Báyìí ni ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ afurasí ṣe ṣá Ọ̀gá pa, jù ú sínú kànga l'Ondo

Afurasi

Ọmọ ẹ̀kọ́ṣe kan ti ọjọ ori rẹ to ogun ọdun ko si gbaga Ọlọpaa lori ẹsun pe o pa ọga to n kọ ọ nísẹ, Savior Joseph.

Ileeṣẹ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ naa ṣàlàyé pé ọmọ ẹ̀kọ́ṣe pada ju oku ọga rẹ ọhun sínú kanga kan ni agbegbe Imafon, Akure ni Ìpínlẹ̀ Ondo.

Arakunrin kan, Odey Julius Ogbaji to jẹ ẹ̀gbọ́n olóògbé Savior Joseph sọ fun awọn oniroyin ohun to ṣẹlẹ̀.

Iroyin ni wahala naa ṣẹlẹ̀ nigba ti Oga arakunrin ọhun to jẹ eeyan to mọ isẹ orule ile, POS daadaa la foonu ẹni to n kọ níṣe mọ́lẹ̀ nitori àìgbọ́raẹniye kan to ṣẹlẹ̀ laarin wọn.

O ni awọn ba oku ẹni ọdun metadinlogbon naa ni ọjọ mẹrin sẹ́yìn ninu kanga nibi ile kíkọ to ti n ṣiṣẹ́ pẹlu ọmọ ẹ̀kọ́ṣe naa nilu Imafon.

Ṣe ni wọn ni ọmọ ẹ̀kọ́ṣe naa parọ nípa ibi ti Oga rẹ wa nigba ti wọn beere lọwọ rẹ.

Gẹgẹ bi ẹ̀gbọ́n oloogbe náà ṣe sọ, a kan si ọmọ ẹ̀kọ́ṣe ọhun a si beere nipa ibi ti Oga rẹ wa o si ni Ọga oun ji ni oru, o gba foonu oun o si fọ ọ mọ́lẹ̀ to tun bẹ̀rẹ̀ si ni lu òun, lẹyin eyi, o ni o sọ pe ki oun lọ sun pada.

"Ni ọjọ kejì, o ni oun pinu lati kuro nibi isẹ ile naa. A wa bii pe bawo lo ṣe ji laarọ ti o ko ri ọga rẹ too si kuro lẹ́nu isẹ? Ó ni oun lero pe o lọ ile igbọnsẹ ni."

"Nigba ti a yẹ foonu to ni Ọga là mọ́lẹ̀ wo, a ko ri ami pe o san loju rárá. Yàtọ̀ fun ìyẹn, o pa foonu ko si tun fi ẹjọ́ sun ẹnikẹ́ni ", o ṣàlàyé.

Ki ni Ọlọpaa ń ṣe nípa rẹ?

Ileeṣẹ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Ondo ni awọn ti gbe ẹjọ́ afurasi naa lọ si ẹ̀ka ìṣewadii Ìpínlẹ̀ naa ni Akure.

Alukoro Ọlọpaa, Funmilayo Odunlami-Omisanya fi aridaju eleyi han to si ṣàlàyé pé àwọn ṣi n ṣe ìwádìí lọwọ "bẹẹ si ni a o gbe afurasi naa lọ ile ẹjọ́ lẹyin ti a ba pari iwadii wa."