Ayefẹlẹ ko ku o. Irọ ni wọn pa

Aworan yinka

Oríṣun àwòrán, Yinka Ayefele/Facebook

Gbajugbaja akọrin ati oludasilẹ ileeṣẹ redio Fresh Fm, Dr Yinka Ayefẹlẹ ti ṣe alaye wi pe nnkan ibanujẹ ni fidio kan to n rin kaakiri lori ikanni ayelujara Tiktok, nibi ti wọn ti kede wi pe oun ti jade laye.

Fidio naa ti awọn eeyan kan n pin kaakiri ori ẹro ayelujara ni wọn ti ṣe afihan aworan Ayefẹlẹ ati awọn ibẹta rọ, bẹẹ sini wọn fi orin idagbere Tope Alabi si aworan naa.

Arakunrin kan ti wọn fi ẹsun kan wi pe o ṣe iṣẹ ibi naa ni wọn pe orukọ rẹ ni David.

Alaye ti Ayefẹlẹ ṣe fun awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun ni wi pe niṣe ni ẹrọ ibanisọrọ oun n dun ni kikan kikan lati ọwọ awọn ololufẹ rẹ to n pe kaakiri agbaye lati beere boya lootọ iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ayefẹlẹ fi iyalẹnu han wi pe ki ni ere ti ẹni to gbe iru fidio naa jade fẹ jẹ ninu iwa laabi naa.

O ni, "Emi ki yoo ku bikoṣe yiye lati maa royin iṣẹ Oluwa. Ọlọrun mọ awọn eeyan to wa lẹyin iroyin ofege naa, yoo si fi iya jẹ wọn.

Ki ni ere ti wọn fẹ jẹ ninu iroyin ofege wi pe mo ti jade laye?"

O ke si awọn ololufẹ rẹ lati kọ eti ọgbọin si iroyin ofege. O ni, "Bi Jesu ba fa bibọ rẹ sẹyin, ọpọlọpọ ọdun ni a o ṣe lori ilẹ yii".