You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kì í ṣe pé mi ò nífẹ̀ẹ́ PDP, ìdí tí mo fi kúrò níbẹ̀ rèé - Gómìnà Adeleke
Lẹyin ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP to gbe e depo, gomina naa ti ṣalaye idi to fi di dandan fun un lati fi ẹgbẹ naa silẹ.
Ana ode yii ti i ṣe Ọjoru ni Adeleke gbegba oroke bii ẹni ti yoo dupo gomina ninu ẹgbẹ Accord to darapọ mọ, lẹyin to kede pe oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ PDP mọ lọjọ Iṣẹgun.
Nigba to n ṣalaye idi rẹ to ṣe fi PDP silẹ lẹyin to ti figba kan leri pe oun ko ni i kuro ninu ẹgbẹ ọhun, Adeleke sọ pe oun nifẹẹ PDP, ṣugbọn ohun to yẹ foun ni lati kuro nibẹ lasiko yii.
Lori eto ileeṣẹ amohumaworan Channels to ti ṣalaye ọrọ naa l'Ojọru lo ti ni:
" Irọ ni pe mo kọ PDP silẹ, mo nifẹẹ PDP, ṣugbọn mo gbọdọ da aabo bo ara mi.
"Mo gbọdọ ri i daju pe mo gbe igbesẹ ti yoo jẹ ki iṣẹ ribiribi ti a n ṣe tẹsiwaju."
Gomina Adeleke sọ pe boun ṣe kuro ni PDP ki i ṣe fun anfaani ara oun nikan, bi ko ṣe fun itẹsiwaju ipinlẹ Osun lapapọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2022 ni Adeleke di gomina Osun, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP to ti dije, ọdun naa lo fi ẹyin Gboyega Oyetola to wa lori ipo naa tẹlẹ janlẹ.
Ṣé ó 'ṣúọ̀' fún Adeleke nínú ẹgbẹ́ Accord ni 2026?
Ẹwẹ, ibeere ti ọpọ eeyan n beere bayii ni pe njẹ aṣeyọri daju fun Adeleke ninu ẹgbẹ Accord to darapọ mọ yii.
Eyi ri bẹẹ pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n fi oju wo ẹgbẹ naa pe ko fi bẹẹ gbajumọ.
Ọpọ n sọ pe Accord ki i ṣe ẹgbẹ ti orukọ rẹ rinlẹ rara, wọn ni ko ma lọ jẹ ohun ti yoo mu ki Adeleke padanu ipo gomina lo rawọ le pẹlu Accord to wọ.
Ṣugbọn Gomina Adeleke funra rẹ ti fesi si eyi, o ni ẹru o b'odo.
Adeleke sọ pe iṣẹ ti oun ṣe ni saa akọkọ yii ni yoo fọhun foun nigba ti idibo gomina Osun yoo ba waye ni 2026.
Gẹgẹ bo ṣe wi:
"Awọn eeyan ipinlẹ Osun ti gbọn si i, wọn si mọ iyatọ laaarin ijọba rere ati ijọba buburu, wọn si ti pinnu lati rin ọna Imọlẹ, emi lọmọ ti wọn n sọ."
Gomina Adeleke tẹsiwaju pe ẹgbẹ oṣelu kọ lo ṣe koko, o ni àtẹ̀gùn lasan ti eeyan fi n dije ni ẹgbẹ jẹ.
O fi kun un pe ohun ti gomina to kuro nipo ṣe labala ai ri owo oṣu oṣiṣẹ gba, to lọtọ fun awọn eeyan lati mọ pe iṣejọba awọn ko jọra wọn.
"Emi wọle mo mu ireti wa, mo mu imọlẹ de ipinlẹ Osun. Fun idi eyi, iṣẹ mi ni akọkọ ohun ti yoo fọhun fun mi."
Koda, o ni ẹru ijọba apapọ ko ba oun. O ni ẹgbẹ alatako loun wa toun fi di gomina ni 2022, oun si lero pe bi yoo ṣe ri lọdun to n bọ naa niyẹn.
Gomina Adeleke sọ pe ọkan oun balẹ, pe awọn eeyan Osun yoo wo aṣesilẹ iṣẹ oun iṣaaju, wọn yoo si fi ibo wọn da oun pada sipo gomina lọdun to n bọ.
"PDP àti Accord yóò fọwọ́ tí Adeleke láti wọlé fún sáà kejì, bí gómìnà ṣe borí ìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ Accord l'Osun"
Ni ọjọ Kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun 2025 ni Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke kede pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ osẹlu Accord Party.
Igbesẹ yii ni awọn eeyan ti n reti lẹyin to ti kọkọ kede ṣaaju pe oun ti fi ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP silẹ tawọn eeyan si n beere pe ẹgbẹ oṣelu wo lo fẹ lọ.
Adeleke ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ sọ pe lati ọjọ Kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni oun ti darapọ mọ Accord Party.
Eyi si ti n mu ki awọn eeyan maa beere pe ṣe Adeleke yoo ri aaye jokoo ni ẹgbẹ tuntun to lọ yii bi o ṣe jẹ pe eto idibo sipo gomina fun saa mii ni ipinlẹ naa ko ni pẹ gberasọ.
BBC News Yoruba kan si alaga ẹgbẹ oṣelu Accord Party tẹka ipinlẹ Osun, Victor Akande, to si sọ wi pe awọn ni igbagbọ ninu gomina Ademola Adeleke ni awọn ṣe f'aaye gba lati darapọ mọ ẹgbẹ awọn.
"Lati igba ti gomina Adeleke ti n tu ọkọ iṣejọba ipinlẹ Osun ni iyatọ ti ba ipinlẹ Osun, ẹni to n sinlu ni Adeleke kii ṣe ọjẹlu bii tawọn ijọba to ti kọja lọ."
O ṣalaye pe ẹgbẹ awọn ko i tii ni oludije ti awọn fẹ fa kalẹ fun eto idibo ipinlẹ naa ti yoo waye lọdun 2026 eyi to mu gbigba gomina Adeleke rọrun.
"Loootọ a ko tii ni oludije si ipo gomina ki Gomina Adeleke to fara han wi pe, ohun fẹ darapọ mọ ẹgbẹ Accord.
"Sugbọn igba ti gomina Adeleke ti fara han lati darapọ mọ ẹgbẹ wa ni awọn to ni oludije si ipo gomina bayii."
Alaga ẹgbẹ naa fi kun pe gbogbo ileri ti Gomina Adeleke ṣe fun ẹgbẹ oṣelu Accord ati eyi to ti ṣe fun ara ilu ni awọn ní igbagbọ pe yoo mu ṣẹ.
O sọ pe oun gbagbọ pe ẹgbẹ awọn ati Gomina Adeleke ni yoo jawe olubori ninu idibo to n bọ naa nitori ẹgbẹ Accord jẹ ẹgbẹ to dara ati wi pe awọn ṣe iṣẹ silẹ fun gomina Adeleke.
'Awọn ara ipinlẹ Osun fẹran Adeleke, yoo tun wọle fun saa keji'
Oludamọran Gomina Adeleke lori eto iroyin, Oladele Bamiji sọ fun BBC News Yoruba pe ọrọ gomina Ademola Adeleke dabi irin ti a gbe lati oke ọya wa si ipinlẹ Osun pe irin naa ni yoo maa jẹ nitori ẹni ti ara ilu fẹràn ni gomina Adeleke.
O ni bi Adeleke ṣe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party bọ si Accord Party ko ni ohun kankan ṣe lori ijawe olubori rẹ nibi eto idibo to n bọ.
"Idaniloju wa fun gomina Adeleke pe, oun ni yoo borí ninu idibo si ipo gomina ipinlẹ Osun ni ọdun 2026."
Bamiji sọ pe idi ti gomina Adeleke ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord, ko ṣẹyin aawọ to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lati oke.
O sọ pe kii ṣe gomina Adeleke nikan lo da ero naa pa bikoṣe awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu ati awọn ara ilu to ri ohun n to ṣẹlẹ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
O fi kun pe ọpọlọpọ oludibo nipinlẹ Osun lo ti ṣetan lati satilẹyin fun gomina Adeleke lati ri pe o wọle fun saa ẹleekeji.
"Igbagbọ tun wa fun gomina Adeleke wi pe, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ẹka ti ipinlẹ Osun ko ni fi gomina Adeleke sílẹ.
Alaga naa yoo ṣe atilẹyin fun gomina Adeleke nitori pe, wọn ti ri gudugudu meje ati yaya mẹfa ti gomina Adeleke ti ṣe sinu ẹgbẹ oṣelu PDP ati fun ara ilu."
Gomina Adeleke bori ibo abẹnu Accord Party
Ẹgbẹ oṣelu Accord ẹka ti ipinlẹ Osun, ti ṣe eto idibo abẹnu lati yan ẹni ti yoo gba asia ẹgbẹ naa lati dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ naa nibi eto idibo ọdun 2026.
Gomina Ademola Adeleke nikan si ni oludije ti ẹgbẹ oṣelu Accord ni lati kopa ninu idibo abẹnu naa.
Awon asoju marun-un ni ijọba ibilẹ kọọkan lo dibo naa ti gomina Ademola Adeleke si jawe olubori ninu idibo ọhun