Human Rights Day: Wo àwọn ẹ̀tọ́ rẹ lábẹ́ òfin àtàwọn ọ̀nà tí wọn ń gbà tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oriṣiriṣi si ni ẹ̀tọ́ ọmọniyan l'agbaye, paapaa ninu ofin orilẹ-ede Naijiria.

Amofin, to tun jẹ Alaga tẹlẹ fẹgbẹ awọn agbẹjọro obinrin l'orilẹ-ede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ, Debby Collins ṣalaye fun BBC, ohun ti ẹtọ ọmọniyan jẹ.

O tọka si ẹtọ lati wa laye, ẹtọ lati ṣe ẹsin tabi jọsin nibi to ba wu ọ, ẹtọ lati sọ ero ọkan rẹ, ẹtọ lati rin si ibi to ba wu ọ, ẹtọ lati darapọ mọ ipejọpọ to ba wu ọ, ati bẹẹbẹ lọ.

O ni: "ẹtọ rẹ jẹ nkan ti ẹnikẹni ko le gba lọwọ rẹ nitori pe lati ọrun lo ti mu u wa.

Eyi to ṣe pataki ni ẹmi rẹ ti ẹnikẹni, labẹ ohunkohun ko lẹtọ lati gba lọwọ rẹ.

Ẹmi eniyan jẹ nkan ti ẹnikẹni ko le deede gba lọwọ ẹlomiran, nitori pe kii 'se ohun ti a le fi funni.

Ki ni o tumọ si ti a ba n tẹ ẹtọ ẹni mọlẹ?

Amofin Debby ni: Ti a ba ti gba ẹmi lọwọ ẹnikẹni, wọn ti gba gbogbo ẹtọ to ku niyẹn. Nitori pe oku ko le ṣe ohunkohun mọ."

Bakan naa ni Amofin Dabby ṣalaye ni kikun pe: ẹnikẹni ko le titori pe nkan jẹ ẹtọ rẹ, ki o ti tori rẹ tẹ ẹtọ ẹlomiran mọlẹ.

"Ti o ba mọ ẹtọ rẹ, o ko ni i tẹ ẹtọ ẹlomiran mọlẹ."

Lori bi awọn obi kan ṣe maa n ba ọmọ wi lọna ait, Arabinrin Collins ṣalaye wi pe biba ọmọ wi gbọdọ jẹ lati inu ifẹ.

Ko tọ ki obi o maa ba ọmọ nipa fifi apa si lara. Eyi kii ṣe ibawi, bikoṣe iwa ẹranko nitori pe awọn ọmọde naa ni ẹtọ wọn labẹ ofin.

Ofin orilẹ-ede Naijiria lori ẹtọ ọmọde ko faaye silẹ lati lò tabi na ọmọ ni ọna aitọ tabi fi apa si ọmọ lara.

Bawo ni ayajọ ẹtọ ọmọniyan ṣe bẹrẹ?

Ọdun 1948 ni awujọ agbaye ya ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila sọtọ lati maa mọ riri ẹtọ ọmọniyan ni awujọ agbaye.

Agbakalẹ yii fihan pe ẹnikẹni ko gbọdọ tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ boya nitori ọjọ ori, ẹ̀ya, ẹ̀sìn, ipo lawujọ, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Àwọn obìnrin ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn tó ń fakọyọ lásìkò yìí

Ọpọlọpọ awọn obinrin lo si ti ṣe takuntakun ninu jija fun ẹtọ ọmọniyan l'agbaye, eyi ti ko yọ orilẹ-ede Naijiria naa silẹ.

Ọjọ ti pẹ diẹ ti awọn obinrin ti n ja fun ẹtọ ọmọniyan l'orilẹ-ede Naijiria.

Oloogbe Olufunmilay Ransome-Kuti si ni o han pe o jẹ obinrin akọkọ to ja fun ẹtọ awọn obinrin ni Naijiria Ta ni Funmilayọ Ransome-Kuti?.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1900 ni a bi Frances Abigail Olufunmilayọ Thomas sinu idile ti wọn fẹran ẹ̀kọ́ iwe.

Olufunmilayọ ni olori ẹgbe ìṣọ̀kan àwọn obinrin Ẹ̀gbá nigba naa.

Ọkan Funmilayọ poruru nigba ti o gbọ ohun to n ṣelẹ sawọn obinrin Egba lọwọ awọn oṣiṣẹ Alake ati Ajẹlẹ ati pe, wọn n tún irẹsi ti wọn fagídí gbà lọwọ awọn obinrin naa tà, ti wọn n kowo rẹ sapo ara wọn.

Oun lo ṣaaju ìwọ́de ti wọn ṣe lati fẹhonuhan lori owo orí gọbọi àti ìyà ti wọn n jẹ lọwọ awọn Oyinbo Ajẹ́lẹ̀.

Wo àwọn ọdọbinrin asiko yii to n ja fun ẹtọ awọn ọmọniyan ni Naijiria:

Olaoluwa Abagun:

Ọdun 1992 ni wọn bi Ọlaoluwa Abagun.

O ṣe ifilọlẹ eto ipolongo ti yoo mu ki awọn ọdọmọbinrin o maa gbogun ti ifipabanilopọ.

Eto yii wa lati maa kọ awọn obinrin ni ọna ti wọn le fi daabo bo ara wọn lọwọ ifipabanilopọ.

Nibi ipade ajọ Isọkan agbaye lo ti fi lọlẹ lọdun 2016. Oun si ni ọmọ Naijiria kan ṣoṣo to ri owo iranwọ gba lọwọ ajọ Womaen Deliver Organization.

Maryam Awaisu:

Maryam Awaisu jẹ́ onkọwe ati ajafẹtọ ọmọniyan

O jẹ ọ̀kan lara awọn ọdọmọbinrin to ṣe idasilẹ eto ipolongo #ArewaMeToo, lati le fun awọn obinrin ti wọn fi ipa balopọ ni igboya lati jade si gbangba, ki wọn o si gbe igbesẹ.

Nitori awọn ọrọ to sọ ati igbesẹ rẹ lori ọrọ naa, awọn oṣiṣẹ alaabo mu ni ọgba ileewe rẹ, botilẹjẹ wi pe wọn pada yọnda rẹ.

Joe Okei-Odumakin:

Josephine Okei-Odumakin jẹ Aarẹ ẹgbẹ Women Arise for Change Initiative, ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ awọn obinrin lorilẹ-ede Nigeria.

Ọpọlọgbọ igba ni wọn ti fi panpẹ ofin mu u si atimọle, paapa lasiko ijọba ologun Ibrahim Babangida.

Ogunlọgọ ẹsun titẹ ẹtọ obinrin loju lo si ti da si to ti bi eso rere fawọn ti ọrọ kan.

Ileeṣẹ alaabo ilẹ Amẹrika fun un ni ami ẹyẹ International Women of Courage Award ni ọdun 2013.

Aya aarẹ Amẹrika nigba kan, Michelle Obama ati John Kerry lo gbe ami ẹyẹ naa le e lọwọ.

Obiageli Ezekwesili:

Ọdun 1963 ni wọn bi Obiageli Ezekwesili nipinlẹ Anambra. O kẹkọ gboye nini iṣẹ iṣiro owo.

O jẹ ọ̀kan lara awọn to da ikọ̀ ipolongo #BringBackOurGirls lori ẹrọ ayelujara.

Eto naa jẹ́ ipolongo lati gba awọn akẹkọbinrin ileewe Chibok ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram ji gbe nileewe wọn lọdun 2014.

Loṣu Kẹta, ọdun 2019, Ezekwesili gba ami ẹyẹ Forbes Woman Africa Social Influencer fun akitiyan rẹ lori ipolongo #BringBackOurGirls lori ayelujara.