Ọkọ̀ ńlá kọlù mọ́to mẹ́ta lọ́nà márosẹ̀ Ibadan sí Eko, bàbá, ìyá àti ọmọ wọn kú, èèyàn méjì míì farapa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bàbá, ìyá àti ọmọ wọn kékeré pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ kan tó wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan.

Àjọ tó ń mójútó ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Eko, Lagos State Traffic Management Authority, LASTMA, nínú àtẹ̀jáde kan sọ pé òwúrọ̀ ọjọ́rú ni ìjàmbá náà wáyé.

Agbẹnusọ LASTMA, Adebayo Taofiq nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé agbègbè Secretariat tí èèyàn bá ti fẹ́ wọ afárá Otedola ni ìjàmbá ọkọ̀ náà ti wáyé.

Ó ṣàlàyé pé àwọn èèyàn méjì ló tún farapa níbi ìjàmbá náà.

Ó sọ pé ìjàmbá ọkọ̀ náà ṣokùnfà ikú ìyá, bàbá àti ọmọ wọn kékeré tó jẹ́ ìdílé kan náà, táwọn méjì míì sì farapa gidi.

Ó ní àwọn ọkọ̀ mẹ́ta ni ìjàmbá náà kàn – Audi kan, Toyota Corolla àti Toyota Camry – lẹ́yìn tí ọkọ̀ ńlá kan tó ń sáré kọlù àwọn ọkọ̀ náà látẹ̀yìn.

"Eyí ló jẹ́ káwọn ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu ọkọ̀ wọn tó sì lọ kọlu ọkọ̀ méjì míì èyí tó ṣokùnfà ìjámbà tó lágbára gidi.

Taofiq fi kun pé lójú ẹsẹ̀ tí ìjàmbá náà ṣẹlẹ̀ ni awakọ̀ tó wa ọkọ̀ ńlá náà ti sálọ pẹ̀lú ọkọ̀ rẹ̀, tó sì fi àwọn èèyàn náà sílẹ̀ sínú ìjàmbá ọ̀hún.

Àjọ LASTMA ní àwọn òṣìṣẹ́ òhun tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àjọ Lagos State Ambulance Service ló sáré gbé àwọn méjì tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn Lagos State Emergency and Trauma Centre, Toll-Gate fún ìtọ́jú.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ti gbé òkú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn fún àjọ tó ń rí sí àmójútó àyíká ìyẹn Lagos State Environmental Health Monitoring Unit.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Isheri Olowora, tó fi mọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ti ìjọba àpapọ̀, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì wà lára àwọn tó ṣe àtìlẹyìn láti rí pé wọ́n ṣe àmójútó ìjàmbá náà.

Ọ̀gá àgbà LASTMA, Olalekan Bakare-Oki júwe àdánù tí ìjàmbá ọkọ̀ náà fà bíi èyí tí kò wọn kò lè rí gbà padà.

Ó rọ àwọn ọlọ́kọ̀ láti dènà eré àsápajúdé pàápàá tí wọ́n bá kó ẹrù púpọ̀.

Bákan náà ló kan sáárá sáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún bí wọ́n ṣe ṣàmójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.