Ìdí tí ẹnu fi n kun Ààrẹ America, Biden lẹ́yìn tó daríji ọmọ rẹ̀ fún ẹ̀sùn gbígbé ìbọn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Joe Biden tilẹ Amẹrika ti kede wi pe oun ti dariji ọmọ oun, Hunter Biden to n jiya ẹṣẹ lọwọ lori ẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu lilo ibọn lọna ti ko tọ ati owo ori, eyi ti wọn fi kan an.

Biden kede idariji naa lọjọ Aiku to kọja, bo tilẹ jẹ pe o ti sọ figba kan ri sọ pe oun ko nii lo ipo oun lati ṣaforiji fun Hunter.

Ninu atẹjade ti aarẹ fi sita, o sọ pe niṣe ni wọn ya ọmọ oun sọtọ ninu ẹjọ naa, to si tun ṣapejuwe ẹjọ naa gẹgẹ bi eyi ti ko tọ.

Hunter Biden ninu oṣu Kẹsan an, sọ niwaju ile-ẹjọ wi pe lotitọ ni oun jẹbi ẹsun owo ori ti wọn fi kan oun, ti wọn si da ẹjọ fun un lori gbigbe oogun oloro ati lilo ibọn lọna aitọ ninu oṣu Kẹfa – leyi to mu ko jẹ ọmọ aarẹ akọkọ ti yoo jẹbi ẹsun lori iwa ọdaran.

Nigba to n sọrọ lori ipinnu ijọba lati dariji Hunter, Aarẹ Donald Trump ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan pada sọ pe idariji ti wọn fun Hunter pẹlu awọn mẹfa ti wọn wa lẹwọn, jẹ ojusaaju ofin ati titapa si ofin.

Idariji ti Joe Biden kede fun ọmọ rẹ yii, lo waye lẹyin ti wọn lo ti kọkọ sọ pe oun ko nii lo ipo oun lati fi dide fun Hunter.

Koda, ninu oṣu Kẹsan an, Ileeṣẹ aarẹ ti jade sita wi pe Biden ko nii dariji ọmọ rẹ.

Ṣugbọn ni irọlẹ ọjọ Aiku, aarẹ jade sita lati sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun gba lori ilana ile-ẹjọ orileede naa, ṣugbọn oṣelu wọ ọrọ naa, fun idi eyi o sọ pe ojusaaju wa lori ẹjọ naa.

Biden, to fi han wi pe ipinnu to ṣe naa ṣoro pupọ, o ni oun nireti pe awọn ara Amẹrika yoo ni imọ nipa ipo rẹ gẹgẹ bii baba ati aarẹ orileede lasiko yii.

Hunter, ẹni ọdun marunlelaadọta, lo ti n gbe pẹlu ibanujẹ lati bi ọdun marun-un ataabọ, gẹgẹ bi baba rẹ ṣe sọ.

Ki lo ṣẹlẹ gangan

Ọmọ ọdun meji ni Hunter Biden wa ninu oṣu Kejila, ọdun 1972 nigba ti tirela kan kọlu tirela mọlẹbi wọn, to si pa mama ati aburo rẹ obinrin, Naomi.

Ko tii ju ọsẹ mẹfa lọ ti baba rẹ jawe olubori ninu eto idibo to gbe e wọle sipo ọkan lara awọn aṣofin ilẹ Amẹrika

Baba Hunter kii muti, ṣugbọn ṣe ẹ ri oun funra rẹ, kekere lo wa to fi fẹran ọti mimu, to si sọ nigba kan ri pe oun fẹran lati maa fa kokeeni lasiko toun wa ni fasiti.

Lọdun 2013, Hunter gba fọọmu lati ṣiṣẹ ologun ti Navy nilẹ Amẹrika, ti wọn si gba a wọle. Iwaju baba rẹ to jẹ igbakeji aarẹ nigba naa ni wọn ti ṣe ibura fun un ni White House.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe lọjọ to gba iṣẹ naa gan-an ni wọn ṣe ayẹwo fun un, ti wọn si ṣakiyesi pe o maa n lo egboogi oloro kokeeni, loju ẹsẹ ni wọn ti lee danu.

Gẹgẹ iwe iroyin New Yorker ṣe sọ, latigba ti ẹgbọn rẹ, Beau ti ku lori aisan jẹjẹrẹ lọdun 2015 lo ti mu ọti mimu lọkunkundun. Igba miran wa ti wọn sọ pe yoo jade nile lati lọ ra ọti vodka, ti yoo si mu tan.

Wahala ọhun bẹrẹ nigba ti iyawo rẹ akọkọ, Kathleen Buhle fi ẹsun kan an wi pe owo to n na lori ọti, egboogi oloro, aṣewo ati ile igbafẹ, paapaa fawọn obinrin to n ba lajọṣepọ ti pọ ju.

Buhle sọ pe igba miran yoo wa ti awọn ko nii ni owo lati fi ṣe ohun to ba ofin mu, nigba ti ọkọ oun ba ti na owo ninakuna tan.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti aarẹ ilẹ Amẹrika yoo maa dariji awọn to jẹ ẹjẹ rẹ.

Bill Clinton naa dariji aburo rẹ ọkunrin, Roger Clinton, lori ẹsun to nii ṣe pẹlu egboogi oloro ti wọn fi kan an lọdun 1985, ṣugbọn to darijii lọdun 2001.

Bakan naa lọdun 2020, Donald Trump naa dariji Charles Kushner, to jẹ ọkọ ọmọ rẹ, Ivanka.

Koda lasiko yii, Kushner wa lara awọn ti Trump fun ni ipo ninu iṣakoso rẹ tuntun yii.