You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ariwo tún sọ lórí ikú Mohbad, ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ rẹ̀, Primeboy lérí láti pe ìyá olóògbé lẹ́jọ́
Ọkan pataki ninu awọn ọrẹ oloogbe Ilerioluwa Aloba (Mohbad), Ibrahim Owodunni tawọn eeyan mọ si Primeboy, ti leri lati pe iya Mohbad lẹjọ bayii, nitori ẹsun ibanilorukọjẹ to fi kan iya naa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro to n ṣoju fun Primeboy, Akinpelu Ogunbona, fi sita, ni wọn ti fi ẹsun ibanilorukọjẹ kan Abosede Adeyemo-Aloba, iya Mohbad.
Lẹta naa ṣalaye pe iya Mohbad ṣe ifọrọwanilẹnuwo kan lori ayelujara, nibẹ lo ti sọ pe gbogbo igba ni Primeboy maa n ba Mohbad ja nigba ti oloogbe wa laye.
Wọn ni iya Mohbad tun sọ ninu ifọrọwanilẹnwo naa, pe gbogbo igba ni Primeboy maa n rojọ pe Mohbad gbagbe oun lẹyin to di olokiki tan.
“ O sọ pe onibaara mi maa n fi gbogbo igba ba Mohbad ja latigba ti okiki rẹ ti buyọ. Bakan naa lo tun sọ pe awọn kan gba onibaara wa lamọran pe ko tete sa lọ lẹyin iku Mohbad, ki wọn ma baa fura si i nipa iku naa.
‘’O mọ ọn mọ sọ awọn ọrọ yii lati tabuku onibaara wa ni, ọrọ naa si ti n nipa buruku lara rẹ pẹlu oju ti awọn ololufẹ Primeboy fi n wo o kaakrii bayii, bẹẹ o mọ pe akọrin ti ogo rẹ ti n buyọ ni’’
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yín lẹ́tà Primeboy?
Ninu lẹta to kede ẹsun ti Primeboy fi kan iya Mohbad ni wọn tun kọ ọ si, pe ki obinrin naa tete yi ohun to sọ pada laaarin ọjọ meje.
Bi ọjọ meje ba pe ti Abilekọ Aloba ko yi ohun ti wọn lo sọ naa pada, Primeboy leri pe oun yoo pe iya ọrẹ rẹ lẹjọ, kootu yoo da si ọrọ awọn.
Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni Amofin Ogunbọna kede pe awọn nnkan tuntun kan tun ti ṣẹlẹ, to si yẹ ki Wumi Aloba, iyawo Mohbad pẹlu awọn ọlọpaa tan imọlẹ si iku to pa akọrin naa.
Agbẹjọro ọhun tun sọ nigba naa pe onibaara oun ko lẹbọ lẹru.
Kekere ni ọrẹ Mohbad ati Primeboy ti bẹrẹ, wọn si jọ wa titi di ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an ọdun 2023 ti Mohabd ku lojiji ni.
Ọlọpaa ko Primeboy, Naira Marley ati gbajumọ, Balogun Eletu (Sam Larry) latari iku Mohbad nigba naa, ki wọn too pada fi wọn silẹ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn sare sin Mohbad, ijọba paṣẹ ki wọn hu oku naa fun ayẹwo, eyi ti wọn hu lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2023.
Lẹyin ayẹwo, ati titi di asiko yii, ẹnikẹni ko ti i mọ iru iku to pa Mohbad, ṣugbọn ariwo ko tan lẹyin iku ọhun titi doni.