Kò sí bí ológun tún ṣe lè rí ìjọba gbà mọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà - Ọ̀gágun Adisa Raji, gómìnà ológun nígbàkanrí
Pẹlu bi ọrọ iditẹ gbajọba ologun ṣe fẹ maa di tọrọ fọnkale bayii lawọn orilẹede ti wọn wa layika orilẹede Naijiria lẹkun iwọ oorun Afirika, ọpọ lo ti n beere bayii pe ṣe kini ọhun ko maa da bi iku to n pojugba ẹni, owe lo n pa a fun ni.
Amọṣa ọkan pataki lara awọn ọgagun ileeṣẹ ologunNaijiria nigbakan ri, Ọgagun Rasheed Adisa Raji ti sọ pe ko si ifoya fun orilẹede Naijiria.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Ọgagun Adisa Raji sọ pe ko si aaye fun ọmọ ologun kankan lati sọ pe oun fẹ ditẹ gbajọba lorilẹede Naijiria nitori pe, iṣejọba tiwanti ti di igi alọye lorilẹede Naijiria.
Ọgagun Adisa Raji figbakan ri jẹ gomina ologun ni ipinlẹ Bauchi ati Sokoto ṣalaye pe ohun ti araalu n fẹ bayii ni iṣejọba tiwantiwa, ko si si ọna meji si eyi.
Ko si bi ologun ṣe le ṣe ijọba mọ ni Naijiria - Ọgagun Adisa Raji
“Nisiyi lori boya ijọba ologun le pada yoo le diẹ.”
Eyi ni esi ti ọgagunfẹyinti naa fọ si ibeere lori boya ki awọn ọmọ Naijiria o maa paya lori bi iditẹgbajọba ṣe n waye lawọn ayika rẹ.
Ọgagun ojuomi, Adisa Raji ni ko si idi fun ologun lati gba ijọba mọ bayi lorilẹede Naijiria ati pe aye ti laju ju ti igba tawọn ologun n ja ijọba gba ni Naijiria.
O ni yoo nira pupọ fun ologun lati sọ pe oun fẹ gba ijọba ni Naijiria bayii nitori pe ko si araalu to fẹ ijba miran yatọ si ti ti alagbada mọ ni Naijiria.
Idi ti wọn fi fi mi jẹ Baba Isalẹ Adini
Nigba to n dahun ibeere lori bo ṣe jẹ oye gbankọ gbi lori ẹsin nilu Ẹgba, Ọgagun Adisa Raji ni awọn eto iranwọ ati idagbasoke ti oun ṣe si ilu lawọn igba ti oun ṣi wa lẹnu iṣẹ ologun lo mu ki wọn ro ipo ẹsin nla naa ro oun.
Iya mi fariga nigba to gbọ pe mo fẹ darapọ mọ ologun
Nigba to n sọrọ lori irinajo rẹ si iṣẹ ologun, Ọgagunfẹyinti Adisa Raji ṣalaye pe gẹgẹ bi ọpọ awọn obi ṣe maa n ṣe nigba ti awọn ọmọ wọn ba fẹ lọ si oju ogun, iya oun ko fara mọ ki oun dara pọ mọ iṣẹ ologun.



