Mọ nípa àwọn òfin tó de wíwọ aṣọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijria ni ọpọ igba ti pariwo sita pe awọn ko nifẹ si awọn alawada se n fi asọ ileeṣẹ ọlọpaa fi da para, eyi ti wọn ni o tabuku si isẹ ileeṣẹ ọlọpaa.
Bakan ni iwe ofin orilẹede Naijiria, eyi to sọrọ nipa iwa ọdaran salaye pe ẹnikẹni ti ko ba ki n se osisẹ ẹsọ alabo ko lẹtọ si wiwọ asọ naa.
Iwe ofin naa ni
"Ẹnikẹni ti ko ba sisẹ pẹlu ileeṣẹ alabo orilẹede Naijiria ko lẹtọ lati wọ asọ ileeṣẹ naa tabi ko lo eyi ninu awọn ami to wa lara asọ, ayifi to ba ti gba asẹ lọwọ Aarẹ orilẹede Naijria tabi Gomina ipinlẹ rẹ ko to wọ asọ naa.
"Ẹnikẹni to ba tako si ofin yii yoo ri ijiya toto ọdun mẹta lọgba ẹwọn tabi ko san owo itanran, tabi ko lọ si ẹwọn, ko dẹ tun san owo itanran,"
Ẹ gba asẹ ki ẹ to lo asọ Ọlọpaa ninu ere yii- Ileeṣẹ Ọlọpaa
Saaju ni alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi ti se ni ikilọ fun awọn elere olori ayelujara lati dẹkun fifi asọ sapajuwe iwa ti ko dara, to si rọ wọn lati gba asẹ ki wọn to lo asọ naa.
Ademuyiwa ninu atẹjade kan ileeṣẹ ọlọpaa n kominu lori bi awọn kan se n ta asọ ileeṣẹ ọlọpaa lojọ, eyi to ni ijọba ko fọwọ si rara.
O ni bi awọn elere sinima lori ayelujara se n fi asọ ileeṣẹ ọlọpaa fi n sapejuwe ohun ti ko da nini sinima ti wọn gbe jade ni ko dun mọ ileeṣẹ ọlọpaa ninu rara.
O wa rọ awọn elere ayelujara lati yii lati ri pe wọn gba asẹ lọwọ ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa ko to di pe wọn yoo lo asọ naa tabi ki ileeṣẹ ọlọpaa fi ofin mu wọn.
Ki lo sẹlẹ laarin Cute Abiola ati Ileeṣẹ Ọlọpaa
Toun ti bi ofin orileede Naijiria ṣe faye gba ẹtọ araalu,kii ṣe bi ti pe ki wọn wa maa fi ẹtọ wọn tabuku ileeṣẹ ọlọpaa.
Gbolohun to ṣaaju ọrọ atẹjade ti alukoro agba ileeṣẹ ọlọpaa fi sita ree nipa bi adẹrinposonu nii Cute Abiola ṣe fi asọ ọlọpaa ṣawada lọna to tabuku ileeṣẹ wọn.
Olumuyiwa Adejobi sọ pe fọnran awada kẹrikẹri to ṣe to sipin loju opo ayelujara tabuku ti ko si bọwọ fun aṣọ ọlọpaa.
O ni iwa yi tapa sofin Naijiria to si ni iru iwa yi yoo maa '' tapo si aṣọ aala awọn ọkunrin ati obirin to n fi tọkan tọkan ṣe iṣẹ ọlọpaa''
Ni bayii o wa sọ pe awọn yoo ṣe iwadii Cute Abiola ti orukọ rẹ gangan n jẹ Abdulgafar Abiola tos i ṣeeṣe li o foju wina ofin lori iwa to hu.
Lẹnu ọjọ mẹta yi, ileeṣẹ ọlọpaa ti n koro oju si awọn adẹrinposonu loju opo ayelujara fawọn kudiẹkudiẹ kan ninu fidio ti wọn n gbe sita.
Laipẹ yi ni arakunrin kan taa mọ si Trinity Guy naa wọ gau lori fọnran to gbe sita eleyi to tabuku ọmọ obinrin keklere kan.
Igba akọkọ kọ ni yi ti Cute Abiola ati awọn alaṣẹ yoo maa gbena woju ara wọn lori awada rẹ.
Nigba to ṣi jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi Naijiria, awọn ọga rẹ fi si atimọle lori bo ṣe n fi aṣọ awọn agbofinro ati ibọn ṣe awada skit rẹ.
Cute Abiola ko ti fesi sọrọ tawọn ọlọpaa sọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












