Wo àwọn gómìnà PDP tó ti fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ àti àwọn tó ṣẹ́kù

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iji lile to n daamu ẹgbẹ oṣelu PDP, eyi to n mu awọn ọmọ ẹgbẹ naa kuro nibẹ nikọọkan-ejeeji ko ti i duro rara, niṣe lo n peleke si i.

Lanaa ode yii ni awọn gomina meji, Ademola Adeleke, ti ipinlẹ Osun, ati Siminalayi Fubara, ti ipinlẹ Rivers tun fi PDP silẹ, ti wọn gba ẹgbẹ miran lọ.

Ẹgbẹ Accord ni Ademola Adeleke darapọ mọ ni tiẹ, bo tilẹ jẹ pe ṣaaju lo ti n sọ pe oun ko ni i fi PDP silẹ, pe ọmọ ẹgbẹ Alaburuda loun tọkan-tọkan.

Ṣugbọn lanaa, Adeleke kede pe oun ko ṣe PDP mọ, Accord loun yoo ti dije fun saa keji.

O ni rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni ẹka apapọ PDP lo mu oun fi wọn silẹ lọ.

Alaye gomina Fubara to fi kuro ninu ẹgbẹ PDP

Fubara ni tiẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, o si ṣalaye pe oun ti gba aṣẹ lati kuro ninu ẹgbẹ PDP.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, o ni oun ti ṣepade pẹlu Aarẹ, oun ko fẹ ṣe aṣiṣe kankan lọtẹ yii.

Gẹgẹ bi Fubara ṣe wi, wọn gba oun laye lati fi PDP silẹ, nitori ko si aabo fawọn ninu ẹgbẹ naa.

"Apa ibi tẹ ẹ ti n duro de ree, a ti pinnu lonii, a n lọ si APC."

Siminalayi Fubara lo sọ bẹẹ.

Pupọ ninu awọn gomina to fi ẹgbẹ to gbe wọn depo silẹ naa lo ṣalaye, pe awọn fẹ ba ijọba apapọ fọwọsowọ pọ ni.

Yatọ si Fubara ati Adeleke to tun ṣẹṣẹ kuro ni PDP, eyi ni awọn gomina miran ti wọn tun ti fi ẹgbẹ alaburada silẹ

Àwọn ìpinlẹ tí gomina wọn ti fi PDP silẹ lọ

Lara awọn ipinlẹ ti gomina wọn ti kuro ninu ẹgbẹ PDP ni:

  • Enugu: Peter Mbah ni gomina ipinlẹ Enugu, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa lo kede pe oun ti fi PDP silẹ, o gba APC lọ.

Mbah sọ pe oun fẹ ki ajọṣepọ wa laaarin ijọba oun ati awọn

ẹkun Guusu.

Ko da lọ si APC, o ko awọn alaga ijọba ibilẹ atawọn oloṣelu nla nipinlẹ naa lọ pẹlu.

  • Bayelsa

Douye Diri ni gomina ipinlẹ Bayelsa, oṣu Kọkanla lo kede pe oun naa ti yago fun PDP, ọmọ ile igbimọ aṣofin 23 lo ko wọnu ẹgbẹ APC.

  • Delta

Sheriff Oborevwori ni gomina ipinlẹ Delta. Ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹrin lo fi PDP silẹ lọ si APC.

  • Akwa Ibom

Gomina Umo Eno ti ipinlẹ Akwa Ibom, kede pe oun ti fi PDP silẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa ọdun 2025.

Umo ni oun fi PDP silẹ nitori ko daju pe oun yoo wọle ibo ninu ẹgbẹ naa boun ba tun dije.

Bó ṣe ń lọ ní Plateau àti Taraba

Awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan kora jọ loṣu Kejila yii, wọn n rọ gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang, lati kuro ni PDP. Wọn ni ko lọ darapọ mọ APC.

O tojo mẹta ti awuyewuye ti n lọ lori gomina naa, pe o fẹ lọ si APC.

Ni Taraba, Gomina Agbu Kefas ti pari eto tiẹ lati lọ si APC.

Awọn ọmọ ti wọn ji gbe nile ẹkọ, nipinlẹ Kebbi ni a gbọ pe o da a lọwọ kọ ti ko fi wọ APC mọ loṣu Kọkanla.

Ana ọjọ Iṣẹgun ni Alaga APC ni Taraba, Ibrahim Tukur, fidi ẹ mulẹ pe Kefas yoo wọ APC loṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Awọn gomina to ṣi wa ninu PDP titi di oṣu Kejila ọdun 2025

Seyi Makinde – Oyo

Ahmadu Fintiri – Adamawa

Caleb Mutfwang – Plateau

Agbu Kefas – Taraba

Dauda Lawal – Zamfara

Bala Mohammed – Bauchi