṣe pupọ lati ri ẹyin iṣoro yii.
Idi eyi si ni pe awọn to yẹ ko moju to o ti da oju kọ owo to n pa wọle, lodi si ipalara to le ṣe.
‘’A maa n ba awọn to ti di baraku fun sọrọ, a maa n la wọn lọyẹ ti a tun maa pe awọn amoye ti yoo ba wọn sọrọ pẹlu, ṣugbọn iyẹn nikan ko to.
Yatọ si pipe awọn akọṣẹmọṣẹ lati da wọn lẹkọọ, ojuṣe gbogbo wa ta a wa lawujọ ni, ta a ba fẹẹ ṣẹgun iṣoro tẹtẹ tita .
‘’Gbogbo eeyan lo gbọdọ lọwọ si atunṣe yii, bẹrẹ lati ori awọn ti wọn n ri si ọrọ tẹtẹ tita.
‘’Awọn ileeṣẹ ti wọn n da a silẹ, titi kan awọn ẹbi wọn ni wọn gbọdọ da si i.
‘’Eeyan o ṣaa ni i maa wo ẹbi tabi ololufẹ rẹ niran ko maa ṣe ohun to ku diẹ kaato.’’
Bẹẹ ni Bimpe Akingbe, Akọwe ajọ Nigeria Bookmakers ṣe ṣalaye.